Accountant-general N80billion arrest: Ka nípa ẹní tí ìjọba Nàìjíría yàn láti di ipò olùṣirò owó àgbà mu lẹyìn aṣemáṣe Ahmed Idris

Anameke

Oríṣun àwòrán, @Others

Wo àwọn nkan ti o ko ma nipa Anamekwe to n rọpo Idris Ahmed ti EFCC mu

Ko jẹ tuntun mọ wi pe ijọba apapọ Naijriia ti kede orukọ ẹlominran lati dipo olusiro agba mu ni Naijiria lẹyin ti wọn ni ki ẹni to wa nibẹ lọ rọọkun nile fun igba kan naa.

Ahmed Idris ni olusiro agba ti igba aje si mọ lori lẹyin ti ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu fẹsun kan pe o lu biliọnu ọgọrin naira ni ponpo.

Orukọ ẹni ti wọn si ni ko gba ipo rẹ bayi ni Anamekwe Nwabuoku.

Yoo wa nibẹ titi di igba ti ijọba yoo fi yan ẹni ti yoo dipo naa mu fọjọ pipẹ.

Ibeere kan tawọn araalu n beere ta wa naa si ni ka yannana ni pe iru eeyan wo ni ẹni ti wọn ni ko di ipo yi mu.

Ipo ẹlẹgẹ ni ipo taa n wi yi jẹ yatọ si pe ẹni to wa nibẹ tẹlẹ se asemase.

Gbogbo ohun to nise pẹlu owo to n wọle ati bi wọn se n se inawo rẹ lorileede Naijria ni ọfisi olusiro owo agba Naijria a maa mojutọ.

Àkọlé fídíò, Lasisi Jasper:Wo ìtàn ayé ọ̀gọ́ àgbà iléẹ̀kọ́ Adeniran Memorial ni Ogbomoso

Nkan to yẹ ko mọ nipa Anamekwe Nwabuoku.

Minisita feto ọrọ aje Naijriia ati isiro owo Zainab Ahmed lo kede pe Anamekwe yoo di ipo Ahmed Idris mu fun igba diẹ naa gẹgẹ bi adele.

Zainab Ahmed yi kanna lo pasẹ ki Ahmed Idris lọ rọọkun nile ki wọn ba le se iwadii to yẹ lori ẹsun ti ajọ EFCC fi kan an.

Àkọlé fídíò, Oromidayo Daniel: Mo tú gbogbo ilé Dayo bóya á máa rí ǹkan tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n...

Nibi ipo ti wọn gbe Anamekwe si bayi, yoo maa se awọn isẹ ati ojuse to wa ni ibamu pẹlu iwe ofin to da ipo naa silẹ gẹgẹ bi atẹjade lati ileesẹ Minisita feto ọrọ aje ti se sọ.

Wọn bi arakunrin Anamekwe ni ọjọ Kẹẹdogun osu Kẹwa ọdun 1962 sinu mọlẹbi Robert O. Anamekwe ni ijọba ibilẹ Ehime,ipinlẹ Imo.

O kawe gboye HND nileẹkọ imọ nipa akoso ati imọ ẹrọ Institute of Management and Technology (IMT) to wa ni Enugu.

Àkọlé fídíò, Amputee: Toheeb Abiodun Olaniyan: Ẹ̀rọ lílọ̀ ní ẹni ọdún mẹ́sàn án ni apa kan mi lọ sí

O kawe gboye nidi imọ isiro.

O t'atibẹ tẹsiwaju lọ si fasiti Commonwealth to wa ni Belize nibi to ti kawe gboye ni isakoso isiro.

•Centre for Democratic Studies lo ti bẹrẹ si ni ba ijọba sisẹ to si gunke nidi isẹ to fi de ipo Olusiro owo agba laarin ọdun 1992 si ọdun 1995.

•Lati ibẹ wọn gbe lọ si ọfisi olusiro owo agba Naijria Abuja to si jẹ igbakeji olusior owo agba ni 1996 si ọdun 2001

•O tun sisẹ ni ile asofin agba Naijiria ni ọfisi aarẹ ile asofin laarin ọdun 2001 si 2003 gẹgẹ bi oluranlọwọ pataki si aarẹ ile asofin lori ọrọ ibaraalu sọrọ.

•O se awọn isẹ to ni se pẹlu eto iroyin ati awọn nkan mii fun aarẹ ile asofin agba.

•Anamekwe bẹrẹ isẹ ni ọfisi olusiro owo agba to wa ni ẹka ileesẹ aabo Naijiria lAbuja.

Nwabuoku se isẹ to si di awọn ipo miran mu to fi de ipo adari ẹka to n se amojuto ati ayẹwo ni ọfisi olusiro owo agba orileede Naijria,AGF.

Ipo yi lo dimu titi ti wọn fi yan gẹgẹ bi adele ipo olusiro owo agba Naijria.

Àkọlé fídíò, Wọ́n gbé Póò ìtọ̀ àti igbẹ́’ tó ti já nídìí lé mi lórí lọ dànù l’Eko, pẹ̀lú òúnjẹ́ mi lọ́wọ́ mi - Ajirebi

Ipenija to wa niwaju Adele olusiro owo agba Naijria.

Iyansipo olusiro owo agba yi ki ba ma yatọ si iyansipo mii nibi ti ẹni ti wọn ba yan sipo yoo ti maa se amojuto eto gbogbo ti ẹni to rọpo n se tẹlẹ.

