Rochas Okorocha: EFCC da ìbọn bolẹ̀ nílé Rochas Okorocha, wọ́n ní Ó ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kà á mọ́lé

Rochas Okorocha

Oríṣun àwòrán, Rochas okorocha/ twitter

Ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede NAIjiria, EFCC ti fi ipa mu gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, Sẹnetọ Rochas Okorocha ni ile rẹ to wa nilu Abuja, olu ilu orilẹede Naijiria.

Ajọ naa fipa wọ ile Sẹnetọ Rochas Okorocha lẹyin ti iro ibọn dun lakọlakọ.

Bakan naa ni wọn fipa le awọn akọroyin kuro ni ile Sẹnetọ naa to tun wa lara awọn to n dije fun ipo aarẹ Naijiria labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC.

Idi ti a fi gbe Okorocha tipatipa ninu ile rẹ- EFCC

Ninu atẹjade ti ajọ EFCC fi soju opo Ayelujara Facebook rẹ, ajọ naa ni awọn ti n ranṣẹ pe gomina tẹlẹ naa pe ko wa yọju si awọn lẹyin to ti kọkọ sa labẹ beeli ti ajọ naa fun un nigba ti wọn kọkọ mu u, ṣugbọn wọn ni ko dahun.

Ajọ EFCC sọ ọ siwaju ninu atẹjade naa pe igba meji ọtọọtọ lawọn ti gbe ẹjọ naa de iwaju adajọ nilu Abuja ṣugbọn ti wọn ko lee gbọ ẹjọ naa nitori aifarahan Sẹnetọ Rochas Okorocha nile ẹjọ.

O fi kun un pe ọgbọn ọjọ oṣu karun un ni igbẹjọ naa yoo si tun waye pẹlu bi adajọ ti ṣe fi ohun silẹ pe oun ko tun ni gba sisun igbẹjọ naa siwaju mọ lọtẹ yii lo faa ti awọn fi gbe igbesẹ naa.

Atẹjade EFCC lori bi wọn ṣe mu Rochas Okorocha si ahamu

Oríṣun àwòrán, Screenshot/EFCC/facebook

EFCC ká Rochas Okorocha mọ́lé, wọ́n ní kó sẹ́bí rẹ̀ tí yóò jáde bí àwọn kò bá mú u

Ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ti ya bo ile gomina ana ni ipinlẹ Imo, Rochas Okorocha nilu Abuja.

Rochas to jẹ ọkan lara awọn oludije fun ipo aarẹ Naijiria lẹgbẹ oṣelu APC gbalejo awọn agbofinro ajọ EFCC lọjọ Iṣẹgun bi o tilẹ jẹ wi pe ko si ẹni mọ ni pato idi ti wọn fi ṣigun bo ile naa.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle bii iwe iroyin Punch ati ileeṣẹ mohunmaworan Channels jẹ ko di mimọ pe erongba awọn oṣiṣẹ ajọ naa ni lati lee fi panpẹ ofin gbe Rochas Okorocha lasiko ti wọn wọ ile naa.

Rochas Okorocha

Oríṣun àwòrán, Rochas okorocha/ twitter

Ninu fidio kan ti o jẹyọ loju opo Twitter ileeṣẹ iroyin Channels Television, awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC ṣu jọ si gbagede ile Sẹnetọ Okorocha.

Wọn faake kọri pe o di igba ti Oloye Rochas Okorocha ba jọwọ ara rẹ ki wọn muu lọ ki awọn to lee fi agbegbe naa silẹ.

Bakan naa ni wọn tun gbegi di gbogbo ọna to wọ agbegbe ile naa ti wọn si n lerileka pe ko si eyikeyi ninu mọlẹbi Okorocha ayafi ti wọn ba jọwọ rẹ fun wọn ki awọn to kuro nibẹ.

Aworan gbagede ile Rochas Okorocha

Oríṣun àwòrán, Screenshot/channelstv

O digba ti mo ba ri iwe igbayọnda ofin lati mu mi ki n to yọju si EFCC- Rochas Okorocha

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa, gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Imo naa koro oju si igbesẹ̀ ajọ EFCC naa to si ni wọn wa ha oun mọ ile oun ni.

Bakan naa lo ṣeleri pe oun ko nibi kan lati lọ, inu ile oun loun yoo si duro si titi di igba ti wọn ba fi iwe igbayọnda ofin lati mu oun han oun.

"Eyi buru jai, mi o si mọ ohun gan to n ṣẹlẹ ni pato. Nibi yii ni emi yoo wa o titi ti maa fi mọ ohun ti wọn n fẹ. Mo fẹ ri iwe igbayọnda ofin lati mu mi tabi aṣẹ ile ẹjọ."

Àkọlé fídíò, Amputee: Toheeb Abiodun Olaniyan: Ẹ̀rọ lílọ̀ ní ẹni ọdún mẹ́sàn án ni apa kan mi lọ sí

EFCC gbe Rochas lọ sile ẹjọ fun kiko N2.9 biliọnu jẹ

Ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kini ni EFCC gbe ẹsun tuntun to nii ṣe pẹlu kiko biliọnu mẹta o din ọgọrun ẹgbẹrun naira, N2.9 biliọnu jẹ.

EFCC fa Okorocha, ẹni to n ṣoju ẹkun iwọ oorun Imo nile aṣofin agba Naijiria, lọ siwaju ile ẹjọ giga apapọ nilu Abuja pẹlu ẹsun pe o lẹdi apopọ pẹlawọn eeyan kan ati ile iṣẹ marun un kan lati ji owo ilu ko sapo.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí BBC fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ohun tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ń gbé sorí ayélujára

Rochas Okorocha ti sẹ ẹsun yii to si ni kii ṣe igba akọkọ niyi ti ajọ EFCC yoo maa doju kọ oun bẹẹ.

Okorocha to ni igbesẹ EFCC n lọwọ oṣelu ninu ṣalaye pe gbogbo aṣẹ ti ile ẹjọ ti pa fun wọn ni wọn n keti ikun si.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold