Buhari sacks Emefiele: Ṣé lóòtọ́ ni Ààrẹ Buhari ti gbaṣẹ́ lọ́wọ́ gómìnà Báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà, Godwin Emefiele?

Oríṣun àwòrán, other
Iroyin ahesọ kan jade sigboro lowurọ Ọjọru pe aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti gba iṣẹ lọwọ gomina Banki apapọ orilẹede naa, Ọgbẹni Godwin Emefiele.
Oniruuru iroyin lo si ti jade lẹyin rẹ bi awọn ọmọ Naijiria kan ṣe n kan sara ni awọn kan n woye pe igbesẹ naa ko tọna.
Godwin Emefiele bọ si agbami iroyin paapaa julọ lori ayelujara nigba ti iroyin gbe e pe oun naa fẹ dije ati pe awọn ẹgbẹ kan ti ko ara wọn jọ lati ra fọọmu idije fun un.
- Irọ ni pé ẹ̀jẹ̀ ń dà nínú Timothy Adegoke- Ẹlẹ́rìí Adegoke
- Ọmọdé 19 ló pàdánù ẹ̀mí wọn ní ìṣekúpani ní iléẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́rẹ̀ Texas
- Ta ni yóò jáwé olúborí láàrin Seyi Makinde àti Gbolaruni Hazeem níbi ètò abẹ́nú PDP?
- ASUP ṣetán láti fi kún ìyanṣẹ́lódì - Ezeibe
- Inú ọ̀sẹ̀ yìí ló yẹ kí ìyàwó mi bímọ kí wọ́n tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò Jubril- ọkọ aláboyún Anambra
- Wọ́n lẹ̀dí àpòpọ̀ mọ́ mi ni mo ṣe fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò abẹ́nú – Dino Melaye
Gbogbo eeyan lo pariwo sita nigba naa pe o ku diẹ kaato.
Awọn eekan bii Oby Ezekwesili, Amofin agba Fẹmi Falana, SAN, ẹgbẹ oṣelu PDP atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ni wọn pariwo pe ko fi ipo silẹ to ba fẹ dije fun ipo kankan gẹgẹ bi ẹtọ rẹ gẹgẹbi ọmọ Naijiria labẹ ofin.
Lẹyin igba naa ni Emefiele gba ile ẹjọ lọ lati bere fun alaye lori boya oun lẹtọ tabi oun ko lẹtọ labẹ ofin lati dije fun ipo aarẹ Naijiria lai kọwe fi ipo silẹ gẹgẹ bi gomina banki apapọ Naijiria.
Ṣe lootọ ni Aarẹ gbe igbesẹ yii?
Gbogbo iroyin to n jade lati ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria ko fi idi iroyin yii mulẹ.
Eeyan kan to sunmọ ileeṣẹ aarẹ pẹkipẹki ṣalaye fun BBC pebi awọn eeyan ṣe ji gbọ iroyin naa loju opo Twitter ni pupọ awọn naa gbọ ọ ati pe irọ to jina si otitọ ni.
Lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, ko tii si atẹjade kankan lati ileeṣẹ ijọba Naijiria to fi idi rẹ mulẹ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti yọ Emefiele nipo gẹgẹ bi gomina banki apapọ Naijiria.
- Lẹ́yìn idojúkọ ASUU, LAUTECH kéde pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọlé wa parí sáà ètò ẹ̀kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ tẹ́lẹ̀
- EFCC ṣàlàyé ìdí tó fi fípa wọ́lé mú Rochas Okorocha lẹ́yìn tí wọ́n rọ̀jò ìbọn nílé rẹ̀ l'Abuja
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'BBC Yoruba Ekiti Governorship Debate' tí yóò wáyé lọ̀sẹ̀ yìí
- Gbajúmọ̀ Olórin Banky W ti rí tíkẹ̀ẹ̀tì ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbà láti díje dupò aṣòfin
- Afurasí 4,000 la fi ṣìkùn òfin mú láàrín ọṣù márùn ún- Amotekun Ondo
- Kò sí ààyè fawọn ọdaràn tó ń ṣiṣẹ́ ibi mọ́ ní ìpínlẹ̀ Anambra- Gómìnà Soludo
Ki ni ofin sọ nipa yiyọ gomina BAnki apapọ NAijiria nipo?
Amọṣa bi eeyan ba wo ofin to de idasilẹ ati akoso banki apapọ Naijiria, ko si ọna ti aarẹ lee fi ṣa dede gba iṣẹ lọwọ gomina banki apapọ Naijiria.
Abala kọkanla iwe ofin Centra Bank Nigeria Act 2007' sọ ọ di mimọ pe ida meji ninu mẹta gbogbo awọn aṣofin agba Naijiria ni lati fọwọ si yiyọ gomina Banki apapọ Naijiria ki aarẹ to lee yọ ọ nipo.














