Oyo PDP Primary: Ta ni yóò jáwé olúborí láàrin Seyi Makinde àti Gbolarumi Hazeem níbi ètò abẹ́nú PDP?

Oríṣun àwòrán, @Seyi Makinde
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde, ti wọle lati dije du ipò gómìnà fun ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party PDP nibi eto idibo abẹlẹ ti wọn ṣẹṣẹ pari ni papa iṣere Lekan Salami, ni ìlù Ìbàdàn.
Makinde ni ibo egberun lona ogoji (1,040 ) lati bori oludije re, Ogbeni Hazeem Gbolarunmi, eni to ni ibo meji.(2)
Idibo ofo mẹfa wa lapapọ ninu ibo ti 1,048 ti wọn ka
Nínú ọrọ àpilẹ̀kọ rẹ Seyi Makinde ṣèlérí ìdàgbàsókè tuntun kaa Kírì ipinlẹ Ọ̀yọ́ gege bi o ti ṣe láàrín odun mẹta tí o n lo lo yii.
- Àwọn agbébọn jí fadá ìjọ Kátólíkì méjì gbé ní Katsina
- Ṣé lóòtọ́ ni Ààrẹ Buhari ti gbaṣẹ́ lọ́wọ́ gómìnà Báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà, Godwin Emefiele?
- Inú ọ̀sẹ̀ yìí ló yẹ kí ìyàwó mi bímọ kí wọ́n tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò Jubril- ọkọ aláboyún Anambra
- Ọmọdé 19 ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìṣekúpani ní iléẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́rẹ̀ Texas
- ASUP ṣetán láti fi kún ìyanṣẹ́lódì - Ezeibe
- Irọ ni pé ẹ̀jẹ̀ ń dà nínú Timothy Adegoke- Ẹlẹ́rìí Adegoke
- MC Oluomo, òpin ti débá gbígba owó orí lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ ní Eko - Iléẹjọ́
- Wọ́n lẹ̀dí àpòpọ̀ mọ́ mi ni mo ṣe fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò abẹ́nú – Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ sẹyin?
Ta ni yóò jáwé olúborí láàrin Seyi Makinde àti Gbolaruni Hazeem níbi ètò abẹ́nú PDP?
Ẹgbẹ òsèlú Peoples Democratic Party, PDP tẹka ipinle Ọ̀yọ́ yoo ṣe eto ìdìbò abẹ́nú fun ipò gómìnà ni gbàgede Adamasingba lonii.
Eto lati yàn ẹni tí yoo gbe asia ẹgbẹ PDP nibi idibo gbogbogboo fun ipo gomina ipinle Oyo yoo wáyé láàárín Gómìnà Seyi Makinde ati Alhaji Gbolarunmi Hazeem ẹni ti o ti jẹ igbá-kejì gómìnà ipinlẹ Oyo nigba kan ri.
Alukoro ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ọ̀yọ́ Akeem Olagunji fìdí rẹ mulẹ pe ẹgbẹrun o le aadọta ní àwọn aṣojú ẹgbẹ tí yoo di ibo làti yàn asoju ẹgbẹ fun ipo gomina ipinle Ọ̀yọ́ ninu egbe PDP.
- Irọ ni pé ẹ̀jẹ̀ ń dà nínú Timothy Adegoke- Ẹlẹ́rìí Adegoke
- Inú ọ̀sẹ̀ yìí ló yẹ kí ìyàwó mi bímọ kí wọ́n tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò - àlàyé rèé lẹ́nu ọkọ aláboyún tí àwọn agbébọn ṣekúpa ní Anambra
- Wọ́n lẹ̀dí àpòpọ̀ mọ́ mi ni mo ṣe fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò abẹ́nú – Dino Melaye
- MC Oluomo, òpin ti débá gbígba owó orí lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ ní Eko - Iléẹjọ́
- EFCC ṣàlàyé ìdí tó fi fípa wọ́lé mú Rochas Okorocha lẹ́yìn tí wọ́n rọ̀jò ìbọn nílé rẹ̀ l'Abuja
- Lẹ́yìn idojúkọ ASUU, LAUTECH kéde pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọlé wa parí sáà ètò ẹ̀kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ tẹ́lẹ̀
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'BBC Yoruba Ekiti Governorship Debate' tí yóò wáyé lọ̀sẹ̀ yìí
- Gbajúmọ̀ Olórin Banky W ti rí tíkẹ̀ẹ̀tì ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbà láti díje dupò aṣòfin
Hazeem gbolarumi ni igbákejì gómìnà ipinlẹ Ọ̀yọ́ nígbà tí otunba Adebayo Alao-Akala jẹ gómìnà ipinle Ọ̀yọ́ 2017 -2011.
Òun lo darí awọn alatilẹyin ẹgbẹ PDP lati yan Rashidi Ladoja gẹgẹ bi gomina ipinle Ọ̀yọ́ ni ọdun 2006.
Yatọ si oṣelu o je agbẹjọro.
Ojo kokanlelọgbọn (31) Osu kẹta lo fi erongba rẹ hàn lati díje du ipo gómìnà ipinlẹ Ọ̀yọ́.

















