Timothy Adegoke: Ẹlẹ́rìí ẹjọ́ ikú Timothy Adegoke ṣàlàyé fún ilé ẹjọ́ pé Ọlọ́pàá fipà mú òun láti bu wọ lùwé àkọsílẹ̀ 'statement' òun ni

ILE ẸJỌ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Iléẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ lórí ikú Timothy Adegoke sí ọjọ́ Aje

Ileẹjọ giga ipinle Osun ti o gbọ ẹjọ lori iku Timothy Adegoke akẹkọọ Fasiti Obafemi Awolowo ti sun igbejo si ọjọ́ Aje.

Adajo Adepele Ojo so elẹyi lẹyin ti agbejoro fun ookan lara awọn afurasi, Ita Edet Okon ni awọn ẹlẹrii oun o ri aye lati yoju si Ile ejo ni oni.

Àkọlé fídíò, 'Ó ṣì wù mí kí n fi ojú mi ríran padà, owó India ni kò sí! Hip hop yìí nìkan ni mo fi ń gbéra'

Okon ro ile ejo giga ipinle Osun lati fun awọn ẹlẹrii ni anfani lati wa si ile ẹjọ ni ojo Aje.

Lẹyin ti Agbejoro Ita Edet Okon ro ile ejo ni Adajo Adepele Ojo wa sun igbejo si ọjo Aje ti o jẹ ogbon ọjọ, oṣu karun-un, ọdun 2022.

Mi ò mọ nǹkan kan nípa 'receipt' ṣùgbọ́n èmi ní mó kó Ẹ̀dá ìwé account- Adeniyi Aderogba, ẹlẹ́rìí ẹjọ́ ikú Timothy Adegoke

Alamojuto ilé itura Hilton hotel, Ogbeni Adeniyi Aderogba sọ fun Ile ejo giga ipinle Osun pe oun o ko mọ nǹkan kan nipa bi wọn ṣe fun oloogbe Timothy Adegoke ni recipt sugbọn ohun ni o ko eda

iwe account ti wọn gbe fun awọn olopaa.

Iwe account ni Adeniyi Aderogba ṣe eda rẹ miiran ti ko ni oruko Timothy Adegoke gege alejo akoko lẹyin ti afurasí miiran Adedeji Adesola ko orúkọ oloogbe naa silẹ gege alejo akoko.

Aderogba, ẹni ọdun marundilogoji ní ọmọ oloye Ramon Adedoyin ti o jẹ Roheem Adedoyin ni o pa lase fun oun lati tun iwe account miiran ko.

O tesiwaju lati sọ fun Adajo Adepele Ojo pe awọn olopaa ipinlẹ Osun fi agidi mo oun lati gba ohun lenu oun ati pe pẹlu agídí ni oun fi ti owo bo iwe àkọsílẹ̀ fun Ile ise olopaa.

Aderogba tun so fun Ile ejo giga ipinle Osun pe oun pẹlu Oyetunde Kazeem ati Roheem Adedoyin lati gbe oku Timothy Adegoke lọ sí Ede road pẹlu oko funfun Hilux.

"Magdalene Chiefuna ni o pe mi lẹyin tí ati gbinyanju lati pe alejo to wa ninu yara 305 tí ko si da wa lohun.

"Chiefuna ni oun ti rí eda kọkọrọ fun yara 305 tí òun si ba oku Timothy Adegoke ni o ri bedi to sun si, mo gbera lati lọ si ile ìtura naa lati woo nkan ti o sele.

"Emi pẹlu Magdalene Chiefuna lọ sí inu yara naa lati woo nkan ti o sele, orun naa poo gan tí mo si fi owo bo imu mi.

"Mo gbe ero ibanisoro mi láti pe Chairman Ramon Adedoyin, mọ salaye fun wọn ti wọn si ni awọn ma pe Roheem Adedoyin lati fi to ilé olopaa leti.

