Kidnapping: Àwọn ajínigbé jí àlùfáà ìjọ àti ọmọ rẹ̀ gbé, bèrè mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìtúsílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ondo

Ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Ondo bẹrẹ iṣẹ lori alufaa ti wọn ji gbe nibẹ

Àwọn ajínigbé jí àlùfáà ìjọ gbé, bèrè mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà owó ìtúsílẹ̀

Àlùfáà ìjọ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olu Obanla ti kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé ní ìpínlẹ̀ Ondo.

Bayii ni ẹbi alufaa naa fi sita pe wọn ṣi n wa owo itanran naa nitori ko si agbara lati wa milionu mewaa naira ti ajinigbe n beere

Àlùfáà ọ̀hún ń ṣe ìrìnàjò kọjá ní òpópónà Ifon-Okeluse ní ìjọba ìbílẹ̀ Ose, ìpínlẹ̀ Ondo kí àwọn ajínigbé náà tó dá wọn lọ́nà.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, àwọn ajínigbé náà wọ àlùfáà Obanla wọ inú igbó kan ní agbègbè náà.

Àkọlé fídíò, 'FUJI níkan ni ‘beat’ tó jẹ́ àṣà wa, ‘Highlife’ kìí ṣe tiwa, kò sóhun tó jọ pé àwọn ọmọ Sàtání ló ń kọ Fuji Gospel'

Lẹ́yìn èyí ni wọ́n kàn sí àwọn ẹbí àlùfáà náà láti mú mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà wá ká àwọn tó le tú àlùfáà sílẹ̀ .

Àwọn ẹbí Obanla ní mílíọ̀nù kan náírà ni àwọn ní ṣùgbọ́n àwọn ajínigbé náà kọ̀ jálẹ̀ wí pé àwọn kò ní gba mílíọ̀nù kan náírà.

Àkọlé fídíò, Oromidayo Daniel: Mo tú gbogbo ilé Dayo bóya á máa rí ǹkan tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n...

Yàtọ̀ sí àlùfáà Obanla, àwọn ajínigbé náà tún jí ọmọ àlùfáà náà tí wọ́n jọ ń ṣe ìrìnàjò lọ sí Okeluse gbé.

Nígbà tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Funmilayo Odunlami ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti ń ṣiṣẹ́ láti gba àwọn ènìyàn náà kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé.

Odunlami ní lóòótọ́ ni ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ àti pé ẹ̀ka tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé ti wà lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

ÈNÌYÀN T'Í WỌ́N JÍ GBÉ

Oríṣun àwòrán, Screenshot