Oriyomi Hamzat: Olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ rédíò Agidigbo, Oriyomi Hamzat ti gba ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, other
Oriyomi Hamzat: Ó tọ́pẹ́! Oriyomi Hamzat ti gba ìtúsílẹ̀.
Gbajugbaja akọroyin to tun jẹ oludasilẹ ileeṣẹ redio Agidigbo FM, Oriyomi Hamzat ti gba itusilẹ.
Hamzat ni wọn fi panpẹ ọba mu ti wọn si gbe lọ si ilu Abuja, ni wọn ti tusilẹ bayii.
Kaakiri Naijiria ni iroyin gbode kan pe ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni Naijiria fi iwe pe Hamzat, ti wọn si fi panpẹ ọba mu lai sọ ẹṣẹ rẹ fun ẹnikẹni.
- Ìwé orúkọ àwọn olùdíje tó bórí ìbó abẹ́nú gómìnà ní APC
- Mọ̀ síi nípa àwọn tó máa díje dupò gómìnà lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ PDP lẹ́yìn tí wọ́n ti yegé nínú ìdìbò abẹ́lé
- Ohun ìbànújẹ́ ló ṣẹlẹ̀ ní Anambra, ẹ dákún mi ò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni fi oró ya oró lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà- Buhari
- Ìkò Ipolongo tí APC yàn sá̀ájú ìdìbò sípò gómínà ní Ekiti rè é…
- Mà á dá fijilanté sílẹ̀, òmìnira á wà fún ìjọba ìbílẹ̀ láti ná owó wọn- Oluwole Oluyede
- Ó ṣe! ọkọ olùkọ́ tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn tó wáyé nílé ẹ̀kọ́ Texas dágbére fáyé
- Ọlọ́pàá fipá mú mi láti buwọ́lu 'Statement'ti mí ò kọ̀ fúnra mi nípa ikú -Adeniyi
Amọ ninu fidio ti Hamzat fun ara rẹ gbe jade lo ti sọ wi pe nitori iroyin iku akẹkọọ fasiti OAU ti wọn pa ni Ile Ife, ti oun ko si jawọ ninu iroyin naa lo fa a ti wọn fi n wa ẹmi oun.
O fikun pe oun ko ni jawo ninu iroyin otitọ ati ododo ninu iṣẹ ti oun yan laayo.
Amọ ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ni idi ti wọn fi fi panpẹ ọba mu wọn ni nitori pe wọn fi ẹsun idukoko lori ayelujara kan ọkunrin naa, eleyii to si jasi ẹsẹ si ofin.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ iroyin Agidigbo 88.7fm fi lede ni wọn ti dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọmọ Naijirira fun aduroti wọn.
Bakan naa ni wọn ni ọga awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an ti ko si dunkoko mọ ẹnikẹni, eleyii to tako ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ.

Oríṣun àwòrán, @Agidigbo
Wọn fikun un pe awọn agbẹjọrọ Maye ti Ife, Ramon Adedoyin ti wọn fi ẹsun ipaniyan Adegoke kan lo wa ni idi iṣẹlẹ naa.
Wọn ni igbesẹ ti ijọba gbe naa ni lati dunkoko mọ Hamzat nitori oun ko iroyin lati pe fun idajọ otitọ ati ododo lori ipaniyan akẹkọọ fasiti OAU, Timothy Adegoke.
- Olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ rédíò Agidigbo, Oriyomi Hamzat ti gba ìtúsílẹ̀
- Ẹgbẹ́ òṣèlú APC Oyo sún ètò ìdìbò abẹ́nú sí òní, ìdí rèé
- Ohun ìbànújẹ́ ló ṣẹlẹ̀ ní Anambra, ẹ dákún mi ò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni fi oró ya oró lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà- Buhari
- Ọlọ́pàá fipá mú mi láti buwọ́lu 'Statement'ti mí ò kọ̀ fúnra mi nípa ikú -Adeniyi
- Ìwé orúkọ àwọn olùdíje tó bórí ìbó abẹ́nú gómìnà ní APC
- Ó ṣe! ọkọ olùkọ́ tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn tó wáyé nílé ẹ̀kọ́ Texas dágbére fáyé
- Mà á dá fijilanté sílẹ̀, òmìnira á wà fún ìjọba ìbílẹ̀ láti ná owó wọn- Oluwole Oluyede
Ẹ̀sùn títàpá sófin tó tako ìwà kòtọ́ lórí ayélujára 'Cybercrime' la fi gbé Oriyomi Hamzat - Ọlọ́pàá
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní sùn títàpá sófin tó tako ìwà kòtọ́ lórí ayélujára 'Cybercrime' la fi gbé Oriyomi Hamzat, àwọn sì gbàyọ̀ǹda níléẹjọ́
Ileeṣẹ iroyin Agidigbo ni ifipanpẹ mu ni naa niise pẹlu Maye ti Ife, Ramon Adedoyin lori ẹsun ipaniyan Timothy Adegoke
Ileeṣẹ ọlọpaa ti sọrọ lori bi wọn ṣe mu gbajumọ agbohusafẹfẹ kan nilu Ibadan, Oriyọmi Hamzat lọjọbọ.
Oriyọmi ti kọkọ sọ ninu fidio kan to fi ṣọwọ si BBC News Yoruba pe nitori awiiyannu oun lori wiwa idajọ ododo fun oku Timothy Adegoke, akẹkọọ fasiti OAU kan to ku sileetura Hilton Hotel to jẹ ti Oloye Rahaman Adedoyin nile Ifẹ.
