Lagos Okada ban: Àwọn ọmọ bíbí Arewa nípínlẹ̀ Eko ní àwọn àjèjì ló ń fi ọ̀kadà dáràn nípínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, lagos task force
Ẹgbẹ awọn ọmọ ẹkun ariwa orilẹ-ede Naijiria, Arewa Comunity, (LASACOMM) ni ipinlẹ Eko ti ke si ijọba ipinlẹ Eko pe gba-gba-gba- lawọn wa lẹyin aṣẹ to pa pe ki wọn ko igbokegbodo ọkada kuro nlẹ lawọn ijọba ibilẹ kan nipinlẹ Eko.
Ẹgbẹ awọn ọmọ ẹkun ariwa Naijiria naa ni ofin yii kii ṣe tuntun nitori pe awọn mọ pe o ti le ni ọdun mẹwaa ti aṣẹ naa ti wa nilẹ.
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'BBC Yoruba Ekiti Governorship Debate' tí yóò wáyé lọ̀sẹ̀ yìí
- Àwọn Jàǹdùkú kọlù alága àjọ tó ń ṣètò eré ìdárayá ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Soludo kéde ẹ̀bùn N10m fún ẹni tó bá mú agbébọn tó gé orí aṣòfin Anambra, Okechukwu
- Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtúnṣe, ẹ̀gbè òsèlú APC sún àyẹ̀wò fún àwọn olujide fún ipò Ààre síwájú
- Ẹran màálù N328 bilionu ni àwọn ará Eko ń jẹ ní àárín ọdún kan- ìjọba
- Taliban gbé òfin kalẹ̀ lórí àwọn Obìnrin atọ́kùn ètò, bó ojú rẹ tóo bá fẹ́ ka ìròyìn bí bẹ́ẹ̀ kọ́.....
- 'Panel Beater' méjì ya odi òjijì lẹ́yìn tí alága ẹgbẹ́ mọkáláìkì tẹ́lẹ̀ gbá wọn l'étí ní Eko
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye méjìdínlógún kò sí pámpẹ́ ọlópàá Ekiti lórí ikú èèyàn méjì
Ipinnu atilẹyin yii waye nibi ipade apero awọn ọmọ Arewa nipinlẹ Eko to waye nilu Eko.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lẹyin ipade naa, ti akọwe wọn, Alhaji Musa Saleh, fọwọ si ẹgbẹ naa ni awọn yoo maa tẹẹ mọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ Arewa nipinlẹ Eko leti nitori pe awọn mọ pe ofin naa wa fun idaabo bo ẹmi ati dukia araalu ni.
Ẹgbẹ awọn ọmọ ẹkun ariwa Naijiria naa wa fi kun un pe awọn mọ pe awọn atọhunrinwa lati orilẹ-ede bii Niger Republic, Chad, Cameroun atawọn orilẹ-ede alamuleti miran lo n ṣọṣẹ.
Wọn ni pe won ti darapọ mọ awọn ọlọkada lo n hu iwa ọdaran gbogbo wọnyii eleyii to n ti igi bọ oju eto abo fun ẹmi ati dukia araalu ni ipinlẹ Eko.
Wọn wa ke si gbogbo awọn ileeṣẹ alaabo gbogbo, paapaajulọ ileeṣẹ wọlewọde lorilẹede Naijiria, iyẹn Nigeria Immigration Service lati tubọ mojuto bi awọn eeyan ṣe n wọle sorilẹede Naijiria latawọn ẹnubode rẹ gbogbo.
Bakan naa ni wọn tun ke si awọn ọmọ Arewa ati gbogbo awọn ọmọ Arewa to n ṣowo ọkada gigun jẹun lati yago si awọn ijọba ibilẹ Apapa, Surulere, Lagos Island, Lagos Mainland, Eti-Ọsa ati Ikẹja nibi ti ijọba ti fofin de igbokegbodo ọkada.
Idi ti ijọba fi gbẹsẹ le ọrọ ọkada nipinlẹ Eko
Lẹyin ti okiki iroyin bi awọn ọlọkada kan ṣe ṣekupa amojuẹrọ kan David Imoh ni ọjọ karundinlogun oṣu karun ni ijọba ipinlẹ Eko ba fi paṣẹ pe ki wọn palẹ gbogbo igbokegbodo ọkada mọ lawọn ijọba ibilẹ mẹfa kan- Apapa, Surulere, Lagos Island, Lagos Mainland, Eti-Ọsa ati Ikẹja- nipinlẹ naa.
Ijọba ipinlẹ Eko fi gbedeke ọjọ kini, oṣu kẹfa, gẹgẹ bi ọjọ ti aṣẹ yii gbọdọ bẹrẹ si ni fi idi mulẹ.
Amọ, ṣaaju aṣẹ yii ni ikọ amuṣẹya ijọba ipinlẹ Eko, Lagos State Taskforce ti ya bo agbegbe naa nibi ti wọn ti ko awọn ọlọkada to n ṣiṣẹ lọna ti ko ba ofin mu lagbegbe naa.
Alaga ajọ naa, CSP Shọla Jẹjẹloye ni pẹlu gbogbo igbesẹ ti wọn ti gbe ṣaaju awọn ọlọkada naa kọ lati jawe tuntun sobi iṣẹ ati iṣe wọn lẹnu iṣẹ.

















