APC primaries list: Ìwé orúkọ àwọn olùdíje tó bórí ìbó abẹ́nú gómìnà ní APC

Oríṣun àwòrán, Others
Ni kete ti asiko ti ajo eleto idibo fun awọn ẹgbẹ oṣẹlu ti n kan ilẹkun gbọngbọn ni pọpọ ṣinṣin ti bẹrẹ kaakiri.
Opọ ẹgbẹ oṣelu lo tun ile iya ẹgbẹ ṣe ti wọn si fi gbendeke sii iye owo gbigba fọọmu idije ati asiko to tọ.Ẹgbẹ́ òṣèlú APC Oyo sún ètò ìdìbò abẹ́nú sí òní, ìdí rèé
Lẹyin naa ni eto ipolongo ati eto idibo bẹrẹ kaakiri awọn ipinlẹ.
Bi awọn kan ṣe n jawe olubori ni awọn mii n fidiremi.Ìwé orúkọ àwọn olùdíje tó bórí ìbó abẹ́nú gómìnà ní APC
Gomina Sanwo Olu- ipinle Eko, Dapo Abiodun- ipinle Ogun ati Abdularamon Abdulrazak- Ipinle Kwara ti jawe olubori lati dije ni abẹ APC.
- Ohun ìbànújẹ́ ló ṣẹlẹ̀ ní Anambra, ẹ dákún mi ò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni fi oró ya oró lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà- Buhari
- Ìjoba ti fi èsùn ìpànìyàn kan oko Osinachi, Peter Nwachukwu
- Iléẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ lórí ikú Timothy Adegoke síwájú, Wo ohun tó fàá....
- Olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ rédíò Agidigbo, Oriyomi Hamzat ti gba ìtúsílẹ̀
- Mọ̀ síi nípa àwọn tó máa díje dupò gómìnà lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ PDP lẹ́yìn tí wọ́n ti yegé nínú ìdìbò abẹ́lé
- Ọlọ́pàá fipá mú mi láti buwọ́lu 'Statement'ti mí ò kọ̀ fúnra mi nípa ikú Timothy Adegoke-Adeniyi

Oríṣun àwòrán, dapo abiodunmfr/twitter
Bakan naa ni gomina Mai Mala Buni jawe olubori lati tesiwaju ni ipinle Yobe
Gomina Zulum n tesiwaju labe APC ni ipinle Borno
Gomina Inuwa n soju APC ni ipinle Kebbi
Nigba ti gomina Abullahi Sule n t4esiwaju lati dije dupo ni ipinle Nasarawa.
Ìwé orúkọ àwọn olùdíje tó bórí ìbó abẹ́nú gómìnà ní APC
Lẹyin ọpọlọpọ kukukẹkẹ lati gbaradi fun idibo ọdun 2023, aworan bi awọ̀ọn oludibo yoo ṣe ri kaakiri ẹgbẹ oṣelu ti n gbera sọ bayii.
Lọjọbọ ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2022 lẹgbẹ oṣelu APC ṣeto ibo abẹnu lati yan awọn oludije fun ipo gomina kaakiri awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria.
Laideena pẹnu, oniruuru iṣẹlẹ awodamiẹnu lo waye lawọn ibudo idibo abẹnu naa kaakiri orilẹede Naijiria.
Eyi wa ni bi awọn to gbegba oroke ṣe bori.
- Àwa mẹ́ta la gbé òkú Timothy Adegoke lọ sí Ede road- Ẹlẹ́rìí Oyetunde Kazeem
- Ọmọ ọdún 19 tí wọ́n sọ sí ẹ̀wọ̀n nitorí ọ̀kadà tó sọnù ti kú
- Gbajúmọ̀ Olórin Banky W ti rí tíkẹ̀ẹ̀tì ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbà láti díje dupò aṣòfin
- Ìjọba kéde òfin kónílé-ó-gbélé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án ní ìpínlẹ̀ Anambra
- Mà á dá fijilanté sílẹ̀, òmìnira á wà fún ìjọba ìbílẹ̀ láti ná owó wọn- Oluwole Oluyede
- Ohun ìbànújẹ́ ló ṣẹlẹ̀ ní Anambra, ẹ dákún mi ò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni fi oró ya oró lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà- Buhari
- Àwọn ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí mọ́kànlá pàdánù ẹ̀mi wọn lẹ́yìn iná tó ṣẹ́yọ
- Oriyomi Hamzat wọ gbaga ọlọ́pàá nítorí ọ̀rọ̀ Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura Rahman Adedoyin
- Wo ojú àwọn tó fẹ́ díje dupò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Oyo lónìí

Oríṣun àwòrán, Babajide sanwo-olu/twitter
Eko akete gbe Sanwo-olu lẹẹkeji
Gomina Babajide Sanwo-Olu lo bori ibo abẹnu ni ipinlẹ Eko. Ibo kolatako ni wọn ṣe fu n un.
Eyi waye lẹyin ti iroyin jade pe awọn meji to ku ti wọn n baa du oye naa- kọmiṣọna fohun amuṣagbara nipinlẹ Eko tẹlẹ, Wale Oluwo ati akọwe agba tẹlẹ nilleṣẹ ohun amugbara yii kan naa, Mustapha Ọlọrunfẹmi- ko kogoja
Iyen, ninu eto ayẹwo ti wọn ṣe fawọn oludije ẹgbẹ fun ipo gomina lolu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa nilu Abuja.

