Texas School Shooting: Ọkọ olùkọ́ tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn tó wáyé nílé ẹ̀kọ́ Texas dágbére fáyé lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí ìyàwó rẹ̀ kú

IRMA ÀTI JOE GARCIA

Ọkọ ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ méjì tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn tó wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Uvalde, Texas ti dágbére fáyé lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí ìyàwó rẹ̀ kú.

Gẹ́gẹ́ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ṣe sọ, ìpòruru ọ̀kan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ikú ìyàwó rẹ̀ ló ṣekúpa á.

Joe Garcia ní ọkọ Irma Garcia tí agbébọn tó yìbọn pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kàndínlógún àti olùkọ́ méjì ní Robb Elementary School ní ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Karùn-ún, ọdún 2022 rán lọ sọ́run àrèmabọ̀.

Ọdún mẹ́rìnlélógún ní àwọn tọkọtaya náà fi gbé papọ̀ tí wọ́n sì bí ọmọ mẹ́rin.

Ọkùnrin méjì àti obìnrin méjì tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìlá sí ọdún mẹ́tàlélógún ni àwọn tọkọtaya náà fi sáyé lọ.

Ní orí ẹ̀rọ ayélujára, Twitter ni John Martinez, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí Garcia ní ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún àwọn wí pé àwọn tún pàdánù Joe sọ́wọ́ ikú nítorí ọgbẹ́ ọkàn tí ikú ìyàwó rẹ̀ dá si lára.

Àkọlé fídíò, Oromidayo Daniel: Mo tú gbogbo ilé Dayo bóya á máa rí ǹkan tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n...

Wọ́n ṣe ìkówójọ fún Garcia

Ní ìgà tí yóò fi di alẹ́ ọjọ́bọ̀, owò tí àwọn ènìyàn ti dá fún ẹbí Garcia ti le ní mílíọ̀nù kan lé ọwọ mẹ́fà dọ́là, èyí tó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye lé sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá dọ́là tí wọ́n gbèrò láti dá fún-un.

Debra Austin tó jẹ́ ọ̀kan lára ẹbí Garcia ló bẹ̀rẹ̀ ìkówójọ́ náà.

Austin ni òun ní ìgbàgbọ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ ikú Irma bá Joe lójijì, òhun ló sì fa ikú rẹ̀.

"Ọdún mẹ́rìnlélógún ni Irma Garcia fi ṣe olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Robb Elementary School tó sì fẹ́ràn àwọn ọmọdé púpọ̀."

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Austin ní akitiyan Garcia láti dá ààbò bo àwọn ọmọ tó wà ní yàrá ikẹ́kọ̀ọ́ nítorí ó ràgà bò wọ́n títí ẹ̀mí fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀ ni.

Garcia àti olùkọ́ kejì tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ, Eva Mireles ti jọ ṣiṣẹ́ papọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ n;i ilé ẹ̀kọ́ fún ọdún márùn-ún kí wọ́n tó papòdà.

Àkọlé fídíò, Ayodeji Rotinwa ni ìròyìnn òfegè gbé àwòrán rẹ̀ síta pè dókítà tó ń pa àwọn Hausa mùsùlùmí