Premier League: Manchester City gba adé Premier League ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti 2021/ 2022

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Manchester City lo gba ade premier league ilẹ Gẹẹsi ni saa 2021-2022 to wa sopin lọjọ Aiku.
Manchester City na Aston Villa mẹta si meji lẹyin ti wọn gba goolu mẹta wọle laarin iṣẹju bii marun lati yii ọrọ pada
Bi o tilẹ jẹ pe ẹsẹ kọkọ fẹ yọ Manchester gẹrẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Aston Villa, ṣugbọn wọn tete ṣa ara wọn jọ pada lati yanju ọrọ naa.
Gundogan gbe ade liigi Premier league ilẹ Gẹẹsi le Manchester City lori

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aston Villa lo kọkọ gba bọọlu si awọn manchester city nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtadinlogoji, ki Coutinho to tun fikan sii fun wọn ni iṣẹju kọkandinlaadọrin.
Amọṣa, Manchester City tete ṣeto to yẹ fun irapada wọn ti wọn si da meji pada ti wọn tun fi ọkan lee;
Goolu meji latọwọ Gundogan ati ẹyọkan latọdọ Rodri lo mu wọn gba ade liigi naa.
Ni ida keji ẹwẹ, Liverpool pẹlu bori ni Anfield bi o tilẹ jẹ wi pe Wolves kọkọ da aya ja awọn ololufẹ Liverpool nigba ti wọn kọkọ gba goolu kan wọle ki Sadio Mane to daa pada ki abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa to danuduro.

Salah ati Robertson fi kun un fun wọn lati bori Wolves pẹlu goolu mẹta si ẹyọkan.
Pẹlu esi yii, Manchester City ni ami mẹtalelọọdurun nigba ti Liverpool ni mejilelaadọrun.
Eyi ni ife ẹyẹ Premier league ilẹ Gẹẹsi kẹrin ti Manchester City yoo maa gba laarin saa marun sẹyin.
Bi ẹ ko ba gbagbe, Manchester City yii kan naa lo gba ife ẹyẹ liigi Gẹẹsi ni saa to kọja.
Tottenham pa ireti Champions league rẹ mọ Arsenal loju

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹwẹ itakangbọn lori tani yoo ṣe ẹgbẹ agbabọọlu kẹrin ti yoo kopa ni idije Champions league Yuroopu ni saa to n bọ laarin Arsenal ati Tottenham tun jẹyọ.
Amọṣa lẹyin o rẹyin Tottenham ni ipo naa ja mọ lọwọ lẹyin ti wọn gbo ewuro si Norwich loju pẹlu goolu marun un si odo.
Eyi tumọ si pe idije Europa ni Arsenal yoo gba ni saa liigi to n bọ bi o tilẹ jẹ pe gooli marun un si ẹyọkan ni wọn na Everton.
Itẹsiwaju leyi fun Arsenal lẹyin ti wọn ṣe ipo kẹjọ ni liigi naa lawọn saa meji sẹyin.
Manchester United jẹ iya goolu kan lọwọ Crystal Palace ṣugbn eyi ko di wọn lọna gbẹyẹ mọ West Ham lọwọ lati gba ipo Europa kan to ku ti West Ham, yoo si maa mu omi si idije Europa Conference League.
Brighton to din dundu iya fun goolu mẹta si ẹyọ kan fun West Ham lo mu ki ọwọ West Ham ja lara aga ipo kẹfa to yẹ ko mu wọn kopa ni idije Europa League saa to n bọ.
Bi awọn ẹgbẹ agbabọọlu naa yoo ṣe duro niyi lẹyin ti saa 2021/2022 ti pari.