"Nigba ti Roheem Adedoyin de, a jọ lọ si inu yara naa ti a si ba oku Timothy Adegoke nibe. Roheem Adedoyin sọ fun mi pe oun fe lọ sí odo àwọn olopaa, lẹyin ọpọlọpọ wakati tí a fi rẹ tí Roheem Adedoyin.

"Roheem Adedoyin pada de ni asalale ti o si ni oun ti sọ fun awọn olopaa ti wọn si ni kí awọn ma gbe oku Timothy Adegoke lọ si ile oku ni ile eko giga fasiti Obafemi Awolowo Teaching Hospital.

"Ṣugbọn Roheem Adedoyin kọ lati gba ona ile eko giga fasiti Obafemi Awolowo ti o mú orí le ona ede road.

"Roheem Adedoyin gbe oku Timothy Adegoke kuro lẹyin oko lilux funfun ti o si gbe si ọna pẹlu bagi rẹ.

" Mo bi Roheem Adedoyin idi ti a fi gbe oku Timothy Adegoke lọ sí Ede road, O ni eru olopaa ba oun.

Adeniyi Aderogba tun wa sọ ile ejo giga ipinle Osun pe pẹlu agídí ni awọn olopaa fi gba ohun lenu oun lori iku Timothy Adegoke.

Agbejoro M.O Omashun bere lọwọ Arakunrin Adeniyi Aderogba pe boya o ri eje nigba ti o se ayẹwo si oku Timothy Adegoke nínu yara 305.

Ninu akọsilẹ ti Adeniyi Aderogba sọ fun awọn olopaa, o ni oun ri ẹ̀jẹ̀ ninu imu ologbe Timothy Adegoke nigba ti o ayẹwo si yara 305.

"Ikan ti mo ri nigba ti mo ṣe ayẹwo sì oku Timothy Adegoke nínu yara 305 ki n se eje rara sugbọn awọn olopaa fi lilu alubami gba ohun mi si ile

Adeniyi Aderogba tesiwaju pe oun ko kopa ninu ipade tabi imule kankan ni ile dokita Ramon Adedoyin lẹyin isele naa

"Mio fi oju mi kan dokita Ramon Adedoyin tabi lọ si ile wọn láti mule kankan.

"Nigba ti a de agoo olopaa ni mo ri dokita Ramon Adedoyin soju.

Àwa mẹ́ta la gbé òkú Timothy Adegoke lọ sí Ede road- Ẹlẹ́rìí Oyetunde Kazeem

Ọkan lara awọn afurasi tí o jẹri lori iku Timothy Adegoke, Oyetunde Kazeem ni Roheem Adedoyin ni o siwaju bi awọn ṣe gbé oku Timothy Adegoke lati ile ìtura Hilton Hotel Honour lọ sí Ede road niluu ile ife.

Oyetunde, ẹni to je osise ìle itura Hilton Hotel ni ọmọ Adedoyin woo oku naa pẹlu asọ duvet tí o fi bora.

O ni ọmọ Adedoyin ni eru olopaa ba ohun ni oun ṣe gbẹ igbese naa.

Ninu oro afurasi naa o ni oun pẹlu monija ile ìtura Adeniyi Aderogba ranse pe Roheem Adedoyin pe eeyan ti ku si ninu yara 305

"bi Roheem Adedoyin ṣe de, o gba kọkọrọ, o si ni kí a tẹlẹ oun lọ sí ninu yara naa.

"A ba oku Timothy Adegoke lori bed pẹlu laptop ati ero ibanisoro rẹ. Roheem Adedoyin ni ki a bosi ita pe oun fe lọ fi to olopaa leti.

Timothy Adegoke ati Ramon Adedoyin

"Nigba ti o di ale, Roheem Adedoyin pa da si ile ìtura pe oun ti ba awọn olopaa soro tí wọn si ki wọn gbẹ oku naa lọ si ile oku.

"A gbe oku naa si inu oko lilux funfun sugbọn o ya mi lenu nigba ti a mori le ona Ede road. Mo bere lowo Roheem Adedoyin sugbon ko dami lohun.

"Nigba ti a de ibi kan, Roheem Adedoyin pana moto ti o si woo oku naa si egbe ona pẹlu aso duvet, laptop ati ero ibanisoro silẹ.