Amọṣa ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe otitọ to jina sootọ pata leyi ati pe titapa si ofin iwa kotọ lori ayelujara, Cybercrime Act 2015 ni wọn fi gbe.
- Mà á dá fijilanté sílẹ̀, òmìnira á wà fún ìjọba ìbílẹ̀ láti ná owó wọn- Oluwole Oluyede
- Àwa mẹ́ta la gbé òkú Timothy Adegoke lọ sí Ede road- Ẹlẹ́rìí Oyetunde Kazeem
- Ọmọ ọdún 19 tí wọ́n sọ sí ẹ̀wọ̀n nitorí ọ̀kadà tó sọnù ti kú
- Ìjọba kéde òfin kónílé-ó-gbélé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án ní ìpínlẹ̀ Anambra
- Gbajúmọ̀ Olórin Banky W ti rí tíkẹ̀ẹ̀tì ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gbà láti díje dupò aṣòfin
- Ohun ìbànújẹ́ ló ṣẹlẹ̀ ní Anambra, ẹ dákún mi ò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni fi oró ya oró lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà- Buhari
- Wo ojú àwọn tó fẹ́ díje dupò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Oyo lónìí
Alukoro ileeṣẹ ọ̀lọ̀paa Naijiria, Ọmọọba Olumuyiwa Adejọbi ṣalaye fun BBC News Yoruba pe lootọ ni wọn mu Oriyọmu Hamzat nitori awọn eeyan kan fi sun pe awọn ohun to n ṣe lori ayelujara tako ofin to gbogun ti iwa kotọ lori ayelujara, iyẹn Cybercrime Act.
O ni fun ọpọlọpọ igba lawọn ọ̀lọpaa si ti kọwe pe Oriyọmi Hamzat lori afẹfẹ ṣugbọn to kọ lati farahan lọdọ awọn ọlọpaa.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
O ni igba to kọ lati farahan lawọn ọlọpaa fi lọgba iwe igbayọnda lati mu u ni ile ẹjọ ti wọn si lọ mu u lọjọbọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria tun ṣalaye siwaju ninu atẹjade kan to fi sita lori iṣẹlẹ naa lọsan Ọjọbọ pe ẹsun idunmọ̀hurumọni lori ayelujara ni wọn fi kan an ni pato; awọn si n ṣewadii lori ẹsun naa lati mọ igbesẹ to kan ti awọn yoo gbe lori rẹ.
Oriyomi Hamzat wọ gbaga ọlọ́pàá 'nítorí ọ̀rọ̀ Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura Rahman Adedoyin'
Oriyomi Hamzat, ìlúmọ̀ọ́ká agbóhùnsáfẹ́fẹ́ wọ gbaga ọlọ́pàá nítorí ọ̀rọ̀ Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura Rahman Adedoyin
Gbajumọ agbohunsafẹfẹ kan nilu Ibadan, Oriyọmi Hamzat ti wa lakata awọn ọlọpaa bayii.
Irọyin to tẹ ileeṣẹ BBC lọwọ fidi rẹ mulẹ pe owurọ Ọjọbọ ni awọn agbofinro wa gbe e ti wọn si taare rẹ si olu ileeṣẹ ọlọpaa nilu Abuja.
Ninu fidio to kan to tẹ BBC lọwọ, ilumọọka agbohunsafẹfẹ naa to tun jẹ oludasilẹ ileeṣẹ redio aladani kan nilu Ibadan ṣalaye pe awọn ọlọpaa ẹka ọtẹlẹmuyẹ SIIB lo wa gbe oun ti wọn si taare oun si ọwọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ FIIB nilu Abuja.
Ninu fidio naa, Oriyọmi Hamzat ni ilu Abuja loun wa ni ọfiisi awọn ọlọpaa naa ati pe ki araalu lee mọ pe ara oun da pe nigba ti oun de ileeṣẹ ọ̀lọpaa ni oun ṣe ṣe fidio naa ai baa mọ bi ọrọ ba ba ibomiran yọ loun fi ṣe fidio naa.
O ṣalaye siwaju sii pe awọn agbofinro naa jẹ ko di mimọ pe agboye ilu Ile Ifẹ to n jẹjọ lori iku akẹkọọ fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke,
Iyẹn Oloye Rahaman Adedoyin lo kọwe si awọn agbofinro nipa gbọnmọgbọnmọ oun lori wiwa idajọ ododo fun Timothy Adegoke to doloogbe ati awọn mọlẹbi rẹ.

Oríṣun àwòrán, Agidigbo fm
Ile ẹjọ Giga ipinlẹ Ọṣun nilu Osogbo n gbọ ẹjọ lori iku Timothy Adegoke lẹyin ti awọn agbofinro gbe Oloye Rahaman Adedoyin atawọn oṣiṣẹ ile itura rẹ, Hilton Hotel nilu ile ifẹ lọ sile ẹjọ.
Lori ẹsun pe ki wọn wa wi tẹnuwọn lori ohun to ṣokunfa iku akẹkọọ naa.
Nigba ti BBC kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede Naijiria lati beere bi ọrọ naa ṣe jẹ pẹlu awọn ọlọpaa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Ọmọọba Olumuyiwa Adejọbi ṣalaye pe oun yoo bere lori rẹ lati jabọ fun wa lori bo ṣe n lọ.



















