Harira Jubril: Aare Muhammadu Buhari ti ṣe ìkìlọ̀ lórí ìkọlù tó ṣekú pa Obìnrin kan àti ọmọ mẹ́rin ní Anambra

Oríṣun àwòrán, @Presidency
Ohun ìbànújẹ́ ló ṣẹlẹ̀ ní Anambra, ẹ dákún mi ò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni fi oró ya oró lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà- BuhariOhun ìbànújẹ́ ló ṣẹlẹ̀ ní Anambra, ẹ dákún
Aare Muhammadu Buhari ti ṣe ìkìlọ̀ lórí ìkọlù tó ṣekú pa Obìnrin kan àti ọmọ mẹ́rin ní AnambraGómìnà Anambra, Àjọ CAN, Àjọ Arewa bu ẹnu àtẹ́ lu obìnrin àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣekúpa
Aare Buhari ti sọrọsoke nipa ohuin to ṣẹlẹ ni ipinlẹ Anambra ti ọpọ ẹmi si n sọnu.Afurasí 4,000 la fi ṣìkùn òfin mú láàrín ọṣù márùn ún- Amotekun Ondo
- Àwa mẹ́ta la gbé òkú Timothy Adegoke lọ sí Ede road- Ẹlẹ́rìí Oyetunde Kazeem
- Ọmọ ọdún 19 tí wọ́n sọ sí ẹ̀wọ̀n nitorí ọ̀kadà tó sọnù ti kú
- Gbajúmọ̀ Olórin Banky W ti rí tíkẹ̀ẹ̀tì ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbà láti díje dupò aṣòfin
- Ìjọba kéde òfin kónílé-ó-gbélé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án ní ìpínlẹ̀ Anambra
- Ọmọdé 19 ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìṣekúpani ní iléẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́rẹ̀ Texas
- Mà á dá fijilanté sílẹ̀, òmìnira á wà fún ìjọba ìbílẹ̀ láti ná owó wọn- Oluwole Oluyede
- Gómìnà Anambra, Àjọ CAN, Àjọ Arewa bu ẹnu àtẹ́ lu obìnrin àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣekúpa
Buhari sọrọ ni kikun nipa obinrin alaboyun ti awọn agbebọn pa pẹlu ọmọ rẹ mẹrin.
Bakan naa ni Aarẹ Buhari ni pe ki enikeni maṣe gbero pe oun fẹ fi oro ya oro lasiko yii.
O( ni pe orilẹ-ede yii jẹ ti gbogbo wa fun idi eyi, ẹnikeni ko gbọdọ gbiyanju lati fi oro ya oro.
O tun ni pe ki ẹnikeni maṣẹ bẹru nitori awọn fọnran fidio orisiirisi to n jade lori ayelujara nipa awọn to n pa ara oke ọya nile Ibo.
Garba Shehu lo fi atejade yii sita loruko aarẹ Buhari.
O ni awọn akọsẹmọṣẹ eleto abo ti bẹrẹ iṣẹ lati wadii ohun to ṣẹlẹ gangan.
Ni afikun, ileese Aarẹ ni ki awon eeyan ṣọra fun pinpin awọn ayederu iroyin tabi fọnran fidi ofege to ti pẹ.
- Gómìnà Anambra, Àjọ CAN, Àjọ Arewa bu ẹnu àtẹ́ lu obìnrin àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣekúpa
- Àwọn agbébọn jí fadá ìjọ Kátólíkì méjì gbé ní Katsina
- Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí tí ọ̀pọ̀ ní pé Falana àtàwọn àgbẹjọ́rò tó kù gbìyànjú ṣùgbọ́n ìgbẹ́jọ́ ṣì ń tẹ̀síwájú lónìí
- Ọmọ ọdún 19 tí wọ́n sọ sí ẹ̀wọ̀n nitorí ọ̀kadà tó sọnù ti kú
- Gbajúmọ̀ Olórin Banky W ti rí tíkẹ̀ẹ̀tì ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbà láti díje dupò aṣòfin
- Ìjọba kéde òfin kónílé-ó-gbélé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án ní ìpínlẹ̀ Anambra
- Àṣírí bí Dubai ṣe di olókìkí wà lọ́wọ́ mi, mó ṣetán láti lòó ní ìpínlẹ̀ Ekiti - Debọ Ranti
- Òtítọ́ ni pé a mùlẹ̀ láti má sọ fún ẹnì kankan- Magdalene Chiefuna, òṣìṣẹ́ Hilton Hotel jẹ́wọ́ nílé ẹjọ́

