Osinachi Death: Èsùn onígun 23 ni ìjóba fi kan oko Osinachi

Oríṣun àwòrán, Others
Osinachi olorin ẹmi naa to jẹ ẹni ọdun mejilelogoji lo ku lẹyin ọjọ diẹ ni ileewosan kan ni ilu Abuja.
Minisita fun eto idajọ ni Naijiria ati Olotu eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami ti gbe ọkọ olorin ẹmi Osinachi to papoda, Peter Nwachukwu lọ si ileẹjọ giga ni ilu Abuja.
Ẹsun onigun mẹtalelogun ti wọn fi kan Peter nipe oun lo ṣokunfa iku iyawo rẹ Osinachi lẹyin ọpọlọpọ lilu bi bara.
Ọjọ Kẹjọ, Oṣu Kẹrin ni Osinachi ku ni ileewosan kan ti wọn ko darukọ rẹ.
- Mọ̀ síi nípa àwọn tó máa díje dupò gómìnà lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ PDP lẹ́yìn tí wọ́n ti yegé nínú ìdìbò abẹ́lé
- Ìkò Ipolongo tí APC yàn sá̀ájú ìdìbò sípò gómínà ní Ekiti rè é…
- Mà á dá fijilanté sílẹ̀, òmìnira á wà fún ìjọba ìbílẹ̀ láti ná owó wọn- Oluwole Oluyede
- Ó ṣe! ọkọ olùkọ́ tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn tó wáyé nílé ẹ̀kọ́ Texas dágbére fáyé
- Ọlọ́pàá fipá mú mi láti buwọ́lu 'Statement'ti mí ò kọ̀ fúnra mi nípa ikú -Adeniyi
- Ohun ìbànújẹ́ ló ṣẹlẹ̀ ní Anambra, ẹ dákún mi ò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni fi oró ya oró lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà- Buhari
- Olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ rédíò Agidigbo, Oriyomi Hamzat ti gba ìtúsílẹ̀
Adari ẹka ileeṣẹ to n risi iwa ipa ni ileeṣẹ ijọba to n risi eto idajọ, Abilekọ Yewande Gbola Awopetun lo pe ipẹjọ naa pẹlu akọle CR/199/2022.
Nwachukwu ni wọn pe lẹjọ ni abẹ ofin section 104 ati 379 ti iwe ofin Administration of Criminal Justice Act, 2015 pẹlu ẹsun ipaniyan eleyii to tako iwe ofin Naijiria, to si le ri iku he to ba jẹbi ẹsun naa.
Osinachi olorin ẹmi naa to jẹ ẹni ọdun mejilelogoji lo ku lẹyin ọjọ diẹ ni ileewosan kan ni ilu Abuja.
Lẹyin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa fi panpẹ mu ọkọ naa lẹyin ti awọn akẹgbẹ Osinachi pariwo sita pe ọkọ rẹ ma n naa ni gbogbo igba ni.
Ẹsun naa ka pe ''Peter Nwachukwu to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ni Ọjọ Kẹjọ, Oṣu Kẹrin,ọdun 2022 lọwọ ninu iku iyawo rẹ, Osinachi fun ọpọlọpọ igba to ti na obinrin naa pẹlu imọlara pe iku ni yoo jasi fun obinrin naa.
Bakan naa ni wọn fẹsun kan an pe o tii jade kuro ninu ọkọ rẹ lori ere to si subu lulẹ.
Ijọba ni eleyii fa ipaya to tako ofin Naijiria to tako iwa ipa si ẹnikẹni.















