'Panel Beater' méjì ya odi òjijì lẹ́yìn tí alága ẹgbẹ́ mọkáláìkì tẹ́lẹ̀ gbá wọn l'étí ní Eko

Oríṣun àwòrán, The Punch
Ọrọ di ẹni oriyọ, o dile, nigba ti wahala bẹrẹ lọjọ Satide, laarin awọn ọmọ ẹgbẹ mọkaliiki, ni agbegbe Ayobo, nipinlẹ Eko.
Iwe iroyin Punch jabọ pe ọrọ ilẹ lo di wahala, debi pe ija naa yọri si sisọ eeyan meji di odi.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, alaga tẹlẹ ni agbegbe naa, lo fi oruka gba 'panel beaters' meji leti, ti wọn si ya odi lẹsẹkẹsẹ.
Kilo pilẹ ọrọ to sọ eeyan meji di odi ojiji?
Ẹnikan to ba the Punch sọrọ, Peter Funsho, ni awọn adari ẹgbẹ lọwọlọwọ, lo lọ ṣayẹwo ilẹ kan ti wọn fẹ fun ọmọ ẹgbẹ kan.
Ṣugbọn alaga tẹlẹ ri, naa ko awọn eeyan miran wa si ori ilẹ naa, eyi to mu ki ọrọ di ariyanjiyan lori ẹni to ni aṣẹ lori ilẹ.
"Alaga tẹlẹ yari pe wọn o gbọdọ kọ́ nkankan si ori ilẹ naa, nitori pe oun ṣi ni aṣẹ lori ilẹ naa.
"Panel Beater kan, Idowu, fun lesi pe ko ni aṣẹ lori ilẹ ọhun nitori o ti kuro ni ipo.
- Ọmọ orílẹ̀-èdè Denmark pa ìyàwó rẹ̀ ọmọ Naijiria àti ọmọ wọn l'Eko, ìjọba dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún un
- Ẹran màálù N328 bilionu ni àwọn ará Eko ń jẹ ní àárín ọdún kan- ìjọba
- Ọlọ́pàá ìpínlẹ Ogun mú olùkọ́ tó fipá bá akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lòpọ̀
- Òkú mẹ́ta, alàyè márùn-ún lá ti yọ nínú ilé tó wó ní Lagos Island
- Ìdajì ilé mi ni mo tà láti rán ọmọ mi nílé ẹ̀kọ́ àmọ́ wọ́n gbẹ̀mì rẹ̀ láìtọ́jọ́ - Bàbá Deborah Samuel
- Agbẹjọ́rò 34 táa tán nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe sọ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Deborah Samuel sẹ́wọ̀n rèé
Ọrọ to sọ yii mu ki ina ija tun ru si.
"Ti alaga tẹlẹ ri naa si yọ oruka kan jade to si fi lu arakunrin naa, ati ẹlomiran, Olowolaiyemo, to da si ọrọ."
Iroyin sọ pe loju ẹsẹ ni awọn mejeeji ṣubu lulẹ, ti wọn ko si le sọrọ mọ tabi dahun ibeere kankan.
"Ileewosan ni Idowu ti laju, lẹyin ti wọn fa omi si lara, ṣugbọn ko ṣi le sọrọ sibẹ.
Eyi lo mu ki wọn o gbe wọn lọ si abule ọkan lara wọn, Oja-Odan, nipinlẹ Ogun, nibi ti ohùn wọn ti la pada, lẹyin itọju ibilẹ."
- Fásitì fọwọ́ òsì júwe ilé fún akẹ́kọ̀ọ́ tó tọ̀ sórí ẹrù èkejì rẹ̀ nítorí ẹ̀yà
- Láí ṣẹ̀ láí rò, wọ́n jó Ṣọ́ọ́ṣì mi pátápátá ní Sokoto, ìrírí mi rèé - Pasitọ ìjọ Celestial
- Ta ni Ahmed Idris oluṣirò owó àgbà Nàìjíríà tó kò sí pampẹ́ àjọ EFCC lórí ẹsùn àjẹbánu N80bn
- Ẹ dákun, ẹ má jẹ̀ẹ́ kí ọkọ mi fi lílù pamí – Ìyàwó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ilé ẹjọ́
- Ẹ kò gbọdọ̀ mu igbó àti sìgá lẹ́nu iṣẹ́ mọ́ – Makinde kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹgbẹ́ onímọ́tò
Ọlọpaa da si ọrọ ija yii
Wọn fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Ayobo leti, ti wọn si mu alaga naa.
Amọ wọn pada gba beeli rẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin sọ pe, lootọ ni ọwọ tẹ awọn afurasi kan, fun ẹsun lilu eeyan lọna aitọ, amọ wọn pada gba beeli wọn.
O sọ pe "awọn adari ẹgbẹ mọkaliiki, ati awọn ti ọrọ naa kan, ti yanju ọrọ ni tubi-inubi pẹlu iranlọwọ DPO ọlọpaa l'agbegbe naa, eyi to mu ki wọn o fi awọn afurasi silẹ."
- Ẹran màálù N328 bilionu ni àwọn ará Eko ń jẹ ní àárín ọdún kan- ìjọba
- Àwọn ọ̀dọ́ dáná sun ilé mẹ́fà, ṣọ́ọ́bù méje ní Bauchi nítórí obìnrin tí wọ́n ló bú Ànọ́bì lórí Whatsapp
- Wo ohun tí iléeṣẹ́ ológun ṣe fun obìnrin yìí lẹ́yìn ọdún Mẹ́tàdínlọ́gọ́rin tí wọ́n gba àkàrà òyìnbó lọ́wọ́ rẹ̀
- Fífẹ̀ ju ìyàwó kan lọ ni àṣírí ẹ̀mí gígùn'
- Ọmọ ìyá méjì ni a pàdánù láàrin ọjọ́ mẹ́ta, ọ̀rọ̀ Dayo nílò ìwádìí, ẹ dẹ́kun isọkúsọ- ẹbí akẹ́kọ̀ọ́ Poly
- Òkú mẹ́ta, alàyè márùn-ún lá ti yọ nínú ilé tó wó ní Lagos Island
- "Ogun ló gbé mi lọ sí Central African Republic, àmọ́ ọmọ ni mo gbé bọ̀"
Awọn meji to ya odi, Ọgbẹni Idowu ati Olowolaiyemọ, ti gbadun , wọn si ti n sọrọ.
Awọn mejeeji to ba akọroyin Punch sọrọ ni, ija ilẹ naa ti bẹrẹ lati ọjọ pipẹ.
Ati pe awọn da si ede aiyede naa, nitori pe awọn ko fẹ ki wọn o yẹyẹ alaga to wa nipo lọwọlọwọ.