Inú ọ̀sẹ̀ yìí ló yẹ kí ìyàwó mi bímọ kí wọ́n tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò Jubril- ọkọ aláboyún Anambra.
Gbogbo ohun tí mo ní ni àwọn agbébọn ti pa yẹn.
Alàyé rèé lẹ́nu ọkọ aláboyún tí àwọn agbébọn ṣekúpa ní Anambra.
Ọkọ aláboyún, Harira Jubril tí àwọn agbébọn pa òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rin ní ìpínlẹ̀ Anambra ní ohun burúkú tí yóò ṣẹlẹ̀ sí òun láyé ni bí wọ́n ṣe pa gbogbo mọ̀lẹ́bí òun run.
Ó ní kò yẹ kí ẹnikẹ́ni lá irú inirá àti ìbàjẹ́ ọkàn èyí tí òun ń là kọjá lásìkò yìí nítorí ìbànújẹ́ ayérayé tí àwọn agbébọn náà dá sí ìgbésí ayé òun.
Ahmed Jubril sọ fún BBC News Pidgin wí pé nínú ọ̀sẹ̀ yìí ló yẹ kí ìyàwó òun bímọ gẹ́gẹ́ bí gbèdéke tí àwọn dókìtà àmọ́ àwọn agbébọn kò jẹ́ kí ìyàwó àti ọmọ tuntun jòjòló tó ń bọ́ gbáyé.
- Òní ni ìgbẹ́jọ́ lórí ikú Timothy Adegoke ń tẹ̀síwájú nílùú Osogbo
- MC Oluomo, òpin ti débá gbígba owó orí lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ ní Eko - Iléẹjọ́
- Wọ́n lẹ̀dí àpòpọ̀ mọ́ mi ni mo ṣe fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò abẹ́nú – Dino Melaye
- Lẹ́yìn idojúkọ ASUU, LAUTECH kéde pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọlé wa parí sáà ètò ẹ̀kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ tẹ́lẹ̀
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'BBC Yoruba Ekiti Governorship Debate' tí yóò wáyé lọ̀sẹ̀ yìí
- EFCC ṣàlàyé ìdí tó fi fípa wọ́lé mú Rochas Okorocha lẹ́yìn tí wọ́n rọ̀jò ìbọn nílé rẹ̀ l'Abuja
"Gbogbo nǹkan tí mo ní láyé ni àwọn agbébọn yìí ti gbà lọ́wọ́ mi, ìyàwó tó wà nínú oyún àti àwọn ọmọ mẹ́rin ni mo pàdánù ní ọjọ́ kan ṣoṣo yìí."
Ó sọ wí pé èyí tó dàgbà jù nínú àwọn ọmọ náà ni ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, tí àbúrò tó tẹ̀lé sì jẹ́ ọmọ ọdún méje kó tó kan ọmọ ọdún márùn-ún àti abúrò pátápátá tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì.
Jubri ṣàlàyé bí àwọn agbébọn ṣekọ̀lù ìyàwó rẹ̀
Nígbà tó ń ṣàlàyé bí àwọn agbébọn náà ṣe ṣe ìkọlù sí ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n sì dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò, Jubril ní ìyáwó àti àwọn ọmọ òun lọ ṣe àbẹ̀wò sí àbúrò òun gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ lọ́sọ́ọ̀sẹ̀ àti pé ìgbà tí wọ́n ń bọ̀ wá sílé ni ìkọlù náà wáyé.
- Gbajúmọ̀ Olórin Banky W ti rí tíkẹ̀ẹ̀tì ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbà láti díje dupò aṣòfin
- Kò sí ààyè fawọn ọdaràn tó ń ṣiṣẹ́ ibi mọ́ ní ìpínlẹ̀ Anambra- Gómìnà Soludo
- Afurasí 4,000 la fi ṣìkùn òfin mú láàrín ọṣù márùn ún- Amotekun Ondo
- Wo ohun tó yẹ kóò mọ̀ nípa aàrùn 'Monkeypox' tó gbòde kàn ní àgbáyé
- Ta ni Anamekwe Nwabuoku tí ìjọba yàn láti delé sí ipò olùṣirò owó àgbà ní Nàìjíríà (AGF)?
- Ẹgbé òsèlú méje darapọ̀ mọ́ ẹgbé òṣèlú Labour Party fún Ètò ìdìbò Ààrẹ
Ó ní nígbà tí òun ń darí bọ̀ láti ibi iṣẹ́ ni àbúrò òujn tó ti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ló sáré wá pàdé òun láti sọ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ fún òun.
Bákan náà ló ní láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà sì ti wáyé lọ́jọ́ Àìkú, àwọn ọlọ́pàá àti ìjọba kankan kò ì tíì yọjú sí òun.
Ó ní òun fẹ́ kó òkú àwọn ọmọ náà àti ìyàwó òun lọ sin ní ìpínlẹ̀ Adamawa tí òun ti wá nítorí kò wu òun láti sin wọ́n sí ìpínlẹ̀ Anambra.
"Owó tí mo máa fi gbé wọn lọ sí ìpínlẹ̀ Adamawa àti [yí tí máa fi sin wọ́n ni mò ń wá báyìí."
"Àwọn ènìyàn tilẹ̀ ti ń fún mi lówó láti fi gbé wọn kúrò ní Anambra."

Kí ni ọlọ́pàá sọ?
Nígbà tí BBC News Pidgin kàn sí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra, Ikenganyia Anthony tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní ìwádìí ti ń lọ lọ́wọ́ lórí ìkọlù náà.
Anthony ṣèlérí wí pé àwọn yóò sa gbogbo ipá wọn láti fojú àwọn tó ṣiṣẹ́ láabi náà winá òfin.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti di ẹrù gbogbo àwọn ipá àti ìpáǹle tó ń wáyé ní ẹkùn ìlà oòrùn Nàìjíríà ru àwọn IPOB .
Ó fi kun pé IPOB ti ń wẹ ara wọn mọ́ lórí àwọn ìkọlù kan ní agbègbè ṣùgbọ́n wọ́n kò tíì sọ ohunkóhun lórí àwọn mọ̀lẹ́bí yìí.
Ẹ ó rántí pé láìpẹ́ yìí ni àwọn agbébọn gé orí ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Anambra ní ìpínlẹ̀ náà.






















