BBC Ekiti 2022Debate: Mà á ṣe ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láti mójútó ètò aàbò dáadáa

Nigba ti oun naa n sọrọ, Oluwole Oluyede lati ẹgbẹ oṣelu ADC, ni oun ni imọ ati akinkanju lati tun ipinlẹ Ekiti ṣe gẹgẹ bi onimọ nípa eto ìlera.
Oluyede ni ti ẹka ìlera, òwò ṣe koko, ijọba oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn aladani lati tun eto ìlera ipinlẹ Ekiti ṣe.
Lori eto ààbò, o ni ti iṣẹ ba wa fun ọdọ, ko ni si ojukokoro lati jalè. "Má a tun da fijilante silẹ, ominira yoo wa fun àwọn ìjọba ìbílẹ̀, lati le gbọ bukaata àwọn fijilante.""Má a ṣe idasilẹ ọlọ́pàá ipinlẹ, state police, ati lilo imọ ẹ̀rọ fun gbogbo awọn elero ààbò."
Bẹ́ẹ̀ naa lo ni pe fun awọn akanda ẹ̀dá, ijọba oun yoo ṣe gbogbo nnkan to ba tọ si wọn, oun yoo da wọn ni oko-owo nipa owo yíya ti ko gunpa, isẹ ijọba yoo si tun wa fun wọn.
- Gómìnà Anambra, Àjọ CAN, Àjọ Arewa bu ẹnu àtẹ́ lu obìnrin àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣekúpa
- Àwọn agbébọn jí fadá ìjọ Kátólíkì méjì gbé ní Katsina
- Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí tí ọ̀pọ̀ ní pé Falana àtàwọn àgbẹjọ́rò tó kù gbìyànjú ṣùgbọ́n ìgbẹ́jọ́ ṣì ń tẹ̀síwájú lónìí
- Òtítọ́ ni pé a mùlẹ̀ láti má sọ fún ẹnì kankan- Magdalene Chiefuna, òṣìṣẹ́ Hilton Hotel jẹ́wọ́ nílé ẹjọ́
- Ọmọ ọdún 19 tí wọ́n sọ sí ẹ̀wọ̀n nitorí ọ̀kadà tó sọnù ti kú
- Gbajúmọ̀ Olórin Banky W ti rí tíkẹ̀ẹ̀tì ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbà láti díje dupò aṣòfin

Bakan naa ni Erelu Kemi Elebute-Halle ti ẹgbẹ oṣelu ADP ni igbesẹ mẹta ni awọn yoo gunle lati le jẹ ki ijọba awaarawa fẹsẹ rinlẹ fun awọn ara ilu.
Elebute-Halle ni gbogbo awọn to ti ṣe ijọba sẹ́yìn ni ko ṣe dáadáa, ati pe asiko ti to ki wọn fun obinrin laye ni oun ṣe fẹ́ ẹ gba akoso ijọba ipinlẹ Ekiti.

"Lori eto aabo, ilana mẹta ni ma a lo fun eto abo.
Ma pese ìṣẹ fun awọn ọdọ lati din ipenija eto aabo ku, ma a ṣe eto itaniji fun araalu, ma a si sisẹ pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ alaabo."
"Mo ti n tọju àwọn akanda ẹda saaju ki n to gbegba ibo. Ma á ni ìdá to ni itumọ fun ìgbàni sisẹ fun àwọn akanda ẹ̀dá."

Ninu ọrọ tirẹ, Segun oni lati ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP ni awọn nnkan ti oun ti ṣe tẹlẹri nigba ti oun ṣe ijọba yoo tẹsiwaju nipa ẹkọ ati eto ilera.
Kí n tó parí ọdún mẹ́rin, Google ati Microsoft yóò dé sí ìpínlẹ̀ Ekiti
Oni ni oun ko le sọ wi pe oun ko ṣe daadaa nigba ti oun ṣe ijọba, ṣugbọn awọn le ṣe ju bẹẹ lọ. Paapaa julọ ni ẹka eto ilera.
Àṣírí bí Dubai ṣe di olókìkí wà lọ́wọ́ mi, mó ṣetán láti lòó ní ìpínlẹ̀ Ekiti - Debọ Ranti Ajayi
Olùdíje sípò gómìnà labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Youth Progressives Party, YPP Debo Ranti Ajayi ni aṣiri bi Dubia ṣe di olokiki wa lọwọ oun, ti ipinlẹ Ekiti yoo si dabi ilu Dubai laaarin ọdun mẹrin.

Debo Ajayi ni ki oun to pari ọdun mẹrin, Google ati Microsoft yoo de si ipinlẹ Ekiti ti ipinlẹ Ekiti yoo si di atunbi.
Ajayi ni wahala ti o wa ni Ekiti bayii ni aisi owo ati pe bi ẹnikan ba sọ pe oun yoo tun ilu ṣe nipasẹ owo ti o n wa lati Abuja nikan, irọ lo pa.
"Emi nikan ni mo le san owo awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti."

