BBC Yoruba Ekiti Gubernatorial debate: Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìpàdé ìtàkurọ̀sọ láàrin àwọn olùdíjé sípò gómìnà Ekiti

Awọn oludije ti yoo kopa nibi itakurọsọ BBC Yoruba

BBC Yoruba yoo ṣe ipade itakurọsọ, Debate, laarin awọn oludije si ipo gomina ipinlẹ Ekiti, ṣaaju idibo naa ti yoo waye ni ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022.

Itakurọsọ naa yoo waye ni Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, nilu Ado-Ekiti, ni deede ago mẹsan-an owurọ.

Ọdun 2018 ni BBC Yoruba bẹrẹ iru ipade itakurọsọ yii, lasiko idibo gomina ipinlẹ Ekiti to waye lọdun mẹrin sẹyin.

Bakan naa ni ipade naa tun waye nipinlẹ Osun, lọdun 2018.

Lẹyin eyi ni awọn ipade itakurọsọ miran waye lasiko idibo gbogboogbo to waye ni ọdun 2019.

Awọn nkan wo ni yoo ṣẹlẹ nibi itakurọsọ Ekiti?

Nibi ipade naa, ni oriṣiriṣi ẹgbẹ laarin ilu, bi ẹgbẹ oṣiṣẹ, awọn ọlọja, ati awọn ẹgbẹ miran to ni nkan ṣe pẹlu eto ijọba awaarawa, yoo ti kopa, lati beere ibeere lori ipinnu ati eto ti oludije kọọkan ni fun ipinlẹ Ekiti.

Àkọlé fídíò, Lasisi Jasper:Wo ìtàn ayé ọ̀gọ́ àgbà iléẹ̀kọ́ Adeniran Memorial ni Ogbomoso

Bakan naa ni awọn oludije naa yoo lo anfaani rẹ̀ lati sọ awọn nkan ti wọn yoo ṣe yatọ si ti ijọba to n bẹ lori aleefa.

Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe gbogbo araalu ni yoo le wọle si gbọngan itakurọsọ naa, amọ ẹ le wo o lori ẹrọ ayelujara Facebook wa, BBC News Yoruba, tabi ki ẹ darapọ mọ awọn ileeṣẹ redio ati tẹlifisan to jẹ alajọṣiṣẹpọ wa, nipinlẹ Ekiti.

Àkọlé fídíò, Oromidayo Daniel: Mo tú gbogbo ilé Dayo bóya á máa rí ǹkan tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n...

Awọn oludije ti yoo kopa ni:

Segun Oni - SDP

Kemi Elebute-Halle - ADP

Oluwole Oluyede - ADC

Àkọlé fídíò, Amputee: Toheeb Abiodun Olaniyan: Ẹ̀rọ lílọ̀ ní ẹni ọdún mẹ́sàn án ni apa kan mi lọ sí

Debo Ranti - YPP

Biodun Oyebanji - APC

Bisi Kolawole - PDP