Oyo Politics: Àwọn Jàǹdùkú kọlù alága àjọ tó ń ṣètò eré ìdárayá ní ìpínlẹ̀ Oyo, Gbenga Adewusi

Oríṣun àwòrán, others
Awọn janduku kọlu alaga ajọ to n ṣeto ere idaraya n'ipinlẹ Ọyọ
Alaga ajọ to n ṣe akoso ere idaraya n'ipinlẹ Ọyọ, Họnọrebu Gbenga Adewusi ti ọpọ eeyan mọ si 'Arole' fi ara pa l'ọjọ Aiku.
O ni pe o waye nibi ikọlu awọn janduku ti o waye ni papa iṣere Lekan Salami to n bẹ ni Adamasingba nilu Ibadan, lẹyin ifẹsẹwọnsẹ ti o laarin ẹgbẹ agbabọọlu 'Shooting Stars' ati 'Mountain of Fire' ti ilu Eko.
Lẹyin ti ikọlu naa fi apa si oju Adewusi ati awọn ẹya ara mii ni Alamọjuto ere idaraya, Arakunrin Gboyega Makinde ati awọn aṣoju ajọ naa gbe alaga wọn digba-digba lọ si ile iwosan ti o ti n gba itọju.
- Ẹran màálù N328 bilionu ni àwọn ará Eko ń jẹ ní àárín ọdún kan- ìjọba
- Taliban gbé òfin kalẹ̀ lórí àwọn Obìnrin atọ́kùn ètò, bó ojú rẹ tóo bá fẹ́ ka ìròyìn bí bẹ́ẹ̀ kọ́.....
- 'Panel Beater' méjì ya odi òjijì lẹ́yìn tí alága ẹgbẹ́ mọkáláìkì tẹ́lẹ̀ gbá wọn l'étí ní Eko
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní iṣẹ ti bẹ̀rẹ̀ láti dóòlà ẹ̀mí Alàfáà tí wọ́n jígbé ní Ondo
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye méjìdínlógún kò sí pámpẹ́ ọlópàá Ekiti lórí ikú èèyàn méjì
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'BBC Yoruba Ekiti Governorship Debate' tí yóò wáyé lọ̀sẹ̀ yìí
- Ìdajì ilé mi ni mo tà láti rán ọmọ mi nílé ẹ̀kọ́ àmọ́ wọ́n gbẹ̀mì rẹ̀ láìtọ́jọ́ - Bàbá Deborah Samuel
- Agbẹjọ́rò 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé
Alaye ti ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣe oju rẹ sọ ni pe alaga ajọ naa n gbiyanju lati daabo bo awọn agbabọọlu 3SC ni iyara ti wọn ti n mura, ki o to di pe awọn janduku yabo oun naa.
Awọn janduku naa gbiyanju lati ba awọn ohun elo papa iṣere naa jẹ, gẹgẹ bi wọn ṣe n ju aga ati okuta lu awọn oṣiṣẹ ajọ to n ṣe akoso ere idaraya to n pẹtu si wọn lati dẹkun awọn nnkan ti wọn n bajẹ ni papa iṣere naa.
Alakoso iroyin fun ajọ naa, Tunde Ajibike fi idi ọrọ mulẹ fun awọn oniroyin pe wọn ti fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti, bo tilẹ jẹ pe awọn janduku naa salọ ki awọn agbofinro to de.












