Vaccination: Kí ní ìdí tí àwọn ènìyàn kìí ṣe fọ́kan tan abẹ́rẹ́ àjẹsára ?

Abere ajesara
Àkọlé àwòrán, Kíní abẹ́rẹ́ ajẹsára, báwo ni wọ́n ṣe n ṣiṣẹ́ àti pé kíní ìdí tí àwọn ènìyàn kìí ṣe fọ́kan tan?

Abẹ́rẹ́ àjẹsára tio ṣe ànfàni fún ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ènìyàn ní àwọ́n ọ̀ọ̀rùndúnrún to ti pẹ́ sẹ́yìn, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọ́n eléto ìlera ni àwọn orílẹ̀-èdè àgbáye lo n sọ pé awọ́n ṣe àkiyési pé kii ṣe gbogbo ènìyàn lo fi ara mọ ọrọ̀ abẹ́rẹ́ ajẹsára, ti àwọ́n miràn si n kọ jálẹ̀ pé àwọn ko fẹ́ ẹ.

Ọ̀rọ̀ náà ti wá jo dóri kókó ti ó sì n kọni lomiinu fún àjọ elétò ìlera ni àgbáye (WHO) ti wọn si ka àsà yìí si ọkan nínú ǹkan mẹ́wàá tó n dúnmọ̀huru mọ́ ètò ìlera lágbàye lọ́dun 2019.

Vaccination

Báwo ni wọ́n ṣe ṣàwári abẹ́rẹ́ àjẹsára?

Ṣááju kí abẹ́rẹ́ àjẹsára to dé, àyé yìí jẹ ibi to ni ewu gídigidi ti ọ̀pọ̀ àwọ̀n ènìyàn si n kú lọ́dọ̀dun nítori àìsàn to ṣee dènà.

Àwọn orílẹ̀-èdè China ló kọ̀kọ̀ bẹ̀rẹ̀ abẹ́rẹ́ ajẹsára ní ọọrundunrun kẹwàá, wọ́n n pe ǹkan ni "Variolation" èyí túmọ̀ sí tísù àwọ̀n ènìyàn ti ará wọ́n lé han si èpo tó maa ǹ wà lóju egbò ti àìsàn kan ba fà á láti mú ìdàgbàsókè ba àwọ́n àfani tó ń ba ààrun ja lára.

Nígbà ti ọọrundunrun mẹ́jọ míràn tún gùn ún, oníṣègùn òyìnbó kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì Edward Jenner wá woye pe àwọn ọmọ tó ń fún omi ọmu Mààlú ní àìsàn to nííṣe pẹ̀lú àwọn màálu yìí sùgbọ́n àìsàn ṣàpọ̀ná (Smallpox) o mú wọ̀n.

Àìsàn sànpọ̀ná jẹ́ àjàkalẹ̀ àrun ní ayé ìgbà náa ti ó si pa ìdá ọgbọ̀n ninú ọgọ́rùn àwọn ènìyàn to lùgbàdì rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn to bá si yèé, wọ́n a maa ni àpá lára tàbi ki wọ́n fọ́ lójú.

Ní ọdun 1796 Jenner sé ìwádìí kan tó si lo James Phipps ọmọ ọdun mẹ́jọ nígbà tó fí àìsàn máàlú si oju egbò láìpẹ́ ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ si ni fi ami àìsàn náà han.

Ní ọdun 1798, èsí ìwádìí náà jáde ti wọ́n si pè é ni ajẹsára láti inu èdè Latin "Vacca" tí ó tumọ si (Cow) Màálu.

ní àwọ́n aṣeyori to ti wáye?

Abẹ́rẹ́ ajẹsára ti ṣe ìrànwọ́ láti séwélé àwọn aburu ti àwọn aisan ti ṣe ni awọn sẹnturi sẹyin.

Ṣááju àsìkò yìí o lé ni ènìyàn mílíọnu méji àti ọwọ́ mẹ́fà ló n ku lọ́dọ̀ọ̀dú ki wọn to gba abẹrẹ ajẹsara akọkọ bni ọdún 1960.

Vaccination

Ọdun díẹ̀ sẹ́yìn ní o wá di pe àwọn eniyan n ku tabi ki wan yarọ nítori àìsàn rọmọ́lápa rọ́mọ́lẹ́sẹ̀, sùgbọ́n níbayii ọ̀rs náà ti di afiẹyin ti eegun fisọ.

Vaccination

Kíni ìdí ti àwọn ènìyàn kìí fi fẹ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára?

Ọjọ ti pẹ ti àwọn èniyan ti ń siye meji lori ọ̀rọ̀ abẹ́rẹ́ àjẹsára fún oniruuru ìdí, láti ori ẹ̀sìn, àsà nítori wọ́n rò ó pé kìí ṣé ohun tó mọ àti pé ọ̀nà láti gba ẹ̀ta ominira ara ẹni lọ́wọ́ wọn ni.

boy with measles

Oríṣun àwòrán, Science Photo Library

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ọ̀rọ̀ abẹ́rẹ́ àjẹsára maa n ni ọwọ òṣèlú nínú, fún àpẹrẹ, bí mínísita fún ọ̀rọ̀ abẹle ni Italy ṣe dara pọ mọ àwọn ẹgbẹ́ ti kìí gba abẹ́rẹ́ ajẹsára.

Kóda láì ni ìdí ni ààrẹ ilẹ̀ Amẹrika ti sọ pé abẹ́rẹ́ ajẹsara nii ṣe pẹlu ohun to n fa ti àwọn ọmọ tí ọpọlọ wọ́n ko jí pépé to.

ní àwọn ewu to wà nibẹ̀?

Tí ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láwujọ ba rí i dáju pé wọ́n n gba abẹ́rẹ́ ajẹsara yóò mú àdinku ba àwọn ajakálẹ̀ ààrun yóò si le àìsàn jina si àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ ti wọ́n ko ti ni àwọn èròja ara ti yóò maa ja fún wọ́n lái ti gba abẹ́rẹ́ ajẹsára.

Vaccination

Onímọ ìṣègùn tó ni ìmọ jù lọ ni ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì ní ọdun to koja ti kìlọ pé ọ̀pọ̀ awọn eniyan ni wọ́n ti tan jẹ pẹlú irọ lóri abẹ́rẹ́ ajẹsára pàpá jùlọ lori ẹ̀rọ ayhelujara, ti olùwádìí ọmọ ilẹ̀ Amrika kan naa si ti ri ìdí ọ̀rọ̀ pé àwọn Russia ni wọ́n n lò láti iròyìn náà ka fún araye.

Iye àwọn ọmọ tó gba abẹ́rẹ́ ajẹ sára kò tìí yi pada gẹ́gẹ́ bi ajọ WHO ṣe sọ ìdá ọgọ́rin ati máruùn nínú ìdá ọgọ́run ni wọ́n wà titi di àsìkò yìí láti nkan bi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.

WHO sọ pe abẹ́rẹ́ ajẹ sara ń dóòlà ẹmi àwọn ọmọ mílíọnu méji si mẹta kákìri àgbáye ní ọdọọdun.

Ìpèníja to ga jùlọ, àti àwọn orilẹ̀ -èdè tó kéré jùlọ ninú gbígba abẹ́rẹ́ ajẹ sára, ti ìja ìdámu àti iyàn si kún ibẹ̀ mi Afghanistan, Angola, àti DR Congo.

Produced by Roland Hughes, David Brown, Tom Francis-Winnington and Sean Wilmott