What to know about monkeypox: Ṣé lóòótọ́ ní pé àwọn òní ìbálòpọ̀ akọ sí akọ wá nínú ewú láti kó 'Monkeypox' jù ará yókù?

Ààrùn 'Monkeypox', bí mó ṣẹ lè kó àti òhun míì tó yẹ ní mimọ
Wọn se awari awọn ọkunrin to lugbadi arun Monkey Pox ni Yuroopu lẹnu lọọlọ yi.
Wi pe won ko aarun yi kọ lo pe fun akiyesi bi kii se pe awọn to ko arun yi lugbadi nipa pe wọn ni ibalopọ pẹlu awọn ọkunrin mii.
Tori naa se a wa le sọ pe aarun monkeypox jẹ eleyi taa le ko latara ibalopọ bii?
Awọn alasẹ ilera sọ pe ko ri bẹẹ.
- Inú Nnamdi Kanu kò dùn sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani tó ń wáyé ní Anambra - Agbẹjọ́rò Kanu
- A kò ní sinmi títí tí àlááfíà yóò fi padà sí Naìjíríà- Buhari
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'BBC Yoruba Ekiti Governorship Debate' tí yóò wáyé lọ̀sẹ̀ yìí
- Àwọn ọmọ bíbí Arewa ní àwọn ọlọ́kada láti orílẹ̀-èdè míràn ló ń dáràn nípínlẹ̀ Eko
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní iṣẹ ti bẹ̀rẹ̀ láti dóòlà ẹ̀mí Alùfáà tí wọ́n jígbé ní Ondo
- Àwọn Jàǹdùkú kọlù alága àjọ tó ń ṣètò eré ìdárayá ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye méjìdínlógún kò sí pámpẹ́ ọlópàá Ekiti lórí ikú èèyàn méjì
- Taliban gbé òfin kalẹ̀ lórí àwọn Obìnrin atọ́kùn ètò, bó ojú rẹ tóo bá fẹ́ ka ìròyìn bí bẹ́ẹ̀ kọ́.....
Onimọ ilera kan to n ba ajọ WHO sisẹ Andy Seale sọ pe ''Bo ti lẹ jẹ pe a ri tawọn kan to jẹ onibalopọ akọ si akọ ko aarun yi,eleyi ko tunmọ si pe aarun awọn ''gay'' ni.Ko si ẹni to ko le ko aarun yi''
O ni awọn aarun ibalopọ jẹ eyi ti eeyan maa n nilo ibalopọ ki o to le ko sugbọn ''eeyan ko nilo ibalopọ ti o to lugbadi monkeypox''
O fi kun pe isọwọ bawọn se n gbọ pe awọn ọkunrin onibalopọ akọ si akọ n ko aarun yi ko ju pe awọn wọnyi ko jafara lati wa itọju fun ara wọn ni kete ti wọn ba ri apẹrẹ aarun yi.
Nibi ọrọ de duro, ki wa la mọ nipa aarun Monkeypox?
O kere tan WHO ti kede pe wọn ri eeyan mejilelaadọrin to ti lugbadi aarun yi ni Yuroopu,Amẹrika,Canada,Australia
Wọn si ti se iwadii eeyan mejidinlọgbọn ti wọn furasi pe o lugbadi aarun yi lawọn orileede mejila ti monkeypox kii saba ran kaakiri.
Sugbọn sa, awọn onimọ ni eleyi kii se bi ajakalẹ Covid-19 ati pe awọn ni ikapa lori ajakalẹ yi.

Ki ni Monkeypox?
Monkeypox jẹ aarun ti kokoro aifojuri monkeypox le sokunfa rẹ.O yatọ si kokoro aifojuri smallpox sugbọn oun ko buru to arun igbona 'smallpox'.
Lagbegbe aarin gbungbun ilẹ Afrika lo wọpọ si ati iwọ oorun ilẹ Afrika ni paapa lawọn agbegbe ti igbo kijikiji wa.
Ni orileede DR Congo lawọn ibi ti igbo kijikiji wa, wọn ti kede pe o leni eeyan 1,200 to ti ko aarun yi lọdun yi nikan.
Wọn ni akọsilẹ eeyan mẹtadinlọgbọn to ku laarin ọjọ Kini osu kaarun 2022 gẹgẹ bi WHO se sọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki lawọn apẹrẹ afihan Monkeypox?
Ara gbigbona, ori fifọ, ara wuwu,irọra ẹyin ati kasan wa lara apẹrẹ aarun yi.
Lẹyin yi, ara yoo bẹrẹ si ni su yoo si kọkọ bẹrẹ lara ko to di bi alefọ gẹgẹ bi onimọ Rosamund Lewis olori ẹka to n mojuto small pox ni WHO se sọ.
Lẹyin igba naa, yoo gbẹ, o ba si gbẹ tan yoo re jabọ.
Ara sisu yi a maa yun eeyan ti o si maa n fa irora sugbọn dokita Amesh Adalja ti ile iwosan John Hopkins to wa ni orileede Amẹrika sọ pe yoo dinku bo ba ti se diẹ si.
O ni laarin ọjọ mẹrinla si ọjọ mọkanlelogun ni yoo fi kora nilẹ ti yoo si lọ fun ara rẹ.