Ni ti oludije lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Bisi Kọlawọle eto igbanisiṣẹ, ọgbin, ilera, itesiwaju awọn obinrin, ati eto ọrọ aje ni awọn nnkan gboogi ti ijọba oun yoo gunle.
Kolawole ni lori eto aabo oun yoo ri daju pe awọn fijilante ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbofinro lati dẹkun iṣoro eto aabo.
"A ti ṣee ri, a o tun ṣee si i ti a ba wọle."
Ẹ̀yin tí ẹ ti tukọ̀ Ekiti tẹ́lẹ̀ kò ṣe dáadáa rárá, ẹ fún Obìnrin láàyè láti wa to Ekiti
Ìpàdé ìta gbángba BBC Yorùbá tí gbérasọ l'EkitiGbogbo eto lo ti to bayii fún ìpàdé ìpàdé ita gbangba fun awọn oldije sipo gomina ipinlẹ EkitOnirUuru awọn araalu lo ti wa ni ikalẹ láti fun oju lounjẹ eto ipade ita gbangba naa, ati lati dá sí eto ọhun.

Bẹẹ naa ni awọn oludije sipo gomina ti yoo kopa ninu ipade ita gbangba naa ti dé sí gbangan ìpàdé.
Lara àwọn oludije to ti wa ni ikalẹ ni Debo Ranti Ajayi, to n dije du ipo ninu ẹgbẹ oṣelu YPP, oludije ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Bisi Kolawole ati Oluwole Oluyede, to n dije ninu ẹgbẹ oṣelu ADC, bẹẹ náà ni Segun
Oni, to n dije du ipo ninu ẹgbẹ oṣelu SDP náà ti wa ni ikalẹ.

Ohun gbogbo ti ṣetan ni ilu Ado Ekiti ni owuro yi
Òní lònìí ń jẹ́, BBC Yorùbá ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ Ipàdé Itagbangba ní Ekiti pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gómìnà
BBC Yoruba ṣeto yii ki gbogbo oludibo ni ipinlẹ Ekiti lè ni oore ọfẹ lati beere gbogbo ohun to n jẹ wọn lọkan lọwọ awọn oludije sipo gomina ti ẹ sọ pe ẹ fẹ ri.Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'BBC Yoruba Ekiti Governorship Debate' tí yóò wáyé lọ̀sẹ̀ yìí

Awọn ti a ti pe wa si gbagede niwọnyii:
Awọn oludije ti yoo kopa ni:
Segun Oni - SDP
Kemi Elebute-Halle - ADP
Oluwole Oluyede - ADC
- Ta ni Anamekwe Nwabuoku tí ìjọba yàn láti delé sí ipò olùṣirò owó àgbà ní Nàìjíríà (AGF)?
- Òtítọ́ ni pé a mùlẹ̀ láti má sọ fún ẹnì kankan- Magdalene Chiefuna, òṣìṣẹ́ Hilton Hotel jẹ́wọ́ nílé ẹjọ́
- ASUP ṣetán láti fi kún ìyanṣẹ́lódì - Ezeibe
- Seyi Makinde ni PDP gbade fún láti díje dupò gómìnà Oyo lẹ́ẹ̀kán síi nínú ìdìbò abẹnu yìí
- Ọmọdé 19 ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìṣekúpani ní iléẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́rẹ̀ Texas
- Inú ọ̀sẹ̀ yìí ló yẹ kí ìyàwó mi bímọ kí wọ́n tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò Jubril- ọkọ aláboyún Anambra
- Ṣé lóòtọ́ ni Ààrẹ Buhari ti gbaṣẹ́ lọ́wọ́ gómìnà Báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà, Godwin Emefiele?
- Gómìnà Anambra, Àjọ CAN, Àjọ Arewa bu ẹnu àtẹ́ lu obìnrin àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣekúpa
Debo Ranti - YPP
Biodun Oyebanji - APC
Bisi Kolawole - PDP
Awọn nkan wo ni yoo ṣẹlẹ nibi itakurọsọ Ekiti?
Nibi ipade naa, ni oriṣiriṣi ẹgbẹ laarin ilu, bi ẹgbẹ oṣiṣẹ, awọn ọlọja, ati awọn ẹgbẹ miran to ni nkan ṣe pẹlu eto ijọba awaarawa, yoo ti kopa, lati beere ibeere lori ipinnu ati eto ti oludije kọọkan ni fun ipinlẹ Ekiti.
Bakan naa ni awọn oludije naa yoo lo anfaani rẹ̀ lati sọ awọn nkan ti wọn yoo ṣe yatọ si ti ijọba to n bẹ lori aleefa.
Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe gbogbo araalu ni yoo le wọle si gbọngan itakurọsọ naa.
Amọ ẹ le wo o lori ẹrọ ayelujara Facebook wa, BBC News Yoruba, tabi ki ẹ darapọ mọ awọn ileeṣẹ redio ati tẹlifisan to jẹ alajọṣiṣẹpọ wa, nipinlẹ Ekiti.















