PDP Presidential Primaries 2022: Lẹ́yìn tó gba tíkẹ́ẹ̀tì, ṣé Atiku lè dé èbúté ògo ààrẹ Nàìjíríà ní 2023?

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar
O ti di ootọ fawọn to n ro pe ko le jẹ bẹ ati awọn alatilẹyin rẹ naa to n gbadura ko ri bẹ.
Atiku Abubakar Igbakeji aarẹ Naijiria nigba kan ri ni wọn gbe asia ẹgbẹ Peoples Democratic Party le lọwọ ko dije dupo aarẹ lọdun 2023.
Ibo 371 ni Atiku ri gba to fi ja awọn akẹgbẹ rẹ toku silẹ.
Ninu wọn ni Gomina Nyesom Wike to gba ibo 237, ati Sẹnẹtọ Bukola Saraki to ri ibo 70
Ninu ọrọ rẹ sawọn to wa nibi eto idibo abẹnu ẹgbẹ, Atiku ni oun yoo giynaju lati da isọkan pada si orileede Naijiria.
Bẹẹ lo leri lati doju ija kọ ipenija aabo,eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ ati awọn nkan miran.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@atiku
Tinubu, awọn mii ki ku oriire
ẹwẹ eekan ẹgbẹ oselu APC nii Bola Ahmed Tinubu ti ki Atiku ku oriire aseyọri rẹ.
Ninu ọrọ rẹ o sọ pe:''Mo fi ayọ gba iro pe Atiku ni oludije to jawe olubori lati du ipo aarẹ labẹ asia PDP ninu idibo abẹnu to waye''
''Mo n reti lati koju rẹ gẹgẹ bi akẹgbẹ to munadoko ninu idibo aarẹ to de tan''
Ohun nikan kọ, awọn miran bi Gomina Godwin Obaseki ati Duoye Diri ti Bayelsa ti ẹgbẹ PDP naa fi ọrọ ikinin ransẹ si Atiku.
Duoye Diri sọ loju opo Facebook rẹ pe ''Mo ki Alhaji Atiku Abubakar ku orire pe o jawe olu bori lati di oludije ẹgbẹ wa ninu idibo aarẹ''

Oríṣun àwòrán, Other
Se lọtẹ yi ti yoo jẹ igba kẹfa ni ọwọ Atiku Abubakar yoo tẹ eku ida?
Odu ni Atiku Abubakar kii se aimọ fun oloko lagbo oselu Naijiria.
Bi a ba ni ka ka ni meni meji, eleyi ni yoo jẹ igba kẹfa ti yoo dije ipo aarẹ.
Saaju igba to pada wa jẹ igbakeji aarẹ Olusegun Obasanjo si ni o ti ni erongba yi.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to se laipẹ o ni oun ni ireti pe lọtẹ yi, ọwọ oun yoo tẹ ipo aarẹ Naijiria.
O ni igba mẹ́rin ọtọọtọ loun gbiyanju lati jẹ Gomina Adamawa ki o to wa di imusẹ ni igba kẹrin.
Ni ọdun 1993, o koju MKO Abiola nibi idibo abẹnu ẹgbẹ Social Democratic Party, SDP sugbọn o fidirẹmi.
Ni 2007, labẹ asia Action Congress o tun fidi rẹmi lọwọ Umaru Yar Adua ti ẹgbẹ PDP.
Bakan naa ni 2011 Atiku gbiyanju lati de ipo aarẹ sugbọn aarẹ tẹlẹ Goodluck Jonathan lo ja ireti rẹ kulẹ.

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar
Lọdun 2014, o darapọ mọ All Progressives Congress lati kopa ninu idibo abẹnu ẹgbẹ naa fun tikẹẹti aarẹ.
Aarẹ Muhammadu Buhari ni kini naa ja mọ lọwọ
Ewẹ ni 2017, o pada si Peoples Democratic Party, PDP. Ni 2019 o ri tikẹẹti ẹgbẹ gba lati dije ipo aarẹ labẹ asia PDP.
Muhammadu Burai yi kanna lo tun ja kulẹ ti ko jẹ ko ribi de ipo aarẹ
Bẹẹ si ni aarẹ Buhari yi naa ti fidirẹmi ni ẹmẹẹta ọtọọtọ ki oun naa to wa pada di aarẹ Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Di major opponents wey Atiku Abubakar fit likely face for 2023
Bayi ti a ti mọ pe Atiku ni PDP yan loludije, awọn wo ni yoo koju rẹ lati du ipo aarẹ?
Yemi Osinbajo seese ki o jẹ ẹni ti yoo ba du ipo yi gẹgẹ bi ẹni to ti jẹ igbakeji aarẹ ri
Iyẹn ti wọn ba fun ni tikẹẹti ẹgbẹ oselu APC ninu idibo abẹnu to n bọ lọna.
Bẹẹ naa ni agbaọjẹ oloselu to tun jẹ ọrẹ Atiku, Bola Ahmed Tinubu naa n foju sun ipo yi.
Minisita feto irinajo Naijiria Rotimi Amaechi naa n wa tikẹẹti APC to fi mọ awọn miran.
Idibo abẹnu ẹgbẹ APC ni yoo tọka ibi ti adagba eto yo rọ re si.
Peter Obi to ti wa lọ si ẹgbẹ Labour Party lati PDP naa wa lara awọn taa n wo pe o le fa da agbo Atiku sina.

Oríṣun àwòrán, Other
Ohun taa mọ nipa Atiku
Ọmọ bibi ipinlẹ Adamawa ni Atiku Abubakar jẹ to si ti gbiyanju lati jẹ aarẹ Naijiria nigba mẹfa
Oloselu to jẹ onisowo bakan naa ni Atiku bubakar.
O gbiyanju lati de ipo Gomina Adamawa ni igba meji iyẹn ọdun 1990 ati 1998 ki o to pada wa jẹ Gomina ipinlẹ naa ni ọdun 1999.
Ni 1993 o koju MKO Abiola ninu idibo abẹnu fun oludije aarẹ labẹ asia ẹgbẹ Social Democratic Party.
MKO Abiola fidirẹ rẹmi ninu idibo yi.
Eya Fulani ni Atiku Abubakar jẹ to si mọ awọn eeyan daada jakejado Naijiriia.
Ninu awọn ti o to gbangba sun lọyẹ lati dije ipo aarẹ lo wa.
Koda awọn alatako rẹ naa gba pe bi eeyan kankan ba wa to le ba wọn fa fun ipo yi, Atiku lẹni naa.
O wa ku ka mọ ni ti yoo koju ninu idibo aarẹ bayi ati pe se awọn to dibo yan saaju to fi gbe ipo keji lẹyin uhari setan lati gbe de ipo aarẹ.
Yoo soro diẹ sugbọn gẹgẹ bi ohun gbogbo to nise pẹlu oselu Naijiria, bi ilẹ ko ba su, enikan kii palẹmọ ọja kuro nilẹ lati lọ sile.