Amọ bayi to se pe ẹni to lọ de ile fun wa labẹ ayẹwo lori ẹsun ajẹbanu, isẹ adele olusiro owo agba yi yoo fẹ le diẹ.

Akọkọ ni pe yoo ni lati se afọmọ ileesẹ ti iru ẹsun ajẹbanu bayi ti jẹyọ.

Àkọlé fídíò, Tàá bá lè bá àwọn ọmọ tó pa Deborah ní Sokoto sọ̀rọ̀ pé ìwà ẹranko ni wọ́n hù, ó burú - Òṣèré Sokoti

Wọn ko ti sọ boya awọn mirn lọwọ ninu iwa ajẹbanu yi pẹlu olusiro owo agba ti wọn jawe lọ rọọkun nile fun yi sugbọn adele yi yoo ni lati sọra tori ko mọ ibi ti iwa ajẹbanu yi de.

O seese ki awọn ti wọn jijọ lu owo ijọba ni ponpo si wa ni ọfisi olusiro owo agba ti wọn yoo si fẹ pa oju ẹsẹ wọn rẹ ki asiri ma ba tu.

Yatọ si eleyi, oju awọn ọmọ Naijria yoo wa lara rẹ nitori ara b ta araalyu lori aduru owo ti wọn gbọ pe wọn fẹsun kan olusiro owo agba to wa nibẹ tẹlẹ pe o ko jẹ.

Àkọlé fídíò, Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Fun idi eleyi, yoo kọkọ ni lati mu ki ọkan araalu ni igbagbọ si isẹ rẹ ki wọn si ma lero pe iru nkan to waye ti aduru owo yi fi poora ko ni waye mọ.

Ijọba Naijria jẹ eleyi to loun tapa si iwa ajẹbanu bo ti le wu ko kere to.

O ku ki araalu ri pe ẹni to di ipo adele yi yoo se afọmọ

Aworan iroyin naa ati minisita iṣuna, Zainab Ahmed Shamsuna

Oríṣun àwòrán, screenshot/Ministry of Finace/facebook

Èmi ò lọ́wọ́ sí ẹ̀sùn ìkówójẹ N80 bílíọ̀nù tí Idris Ahmed olùṣírò owó àgbà kó jẹ o- Zainab Ahmed mínísítà ìṣúná Nàìjíríà

Ileeṣẹ eto iṣuna lorilẹ-ede Naijiria ti sẹ kanlẹ pe ko si otitọ ninu ẹsun kan ti wọn ni oluṣiro owo agba lorilẹede Naijiria, fi kan minisita feto iṣuna, Zainab Shamsuna Ahmed pe ọwọ oun pẹlu ko mọ lori iwa ajẹbanu ati kiko owo ilu jẹ.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí BBC fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ohun tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ń gbé sorí ayélujára

Ni ọsẹ to kọja ni ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC fi panpẹ ofin gbe oluṣiro owo agba lorilẹede Naijiria fun ẹsun kiko owo to to ọgọrin biliọnu naira (N80Billion) jẹ.

Ileeṣẹ minisita fun iṣuna ati ato apapọ, Zainab Shamsuna Ahmed fi sita loju opo Facebook rẹ pe gbogbo ọrọ ti oluṣiro owo agba, Idris Ahmed sọ ninu eyi to ti n so minisita feto iṣuna mọ ọgọrin biliọnu naira to ko jẹ lo jẹ irọ.

Ileeṣẹ eto iṣuna lorilẹede Naijiria ni iroyin naa ti tẹ oun lọwọ nipa iroyin ofege naa to ti n gbilẹ lori ayelujara, eyi to n sọ pe oluṣiro owo agba naa ti tu kẹkẹ ọr fun awọn to n fi ọrọ wa a lẹnu wo ni ajọ EFCC pe minisita feto iṣuna naa ni awọn dukia olowo iyebiye to fi orukọ ọkọ rẹ ra ni Abuja ati Kaduna ati Dubai.

Aworan iroyin naa ti ileeṣẹ iṣuna NAijiria pe ni ayederu

Oríṣun àwòrán, screenshot/Ministry of Finace/facebook

Atẹjade naa wa n rọ awọn araalu lati kọ ipakọ si iroyin naanitori ri iroyin ofege ajegbodo to n wẹni kunra ni.

Lọjọ Aje ni ajọ EFCC kede loju opo Facebook rẹ pe oun ti mu olusiro owo agba lorilẹede Naijiria lori ẹsun ṣiṣowo ilu baṣubaṣu.

Aworan iroyin ti ileeṣẹ iṣuna NAijiria gbe sita lati sọ pe minisita iṣuna, Zainab Ahmed Shamsuna ko mọ nipa ayederu iroyin naa

Oríṣun àwòrán, screenshot/Ministry of Finace/facebook

Ajọ EFCC ni ọgbẹni Ahmed Idris lo awọn ọrẹ, mọlẹbi ati ọna miran lati ko owo ilu to to ọgọrin biliọnu Naira jẹ, eleyi to mu ki ileeṣẹ eto iṣuna ni Naijiria o paṣẹ lọ rọọkun nile fun un.

Ko pẹ lẹyin eyi ti ijọba orilẹede Naijiria kede orukọ Anamekwe Nwabuoku gẹgẹ bi adede olusiro owo agba tuntun.