Buhari visit to Kano: A kò ní sinmi títí tí àlááfíà yóò fi padà sí Naìjíríà- Buhari

Oríṣun àwòrán, @Presidency
Muhammadu Buhari ṣèlérí ètò amáyédẹrùn fún àwọn ọmọ ogun, àti láti pèsè ètò àbò tó péye
Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe ijọba oun ko ni sinmi ayafi to ba yanju iṣoro to n koju ẹka eto abo ni gbogbo kọrọkọndu orilẹ-ede Naijiria.
Buhari lo sọ ọrọ naa nibi ipade awọn ọmọ ileeṣẹ ọmọ ogun orufurufu kan to waye niluu Kano ni ariwa Naijiria.
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'BBC Yoruba Ekiti Governorship Debate' tí yóò wáyé lọ̀sẹ̀ yìí
- Àwọn ọmọ bíbí Arewa ní àwọn ọlọ́kada láti orílẹ̀-èdè míràn ló ń dáràn nípínlẹ̀ Eko
- Soludo kéde ẹ̀bùn N10m fún ẹni tó bá mú agbébọn tó gé orí aṣòfin Anambra, Okechukwu
- Àwọn Jàǹdùkú kọlù alága àjọ tó ń ṣètò eré ìdárayá ní ìpínlẹ̀ Oyo
- 2023: Ègbé Òsèlú Méje Darapo Mo Ègbé òṣèlú Labour Party fún Ètò ìdìbò Ààrẹ
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní iṣẹ ti bẹ̀rẹ̀ láti dóòlà ẹ̀mí Alùfáà tí wọ́n jígbé ní Ondo
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye méjìdínlógún kò sí pámpẹ́ ọlópàá Ekiti lórí ikú èèyàn méjì
O ni "Ijọba yii ko ni sinmi titi ti a oo fi da alaafia ati eto to peye pada si orilẹ-ede yii."
Buhari tun fi akoko naa ki awọn ọmọ ogun ọhun ku iṣẹ takun-takun ti wọn n ṣe lati dabo bo awọn araalu.
O ni ijọba oun ko ni fa ọwọ atilẹyin rẹ sẹyin lọdọ awọn ọmọ ogun naa latari iṣẹ akinkanju tio wọn n ṣe.
A ti ṣetan lati jawe sobi akitiyan wa
Nigba toi n fi ẹmi imoore han si awọn o logun naa fun bi wọn ṣe n fi wọn wewu, Buhari ni "Mo fẹ fi da yin loju pe awọn ọmọ Naijiria mọ riri iṣẹ akin ti ẹ n ṣe."
Lẹyin naa lo rọ wọn lati maṣe fa sẹyin ninu ojuṣe wọn nitori obitibiti owo ti ijọba ti na lori ẹka eto abo, eyii to ti n so eso rere.
O ni "Ninu afojusun wa lati tubọ jẹ ki ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu ba igba mu, a oo tubọ maa na ọwọ si ileeṣẹ naa."
"Fun idi eyii, a ti gbe owo kalẹ lati ra awọn irinṣẹ ogun, to fi mọ awọn ọkọ UAV ati elikọpita lati mu ki iṣẹ yin rọrun."
"A fẹ ki ẹ mọ pe ijọba wa ti ṣetan lati ṣe gbogbo ohun to yẹ lati ri pe a ṣe gbogbo atilẹyin to yẹ fun yin lati yanju iṣoro to n koju eto abo."
Buhari tun ṣeleri lati ṣeto awọn ohun igbayegbadun fun awọn ọmọ ogun naa.
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje, awọn lọgalọga nileeṣẹ ọmọ ogun, awọn ọba alade, to fi mọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin.
















