MC Oluomo, òpin ti débá gbígba owó orí lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ ní Eko - Iléẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Others
MC Oluomo: Iléẹjọ́ pàṣẹ òpin śi gbígba 800 lójúmọ́ lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ ní Eko
Ileẹjọ giga nipinlẹ Eko ti paṣẹ fun alaga awọn awakọ nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti wọn n pe ni MC Oluomo ki wọn dẹkun gbigba owo ori lọwọ awọn awakọ ni Eko.
Ileẹjọ naa pa aṣẹ fun MC Oluomo ati awọn mẹjọ miran lori ẹsun pe ko tọ si wọn lati ma a gba a.
Agbẹjọro Agba, Peter Lifu fi aṣẹ naa lele lasiko ti agbẹjọrọ Olukoya ati ẹgbẹ awọn awakọ tuntun, Transport Society of Nigeria pe wọn lẹjọ.
- Èmi ò lọ́wọ́ sí ẹ̀sùn ìkówójẹ N80 bílíọ̀nù tí Idris Ahmed olùṣírò owó àgbà kó jẹ o- Zainab Ahmed mínísítà ìṣúná Nàìjíríà
- EFCC ṣàlàyé ìdí tó fi fípa wọ́lé mú Rochas Okorocha lẹ́yìn tí wọ́n rọ̀jò ìbọn nílé rẹ̀ l'Abuja
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'BBC Yoruba Ekiti Governorship Debate' tí yóò wáyé lọ̀sẹ̀ yìí
- A kò ní sinmi títí tí àlááfíà yóò fi padà sí Naìjíríà- Buhari
- Àwọn ọmọ bíbí Arewa ní àwọn ọlọ́kada láti orílẹ̀-èdè míràn ló ń dáràn nípínlẹ̀ Eko
- EFCC ká Rochas Okorocha mọ́lé, wọ́n ní kó sẹ́bí rẹ̀ tí yóò jáde bí àwọn kò bá mú u
- Afurasí 4,000 la fi ṣìkùn òfin mú láàrín ọṣù márùn ún- Amotekun Ondo
- Kò sí ààyè fawọn ọdaràn tó ń ṣiṣẹ́ ibi mọ́ ní ìpínlẹ̀ Anambra- Gómìnà Soludo
Lara awọn ajọ ti ọrọ naa tun kan ni Ajọ National Union of Road Transport Workers, Registered Trustees of Road Transport Employers Association of Nigeria, Registered Trustees of the Nigerian Association of Road Transport Owners.
Olotu idajọ nipinlẹ Eko, Alhaji Lawal Othman naa ko gbẹyin ninu awọn ti wọn pe lẹjọ naa, to fi mọ Ọga Agba ọlọpaa patapata ati adari ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS.
Bakan naa ni wọn bẹ ileẹjọ ki o paṣẹ ki wọn ye fi iya jẹ awọn awakọ lọna aitọ abi ki wọn fi panpẹ mu wọn lati san owo naa ni ojojumọ.
Saaju ni Adajọ ti ni oun fun wọn ni ọjọ meje lati dahun si ipẹjọ ti Ajọ awọn awakọ naa pe mọ wọn ati idi ti ko yẹ ki wọn fofin de won lori ipẹjọ naa.
Amọ adajọ nibi igbẹjọ naa ni wọn kọ lati dahun si iwe ipẹjọ naa laarin ọjọ meje ọhun.
Nitori naa ni adajọ ṣe paṣẹ ki wọn ye gba owo ori to to ọgọrun mẹjọ naira naa lọwọ awọn awakọ to si sun igbẹjọ si Ọjọ Kẹfa, Oṣu Kẹfa, ọdun 2022.















