Texas Shooting: Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọdé 19 ló kú nínú ìṣekúpani tó wáyé ní iléẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọmọdé 19 ló pàdánù ẹ̀mí wọn ní ìṣekúpani ní iléẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́rẹ̀
Ogo wẹẹrẹ mọkandinlogun ati ọdọlangba meji lo padanu ẹmi wọn nigba ti agbebọn kan ṣina bolẹ ni ileẹkọ alakọbẹrẹ ni Guusu ilu Texas, lorilẹede Amẹrika.
Iṣẹlẹ apanilẹkun naa waye nigba ti agbebọn kan ṣina bolẹ ni ileẹkọ alakọbẹrẹ Robb Elementary School nibi ti awọn olukọ ti n kọ awọn ọmọ ọdun meje si mẹwaa ni ilu Uvalde.
- Irọ ni pé ẹ̀jẹ̀ ń dà nínú Timothy Adegoke- Ẹlẹ́rìí Adegoke
- Inú ọ̀sẹ̀ yìí ló yẹ kí ìyàwó mi bímọ kí wọ́n tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò - àlàyé rèé lẹ́nu ọkọ aláboyún tí àwọn agbébọn ṣekúpa ní Anambra
- Wọ́n lẹ̀dí àpòpọ̀ mọ́ mi ni mo ṣe fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò abẹ́nú – Dino Melaye
- MC Oluomo, òpin ti débá gbígba owó orí lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ ní Eko - Iléẹjọ́
- EFCC ṣàlàyé ìdí tó fi fípa wọ́lé mú Rochas Okorocha lẹ́yìn tí wọ́n rọ̀jò ìbọn nílé rẹ̀ l'Abuja
- Lẹ́yìn idojúkọ ASUU, LAUTECH kéde pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọlé wa parí sáà ètò ẹ̀kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ tẹ́lẹ̀
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'BBC Yoruba Ekiti Governorship Debate' tí yóò wáyé lọ̀sẹ̀ yìí
- Gbajúmọ̀ Olórin Banky W ti rí tíkẹ̀ẹ̀tì ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbà láti díje dupò aṣòfin
Agbebọn naa lo ṣina bolẹ̣ ki eṣọ alaabo to pa agbebọn naa.
Iwadii fihan pe afurasi ẹni ọ̣dun mejidinlogun naa ni o gbebon AR semi -automatic rifle, to si ti kọkọ yinbọn pa iya rẹ agba ko to lọsi ileẹkọ naa.
O si ṣeeṣe ki afurasi aṣekupani naa jẹ akẹkọọ ni ileẹkọ giga ni agbegbe naa, to si da bi ẹni pe oun tika lara rẹ lo ṣe ohun to wu u laisi ẹlomiran to mọ si.
Gomina ilu Texas, Greg Abbot ni agbebọn ti o pe oruko rẹ ni Salwador Ramos wa ọkọ gunlẹ, ki o to wọ ileẹkọ naa.
Ileeṣẹ iroyin nilẹ Amẹrika daruko ọmọ meji ninu awọn mokandiinlogun to ku naa.
Tisa ileeḳo naa ti orukọ re n jẹ Eva Mireles naa kagbako isekupani to waye naa.
Okan lara awon obi to padanu omo re ko si oju opo ikansiraẹni Facebook rẹ ni ọmọ oun Amerika ni wọn ti pa, to parọwa si awọn eniyan rẹ pe ki wọn ma tabuku mọlẹbi wọn.
O ni ki wọn di mo ̣wọn lat igba de igba ki wọn si sọ fun wọn pe wọn fẹran wọn.
Awọn akẹ̣kọ̣ọ ịleẹko naa to to ẹẹdẹgbẹta ni wọn jẹ ọmọ orilẹede Spain tabi gbungun Amẹrika to n gbe ni Texas.