Oríṣun àwòrán, dabiodunMFR/twitter
Laarin ọpọlọpọ awuyewuye, Dapọ Abiọdun yọ ni ipinlẹ Ogun
Oludije marun un miran lo ba gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun figagbaga fun aṣia ẹgbẹ APC, amọṣa Gomina Abiọdun bori pẹlu ibo ẹgbẹrun kan ati mejidinlaadọsan, (1,168)
Amọṣa, meji ninu awọn oludije naa, Adekunle Akinlade ati Biyi Ọtẹgbẹyẹ ni wọn ti tako alaga igbimọ idibo ti ẹgbẹ oṣelu naa fi ranṣẹ si ipinlẹ naa, iyẹn ọgbẹni Wale Ohu
Awọn oludije naa sọ ọ ninu atẹjade kan ti wọn jumọ fọwọ si tun kọminu lori iwe orukọ awọn aṣojudibo ti wọn lo fun idibo abẹnu naa.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Ni ipinlẹ Rivers
Tonye Cole lo bori ibo abẹnu fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Rivers.
Ibo ọrinlelẹẹdẹgbẹrun o le mẹfa, (986) lo ni.
Bi idibo naa si ṣe lọ niyi:
Michael West 43,
Tonye Cole Patrick 986,

Oríṣun àwòrán, Babajide sanwo-olu
Bernard Mikko 2,
Magnus Abe 1,
Sokonte Davies 49,
Ojukaye 190.
Buni bori ni Yobe
Alaga igbimọ afunṣọ ẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹ, Mai Mala Buni lo bori fun aṣia ẹgbẹ oṣelu APC lati dije fun ipo gomina nipinlẹ naa.
Buni ni ibo marunlelẹgbẹrin ninu ẹgbẹrin ati aadọrun ibo, (890) to wa nilẹ.
Ko si ẹni to ba Buni du aṣia ẹgbẹ naa gẹgẹbi alaga igbimo alakoso ibo naa, Umar Lawan Kareto ṣe sọ.
Nwifuru firu yọ wọn nipinlẹ Ebonyi
Họnọrebu Ogbonna Nwifuru lo bori nipinlẹ Ebonyi pẹlu ibo ojilelẹẹdẹgbẹrin ati mẹta, (743)
Awọn oludije to ku ni Rosemary Okofe, Ucha Ali Julius, Edward Nkwegu, ati Elias Mbam.
Matawalle gba Zamfara
Gomina Bello Matawalle lo bori ni ipinlẹ Zamfara.
Alaga igbimọ alakoso ibo abẹnu nipinlẹ Zamfara, Babagana Tijani kede matawalle pẹlu ibo ẹẹdẹgbẹrinle mẹtalelọgbọn.
Gomina Matawalle wọle lalailatako lẹyin ti gbogbo awọn to fẹ baa dije yọwọ kuro lawọ idije naa.
Emenike gbegba oroke ni Abia
Oloye Ikechi Emenike ni awọn aṣojudibo yan nipinlẹ Abia lati gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu APC lasiko idibo fun ipo gomina ti yoo waye lọdun 2023.
Awọn meje ni wọn jumọ ra fọọmu idije fun ipo gomina ẹgbẹ oṣelu APC nibẹ ṣugbọn mẹta ninu awọn mẹfa yoku binu jade kuro nibudo idibo naa lori ẹhonu pe eto idibo boo roju mi oo rinu mi, Indirect process ni wọn lo fun idibo abẹnu naa.

Oríṣun àwòrán, other
Sẹnetọ Ọmọ agege ni Delta.
Igbakeji aarẹ ileegbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Ovie Omo-Agege ni aṣia oludije ipo gomina ẹgbẹ oṣelu bọ si lọwọ ni ipinlẹ Delta.
Awọn ẹgbẹkan ati aadọwaa oludibo (1190) lo tẹka fun un.
Zulum ni APC fa kalẹ ni Borno
Gomina ipinlẹ Borno lọwọlọwọ, Ọjọgbọn Zulum ni awọn aṣojudibo fa kalẹ lẹẹkeji pẹlu ibẹ ẹgbẹrun kan ati irinwo o le mọkanla, (1411)

Oríṣun àwòrán, Governor nasarawa/ twitter
Nasarawa ati Sule
APC Nasarawa fa gomina ipinlẹ naa, Onimọ ẹrọ A.A. Sule kalẹ gẹgẹbi oludije wọn fun ipo gomina lasiko idibo apapọ ọdun 2023.
Gbogbo awọn aṣojudibo lati wọọdu mẹtadinlaadọjọ̀, 147 to wa kaakiri ijọba ibilẹ mẹtala ni ipinlẹ naa lo dibo fun gomina Sule.
Inuwa Yahaya ni APC gbe ni Gombeapc
Gomina ipinlẹ Gombe lọwọlọwọ, Muhammadu Inuwa Yahaya lo bori.
Oun pẹlu ko latako lasiko idibo naa.





















