Party Foods: Èrò àwọn ọmọ Naijiria ṣọ̀tọ̀tọ̀ lórí àwọn tó pin gàrí, ṣúgà àti mílíkì níbi ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Lara awọn ounjẹ ti wọn maa n pin, paapaa nilẹ Yoruba lasiko awọn ayẹyẹ bii ọjọ ibi, iṣile, isọmọlorukọ atawọn ariya mii ni; irẹsi, iyan ati ọbe ẹfọ, amala ati gbẹgiri, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Amọ kayeefi lo jẹ niluu Eko nigba ti idile kan pin gari, miliki ati ṣuga nibi inawo ti wọn ṣe.
Ninu fidio kan lori ikanni Instablog Naija loju opo Instagram ni awọn kan ti n pin gari, ṣuga ati miliki fun awọn eeyan to wa ba wọn ṣe ayẹyẹ.
- Àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga gbogbonìṣe Poly ní Nàìjíríà , ASUP bẹ́rẹ́ ìyanṣẹ́lódì, wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀
- Genevieve Nnaji fi fídíò sí Instagram, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ìròyìn sọ pé ó ní àrùn ọpọlọ
- Buhari pàṣẹ fún àwọn mínísítà tó bá fẹ́ dupò òṣèlú láti kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀ ní kíá
- Ṣé lóòtọ́ ní Makinde gbà tíkẹ̀ẹ̀tì Sẹ́nétọ̀ lọ́wọ́ Kola Balogun fún Joseph Tegbe?
- Johnson Sulemann sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀sùn tí Stephanie Otobo fi kàn án
- Buhari kò ní fi oṣù mẹ́fà kún ìjọba rẹ̀ bí àwọn kan ṣe ń bèrè - Ìjọba àpapọ̀̀̀
- Wo àwọn tó ra fọ́ọ̀mù ipò Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC
- Ṣé lóòtọ́ ni Jonathan ti gbẹ̀yìn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC? Nkan tí PDP àti APC sọ rèé
- Wo ìdí tí Ilé aṣòfin àpàpọ̀ Nàìjíríà ṣe yí òfin ìdìbò padà fún ààrẹ, gómìnà, àwọn aṣòfin àtàwọn míràn
Bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ agbegbe ti ayẹyẹ naa ti waye, a gbọ pe ilu Eko ni.
Bẹẹ si ni a gbọ pe ayẹyẹ isọmọlorukọ ni wọn n ṣe lọjọ naa pẹlu.
Iha wo ni awọn eeyan kọ si igbesẹ yii?
Ọpọ awọn to ri fidio naa lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede nipa rẹ.
Pupọ ninu awọn to n sọrọ nipa fidio ọhun lo n sọ pe igbese awọn to n ṣe ayẹyẹ naa ko buru.
Lara awọn to sọrọ ni Ayo Olorun Tomiwa to sọ loju opo Instagram pe "Awọn lo n ṣe ayẹyẹ, ohun to ba wu wọn ni wọn si le pin nibi ayẹyẹ naa, ki ẹni ti ko ba tẹ lọrun gba iule rẹ lọ."
Ẹlomiran to da si ọrọ naa ni "Wọn gbiyanju gidi, nitori ko rọrun lati ri gari ati miliki gan laye ode oni."
Bẹẹ lawọn mii ẹwẹ n sọ pe, bisikiti ati ẹlẹrindodo san j ugari ati ṣuga toun ti miliki lọ nibi isọmọlorukọ.

















