APC Presidential Primaries: Ìdí tí INEC fi gbà kí APC sún ìdìbò abẹ́lé síwájú rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC ti kede idi ti awọn fi gba ẹgbẹ oṣelu APC laaye lati sun idibo abẹle wọn siwaju.
Eyi ko ṣẹyin bi INEC ̣ṣe kọko fi Ojo Keta, Oṣu Kẹfa lede gẹgẹ bi gbedeke fun awọn ẹgbẹ oṣelu lati ṣe idibo abẹle wọn.
Amọ INEC fi ọsẹ kan kun fun awọn ẹgbẹ oṣelu yii lati fi pari idibo abẹle wọn.
Eleyii mu ki ẹgbẹ oṣelu APC to yẹ ki wọn ṣe idibo abẹle fun oludije sipo aarẹ ni ọjọ kọkandinlọgbọn ati Ọgbọnjọ oṣu yii sun si iwaju.
- Àwọn wo ní olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó ń gbèrò láti rọ́pò Ààrẹ Buhari
- Ṣé ní ìgbà ẹlẹ́ẹ̀kẹfà yìí ni ọwọ́ Atiku Abubakar yóò tẹ èku idà ààrẹ Nàìjíríà?
- Wo bí Atiku Abubakar ṣe la Wike mọ́lẹ̀ tí Saraki náà sáré lọ kìí kú oríire
- Èrò àwọn ọmọ Naijiria ṣọ̀tọ̀tọ̀ lórí àwọn tó pin gàrí, ṣúgà àti mílíkì níbi ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ
Idi ti a fi sun gbedeke eto idibo abẹle siwaju re e
Kọmisọnna Ajọ INEC ni Naijria, Festus Okoye ni awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ipade pẹlu awọn adari awọn ẹgbẹ oṣelu lorisirisi.
Alaga Ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu lo dari ipade naa.
Lasiko ipade naa awọn ẹgbẹ oṣelu labẹ asia inter-party advisory council (IPAC) bẹbẹ lọwọ INEC lati sun idibo gbogboogbo ọdun 2023 siwaju.
Amọ lẹyin ipade naa ni INEC ni awọn ko ni sun idibo gbogboogbo siwaju, amọ awọn yoo sun ọjọ siwaju fun awọn ẹgbẹ oṣelu lati ṣe idibo abẹle wọn.
Ọjọ Kejidinlọgbọn, Oṣu Karun un ni ẹgbẹ oṣelu APC kede peawọn ti sun idibo abẹle lati yan ẹni ti yoo dije dupo aarẹ labẹ ẹgbẹ wọn siwaju.












