PDP primaries list: Mọ̀ síi nípa àwọn tó máa díje dupò gómìnà lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ PDP lẹ́yìn tí wọ́n ti yegé nínú ìdìbò abẹ́lé

Olubori PDP

Oríṣun àwòrán, @RSGH

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Àwọn tó díje dupò gómìnà tó borí nínú ìdìbò abẹ́lé PDP rè éSeyi Makinde ni PDP gbade fún láti díje dupò gómìnà Oyo lẹ́ẹ̀kán síi nínú ìdìbò abẹnu yìí

Orukọ awọn to laluyọ lati dije du ipo gomina ninu idibo gbogboogbo ni Naijiria labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ti jade lẹyin idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu naa.Ìdí tí mo fi fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ - Peter Obi

Kaakiri orilẹede Naijiria ni idibo naa ti waye ni Ọjọ Karundinlọgbọn, Oṣu Karun un, ọdun 2022.

Awọn idibo abẹle to lamilaaka ni ti ipinlẹ Delta ati ti Rivers.

Lara awon ipinle miran ti idibo abele ti waye ni ipinle Oyo, Benue, Adamawa, Delta, Kaduna, Taraba, Bauchi, Abia, Akwa Ibom ati bẹẹ bẹ̣e lọ.

Ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC lo ṣakoso eto idibo naa ti awọn ẹṣọ alaabo naa si peju sibẹ wamuwamu.

Ọjọ kẹta , Oṣu Kẹfa ni gbedeke ti Ajọ to n risi eto idibo ni NaIjiria, INEC fun awọn ẹgbẹ oṣelu lati ṣe idibo abẹle wọn.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Adamawa:

Gomina Umaru Fintiri to n dije dupo fun saa keji lo bori ninu eto idibo naa.

Ibo 663 ninu 668 lo fi jawe olubori

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Oyo

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde to n dije dupo gomina fun saa keji lo bori ninu idibo abẹle naa

Ibo 1,040 ninu 668 lo fi bori Hazeem Gbolarunmi ti wọn jọ figagbaga.

Àkọlé fídíò, Ayodeji Rotinwa ni ìròyìnn òfegè gbé àwòrán rẹ̀ síta pè dókítà tó ń pa àwọn Hausa mùsùlùmí

Benue

Abẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin, Titus Uba lo bori ninu eto idibo naa.

Ibo 731 lo fi ṣajulọ fun igbakeji gomina Benue, Benson Abounu ti wọn jọ figagbaga.

Àkọlé fídíò, Amputee: Toheeb Abiodun Olaniyan: Ẹ̀rọ lílọ̀ ní ẹni ọdún mẹ́sàn án ni apa kan mi lọ sí

Enugu

Ọjọgbọn Eleazar Ikonne lo bori ninu eto idibo naa.

Oun ni ọga agba fasiti ipinlẹ Abia tẹlẹri.

Àkọlé fídíò, 'FUJI níkan ni ‘beat’ tó jẹ́ àṣà wa, ‘Highlife’ kìí ṣe tiwa, kò sóhun tó jọ pé àwọn ọmọ Sàtání ló ń kọ Fuji Gospel'

Delta

Abẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin ipinlẹ Delta, Sheriff Oborevwori lo bori ninu eto idibo naa.

Ibo 597 ninu 826 lo fi jawe olubori.

Àkọlé fídíò, Títí ayé yóò fi parẹ́, wọ́n ó máa sọ̀rọ̀ sí Ànọ́bì ni, wọ́n ó sì máa bú Jésù ni, ẹ wá gbọ́ òótọ́ ohun tí Quaran sọ – Akeugbagold

Rivers

Akapo ipinlẹ Rivers tẹlẹri, Fubara Siminialayi lo bori ninu eto idibo naa.

Ibo 721 lo fi jawe olubori.

Àkọlé fídíò, Tàá bá lè bá àwọn ọmọ tó pa Deborah ní Sokoto sọ̀rọ̀ pé ìwà ẹranko ni wọ́n hù, ó burú - Òṣèré Sokoti

Akwa Ibom

Komisọnna fun ọrọ ilẹ ati omi tẹlẹri nipinlẹ Akwa Ibom, Pasitọ Umo Bassey Eno lo bori ninu eto idibo naa.

Ibo 993 lo fi jawe olubori.

Saaju ni gomina ipinlẹ Akwa Ibom ti kede rẹ gẹgẹ bi ẹni ti yo rọpo rẹ ti o ba fi ipo silẹ.