Covid: Láàrin ọjọ́ kan sí ọdún kan ti o gba abẹ́rẹ́ Covid, wo bí yóò ṣe ṣe lára rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Rachel Schraer
- Role, Health and misinformation reporter
"A o mọ ijamba tabi ipalara ọlọjọ pipẹ ti abẹrẹ ajẹsara Covid-19 n ṣe". Eyi jẹ nkan to maa n wọpọ ju tawọn eeyan n sọ lori ayelujara.
Amọṣa, laarin ọdun kan ni ẹmi gigun aabo ti eeyan lee ni to ba ti kan ti abẹrẹ ajẹsara.
Awọn onimọ Sayẹnsi ti ṣalaye to kun to to tun le nipa ohun to lee mu ki ipalara yọju latari gbigba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.
Ki lo n ṣẹlẹ ni agọ ara rẹ too ba gba abẹrẹ Covid-19?
Bo tilẹ jẹ pe ṣẹṣẹ de aye ni awọn abẹrẹ ajẹsara Covid-19, ilana ti wọn n gba ṣiṣẹ lara rẹ kii ṣe ajoji ile aye.
Nini imọ nipa bi wọn ṣe n ba awọn eroja ara ṣiṣẹ lee ran wa lọwọ lati mọ bi a ṣe le tete reti ijamba tabi ipalara ti yoo ba ṣẹlẹ.
Lẹyin iṣẹju 15
Eeyan perete nikan ni imọlara wọn yoo farahan si awọn eroja to wa ninu abẹrẹ ajẹsara naa eyi yoo si ṣẹlẹ laarin nkan bii isẹju mẹẹdogun ti wọ́n ba gba a.
Fun gbogbo awọn eeyan to ku, ipalara tẹẹ ba ri kan jẹ idahun agọ ara yin si abẹrẹ naa ni tabi si aabo ara to gbe jade lara yin.
Lẹyin wakati kan
Ọrọ to sọ pe - bi ara yin ba dahun si abẹrẹ naa funrarẹ - oju ẹsẹ ni yoo bẹrẹ.
Agọ ara rẹ maa n mọ ti ajoji ba wọle o si maa n koju ija sii pẹlu awọn ọmọ ogun sẹẹli alaabo, eyi ni nkan ijagun ti yoo lo lodi si kokoro bẹẹ.
A mọ idahun ara to ba ni ṣe pẹlu ipele yii yoo waye laarin wakati kan tabi ọjọ bii melo kan koda to fi mọ idahun ara to wọpọ ju iyẹn apa wiwu, ara gbigbona atawọn nkan bii omi inu ara.
Lẹyin ọjọ 10
Asiko yii ni iṣi mii nipa bi ara ṣe maa n dahun si abẹrẹ ajẹsara - ibi ni agọ ara ti maa n kọ lati fara mọ nkan to n la kọja,ara yoo maa pese awọn sẹẹli to wa gun biba kokoro aburu ja nikan gbogbo eyi yoo si kasẹ nilẹ lẹyin ọjọ mejidinlọgbọn.
Ẹwẹ, o ni ipalara adama kan to wọpọ pẹlu abẹrẹ ajẹsara AstraZeneca- ẹjẹ didi pọ - o si maa n ṣẹlẹ laarin asiko yii amọ o ni ṣe pẹlu awọn sẹẹli to n daabo bo ara rẹ ati bo ṣe dahun si abẹrẹ naa. Idi niyi to jẹ pe laarin ọsẹ bii mẹrin ti eeyan gba abẹrẹ ajẹsara ni iṣẹlẹ ẹjẹ didi maa n ṣẹlẹ.
Lẹyin ọjọ 28
Ni kete ti asiko ifara mọ nkan ba ti kja- ni nkan bii oṣu kan, o ku ọ ku awọn sẹẹli to kan maa n ranti nkan eyi ti yoo si fun ọ ni abo fun ọpọlọpọ oṣu tabi ọdun lẹyin igba too ni imọlara rẹ gangan. Amọ kii ṣe pe ara rẹ tun n dahun lẹẹkan sii, Dokita Victoria Male to jẹ onimọ nipa imọlara ilara ọmọ bibi ni London ṣalaye.
Tori naa, o ni boo ba ti ni imọlara pe ara rẹ n dahun si abẹrẹ too gba, o nira gidi ki nkankan to ba tun ṣẹlẹ lẹyin igba yẹn jẹ pe abẹrẹ Covid lo fa a.
Ko si igbagbọ ida ọgọrun geerege ninu ohunkohun to jẹ́ imọ iṣegun oyinbo, torinaa a o le sọ pe ohunkohun o le ṣẹlẹ lẹyin asiko naa.
Amọ awọn onimọ iṣegun oyinbo ko lee sọ tabi ranti akoko kankan ti ijamba tabi ipalara abẹrẹ kankan n waye tayọ oṣu mẹfa lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọna mii, awọn orilẹede agbaye ti n ṣe awọn eto lati bojuto ijamba to ba lee suyọ latari abẹrẹ ajẹsara ati ki wọn si le pin bi o ṣe ṣẹlẹ pẹlu ara wọn.
Sibẹ sibẹ, awọn eleto ilera lagbaye naa n boju wo ati ri boya ijamba kankan wa, Dokita Lahariya sọ bẹẹ.













