Peter Obi: Peter Obi fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀, kí làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kòtọ́ nínú ẹgbẹ́ PDP tó ní ó ti òun jáde?

Pter Obi

Oríṣun àwòrán, Peter obi

Iroyin kikọwe fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ jẹ eyi to ba ọpọ eeyan lojiji.

Amọṣa, ohun to waye niyi lọjọru lẹyin ti gomina tẹlẹ nipinlẹ Anambra naa fi lẹta ikọwefipo silẹ rẹ han lori ayelujara.

Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Anambra to tun jẹ ọkan lara awọn oludije fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP kede pe oun ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ ninu lẹta to kọ si awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa.

Peter obi ṣalaye ninu lẹta kan to kọ si alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP lolu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa l'Abuja pe lara ohun to jẹ oun logun julọ ni mu ayipada ọtun ba orilẹede Naijiria, amọṣa igbesẹ ati fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ ko din ilepa naa ku.

Iweri fun ipo aarẹ

Oríṣun àwòrán, Peter obi / twitter

Ki ni Peter Obi sọ pe o le oun kuro lẹgbẹ PDP?

Ninu atẹjade kan to fi sita l'Ọjọru, Peter Obi ni awọn iṣẹlẹ kan to n ṣẹlẹ lẹgbẹ oṣelu naa lo mu ko ṣoro fun oun lati tẹsiwaju gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa.

"Iyi nla lo jẹ fun mi lati ko ipa ninu ilakaka lati tun orilẹede yii to nipasẹ ẹgbẹ oṣelu wa. Amọṣa o jẹ ohun ibanujẹ jọjọ pe awọn iṣẹlẹ to n waye laarin ẹgbẹ oṣelu yii bayii jẹ ko le pupọ lati tubọ tẹ siwaju lati maa kopa ninu ilakaka yii."

Lẹta ti Obi kọ fi ipo silẹ

Oríṣun àwòrán, Peter obi / twitter

Peter Obi wa lara awọn oludije to ti ra fọọmu lati du ipo aarẹ orilẹede Naijiria labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP.

Peter Obi ko ṣalaye ni pato idi to fi fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ pẹlu bi ipade idibo yan oludije fun ipo aarẹ naijiria labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu naa ku ọjọ mẹrin pere.

Peter Obi ni oun ti kọkọ kọwe si alaga wọọdu oun, Agulu ward 2 nijọba ibilẹ Anaocha lati fi too leti pe oun kii ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP mọ bẹrẹ lati ogunjọ oṣu karun un ọdun 2022

Ati pe oun ti jawọ ninu idije fun ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu naa.