Bawo ni Monkeypox se n ran kaakiri?
Monkeypox le tan ka si ara ẹdamọniyan lati ọdọ ẹranko to ba ko aarun yi bi ọbọ, ekute tabi ọkẹrẹ.
Ko wọpọ ki awọn eeyan ko aarun yi ran ara wọn sugbọn o le sẹlẹ ti eeyan ba ko lara ẹni to sunmọ to ni aarun yi.'
Ọna tawọn eeyan n gba ko ni latara awọ ara to ba ni alefọ,ọna ọfun, oju ati ẹnu.
Bi eeyan ba tun fi ọwọ kan asọ ẹni to ni aarun yi, tawẹli, tabi asọ ibora rẹ,eeyan le lugbadi aarun yi.

Se Monkeypox le pa eeyan?
Monkeypox gẹgẹ bi WHO se sọ jẹ aarun ti o maa mu eeyan fun igba diẹ ni amọ a ti ri awọn imi to la iku lọ.
Laipẹ yi, nkan bi ida mẹta si mẹfa ninu ida ọgọrun lo n padanu ẹmi wọn lọwọ aarun yi sugbọn alaye to wa lori rẹ ko lọ geere.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita Adalja sọ pe: ''Nigba mi eeyan a maa ri ti ida iye awọn to padanu ẹmi wọn lọwọ aarun yoo to nkan bi ida mẹwaa sugbọn pupọ wọn lo n gbe lagbegbe ibi ti nkan amayedẹrun ko si ti eto ilera wọn si mẹhẹ.''
O ni ẹda aarun yi meji taa mọ si ẹda ti iwọ oorun Afrika ati eleyi to n ja ni aarin gbungbun Afrika.
Eleyi to wa nita bayi jẹ eyi to nise pẹlu iwọ oorun ilẹ Afrika.
''Ohun iduunu ni pe ẹda ti iwọ oorun ilẹ Afrika yi ko lagbara to ti aarin gbungbun Afrika.Tori naa awọn ti yoo ko aarun yi nipa ẹda taa n wi yi ko ni pọ.''
Ọjọgbọn Catherine Bennet onimọ nipa ajakalẹ aarun ti fasiti Deakin to wa ni Melbourne Australia lo sọ bẹ fun BBC.
- Báwo ni abẹ́rẹ́ àjẹsára ṣe bẹ̀rẹ̀?
- Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀
- Ṣé o mọ̀ pé o leè kó Covid pẹ̀lú ọmọ ìka ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ láì mọ̀?
- U.S. yóò máa fún àwọn ọmo Nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
- Tea àti omi iyọ̀ ni èròjà tí orílẹ̀-èdè yìí fí n kojú ààrùn COVID-19
- Lóòtọ́ abẹ́rẹ́ Covid-19 lée jẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀dé ayé, àmọ́ ẹ wo ìdí tí kò lè ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ lára yín - Dókíta
- Àwọn nǹkan mẹ́ta tí a kò tíì mọ̀ nípa Covid-19 lẹ́yìn tí àrùn náà bẹ́ sílẹ̀ rèé
Kini itọju monkeypox?
Wọn a maa se itọju monkeypox nipa mimu adinku ba awọn apẹrẹ rẹ.
Awọn oogun apakokoro wa sugbọn ''bi eeyan ba se tete ri pe aarun yi ti wọ ara ni yoo se gba sisẹ'' si gẹgẹ bi Ọjọgbọn Bennett se sọ.
Ko si abẹrẹ ajẹsara fun aarun yi sugbọn WHO ni abẹrẹ ajẹsara ti aarun igbonna le koju rẹ debi to lami.
Amọ sa Ọjọgbọn Bennett ni kawọn eeyan ma foya tori awọn ko ni maa wa abẹrẹ ajẹsara bi ti Covid-19 fun gbogbo aye.
O ni awọn agbalagba mi to wa laye nigba ti wọn fi n gba abẹrẹ igbonna yi ti gba abẹrẹ naa nigba naa.
O fi kun pe wọn le lo abẹrẹ yi gẹgẹ bi idaabo fawọn osisẹ ilera to n tọju alaisan lawọn agbegbe ti ọwọja rẹ ba pọ si.
















