Afurasí 4,000 la fi ṣìkùn òfin mú láàrín ọṣù márùn ún- Adetunji Adeleye adarí Amotekun Ondo

Amotekun

Oríṣun àwòrán, @Amotekun

Amotekun mú afurasí 4,000 lórí onírúrú ẹ̀sùn l'Ondo

Ikọ alabo Amotekun ipinlẹ Ondo ti ni o kere tan, awọn ti fi ṣikun ofin mu nnkan bii ẹgbẹrun mẹrin awọn afurasi laarin oṣu Kinni si oṣu Karun un ọdun 2022 lori oniruru iwa ọdaran.

O ni awọn fi panpẹ ofin mu awọn eeyan ọhun lori oniruru awọn ẹsun bii ijinigbe, idigunjale, nini ohun ija oloro lai gba aṣẹ lọwọ ijọba, atawọn ẹsun mii.

Adeleye ṣalaye pe iwa ọdaran ti dinku si pẹlu ida aadọrin l'Ondo nitori akitiyan ikọ Amotekun lati ti ọwọ iwa ọdaran bọlẹ.

Nibe ni Adeleye ti salaye pe: "Laarin oṣu Kinni si oṣu Karun un ọdun 2022, a ti fi ṣikun ofin mu nnkan bii ẹgbẹrun mẹrin afurasi, awọn kan ninu wọn ti wa lọgba ẹwọn, nigba ti iwadii ṣi n lọ lọwọ lori awọn mii."

"Laarin oṣu marun un to kẹyin ọdun to kọja, ati oṣu marun un to bẹrẹ ọdun yii, awọn ti a fi ṣikun ofin dinku si."

"Lọdun to kọja, awọn ti a mu lori ẹsun pe wọn tapa si ofin ma fi ẹranjẹko laarin igboro to ẹgbẹrun mẹrin, amọ lọdun yii, awọn ti a ti mu lori ẹsun kan naa ko tii ju ẹgbẹrun kan."

Àkọlé fídíò, Amputee: Toheeb Abiodun Olaniyan: Ẹ̀rọ lílọ̀ ní ẹni ọdún mẹ́sàn án ni apa kan mi lọ sí

Ona wo ni awọn ajinigbe n gba ṣiṣẹ bi Adeleye ṣe ṣalaye?

Adeleye sọ siwaju si pe ṣaaju akoko yii, ni ṣe ni awọn ajinigbe maa n ṣọṣẹ bo ṣe wu wọn amọ ikọ Amotekun ti ti ọwọ wọn bọ aṣọ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, aṣeyọri naa kii ṣe igbiyanju Amotekun nikan, amọ awọn ṣe aṣeyọri naa pẹlu ifọwọsowọpọ ajọ NSCDC, DSS ati ileeṣẹ ọmọ ogun.

Àkọlé fídíò, Lasisi Jasper:Wo ìtàn ayé ọ̀gọ́ àgbà iléẹ̀kọ́ Adeniran Memorial ni Ogbomoso

A ko ni da si eto oṣelu tabi idibo

Adari ikọ Amotekun ọhun tun sọ pe awọn oṣiṣẹ ikọ naa ko ni lọwọ ninu eto idibo Aarẹ ọdun to n bọ.

O ni "Ti ijọba ipinlẹ Ondo ko ba lo ikọ Amotekun fun idibo tirẹ, o yẹ ki ẹ mọ pe a ko ni fi sẹgbẹ kan to ba di akoko eto idibo gbogbogbo ọdun to n bọ.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí BBC fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ohun tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ń gbé sorí ayélujára

"Ohun to kan wa ninu eto idibo naa ni pe ki awọn araalu ma ṣe tẹ ofin loju mọlẹ lasiko eto idibo naa, awa yoo si ṣe iṣẹ wa bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ."

Lẹyin naa lo rọ awọn araalu lati tete bun awọn gbọ ti wọn ba kofiri iwa ọdaran kankan lagbegbe wọn.