"Mo tun bi Roheem Adedoyin idi ti a fi gbe oku Timothy Adegoke lọ si ede road, O sọ fun mi pe eru olopaa ba oun pupo nitori pe nnkan miiran le jade."

Oyetunde Kazeem wa fi idi e mule pe oun ko kopa ninu bi awọn akẹgbẹ ṣe múlẹ.

Timothy Adegoke ati Ramon Adedoyin

Oríṣun àwòrán, others

Ni ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2022 yii ni igbẹjọ lori iku oloogbe Timothy Adegoke n tesiwaju nile ẹjọ giga ni Osogbo

Dókítà mìíràn takò esi ayẹwo ara, Òṣìṣẹ́ Hilton Hotel jẹwọ pe otitọ nipé awon múlẹ

Ni ana ode yi ojo kedogbon osu karùn-ún ọdun 2022 ni igbẹjọ lori iku Arakunrin Timothy Adegoke tesiwaju,

Skip Facebook post, 1

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 1

Igbejo beere pẹlu ohun iyalẹnu fun awọn akoroyin lẹyin ti Dokita Rahmon Adedoyin bẹrẹ si i ṣepe fun wọn pe awọn ti o n ya fọto oun.

falana
Skip Facebook post, 2

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 2

Adedoyin lo ni ileetura Hilton to wa niluu Ileefẹ, nibi ti akẹkọọ Fasiti OAU kan, Timothy Adegoke, ku si loṣu Kọkanla, ọdun to kọja.

Adedoyin ati awọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa ni wọn n jẹjọ lori ẹsun bii mọkanla ti wọn fi kan wọn.

Loṣu kan sẹyin to yẹ ki awọn olujẹjọ bẹrẹ awijare wọn niwaju Onidaajọ Adepele Ojo ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun ni agbẹjọro fun Adedoyin, Barisita Ẹlẹja (SAN), sọ pe ko ni ẹlẹrii kankan lati pe.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Dokita ẹni tí ó jẹ ojogbon lati ile eko giga fasiti Obafemi Awolowo Teaching Hospital, Olusegun Silvester Ojo ni esi ayẹwo ara ti wọn akẹgbẹ oun se lori iku Timothy Adegoke ni ko waye laito, ti oun si keyin si ọpọlọpọ oun ti wọn gbẹ jade ati pe ko si nnkan to jọ pe ẹjẹ n da lati inu wa.

Ojogbon Ojo naa pẹlu Dokita Akin Komolafe ni ayẹwo wọn yato esi ayẹwo awọn dokita mẹfa to ṣe ayẹwo ara Timothy Adegoke lẹyin tí wọn gbẹ oku rẹ ni Ede road niluu ile ife.

Àkọlé fídíò, Amputee: Toheeb Abiodun Olaniyan: Ẹ̀rọ lílọ̀ ní ẹni ọdún mẹ́sàn án ni apa kan mi lọ sí

Ní afikun, okan lara awọn afurasi to jẹjọ lori iku Timothy Adegoke, Magdalene Chiefuna sọ fun Ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun ni ana pe otitọ ni awọn mulẹ lati maṣe sọ ọrọ lori iku Timothy Adegoke fun ẹnikẹni lẹyin iṣẹlẹ naa.

Chiefuna, ẹni ọdun mẹ́rìnlélógún, akẹkọọ fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ to tun jẹ ọkan lara awọn òṣìṣẹ́ ìle itura Hilton Hotel ni ilu Ile-Ifẹ lo fi idi ọrọ náà mulẹ nigbati o dahun ibere lati ọwọ agbejoro Fẹmi Falana.

Àkọlé fídíò, Lasisi Jasper:Wo ìtàn ayé ọ̀gọ́ àgbà iléẹ̀kọ́ Adeniran Memorial ni Ogbomoso

Ó ni idi ti awọn fi múlẹ lati ma sọ fún ẹni kankan ni làti dabo bo ilé itura Hilton hotel.