Delegates in Nigeria: Ǹkan tí àwon omo Naijiria ń so nípa ''delegates'' tó ń dìbò fún egbé òsèlú ní yìí...

Oríṣun àwòrán, Others
Ǹkan tí àwon omo Naijiria ń so nípa ''delegates'' tó ń dìbò fún egbé òsèlú ní yìí...
Lati ibẹrẹ ọsẹ yii ni awọn eniyan ti n sọrọ nipa awọn aṣoju ''delegates'' yii ati idi ti awọn ẹgbẹ oṣelu yii ṣe n fun wọn ni agbara lati dibo ṣoju awọn eniyan.
Lati ibẹrẹ ọsẹ yii ni awọn eniyan ti n sọrọ nipa awọn aṣoju ''delegates'' yii ati idi ti awọn ẹgbẹ oṣelu yii ṣe n fun wọn ni agbara lati dibo ṣoju awọn eniyan.
Awọn aṣoju wọn yii ni wọn n gba owo lọwọ awọn oludije, ti wọn si n dije fun awọn oloṣelu ti wọn ba fẹ.
Saaju idibo apapọ ti ọdun 2023, awọn aṣoju wọn yii ni apo wọn ti ku nitori awọn eniyan bẹrẹ si ni mọ wọn paapaa lori ẹrọ ayelujara.
- Sanwo Olu, Dapo Abiodun àti Abdulrazaq jáwé olúborí láti tẹ̀síwájú díje dupò lábẹ́ àsìá APC
- Àwọn olùfẹ́hónúhàn dáná sun ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́ta àti mọ́ṣáláṣí mẹ́rin, ẹ̀mí ogún èèyàn sọnù
- Iléẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ lórí ikú Timothy Adegoke síwájú, Wo ohun tó fàá....
- Ìjoba ti fi èsùn ìpànìyàn kan oko Osinachi, Peter Nwachukwu
- Olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ rédíò Agidigbo, Oriyomi Hamzat ti gba ìtúsílẹ̀
- Ẹgbẹ́ òṣèlú APC Oyo sún ètò ìdìbò abẹ́nú sí òní, ìdí rèé
- Ohun ìbànújẹ́ ló ṣẹlẹ̀ ní Anambra, ẹ dákún mi ò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni fi oró ya oró lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà- Buhari
- Ọlọ́pàá fipá mú mi láti buwọ́lu 'Statement'ti mí ò kọ̀ fúnra mi nípa ikú Timothy Adegoke-Adeniyi
Kini awọn eniyan n sọ lori ẹrọ ayelujara?
Ọkan lara awọn ọrọ to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara ti awọn eniyan n sọrọ nipa rẹ ni #delegates, paapaa loju opo ikansiraẹni Twitter.
Lara awọn ohun to n kọ awọn eniyan lominu ni bi awọn oludije ṣe n fun awọn aṣoju oludibo yii ni owo ni gbangba.
Ero ọpọ eniyan ni wipe lilo ọna awọn aṣoju yii ko fun awọn eniyan ni anfaani lati dibo yan ẹni ti wọn fẹ ni ijọba tiwantiwa.
Ajafẹtọ obinrin ni Naijiria, Aisha Yesufu ti ni awọn aṣoju yii ko ba dibo yan ẹni ti awọn eniyan fẹ, ki wọn ma dibo fun ẹgbẹ naa ni igba ti akoko idibo gbogboogbo ba de.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bakan naa ni Ajafẹtọ Rinu Oduala ni lilo awọn aṣoju lati dibo yan awọn oludije ni ẹgbẹ oṣelu ko ba ilana oṣelu tiwantiwa lọ.
O ni ohun ti awọn eniyan n tele ni owo ati ọla awọn oludije naa, nitori naa ẹni to ba ni owo ju ni yoo ni ibo to pọju lọ
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Farooq Kperogi to ma n gbohun si afẹfẹ nipa ọrọ Naijiria ni o ṣeni laanu bi awọn ọmọ Naijiria ti wọn pe ni aṣoju oludibo se n ta ibo wọn ni gbangba lai si ibẹru.
Kperogi ni eyi buru jai fun eto oṣelu ni orilẹede Naijiria.
O ni ohun ti yoo ṣẹlẹ ni ọdun 2023 ni ki awọn adari ra ibo lọwọ awọn aṣoju nitori naa eeru ni esi idibo naa yoo jasi ni apapọ.
Bakan naa ni iroyin gbe e pe awọn oludije kan gba owo wọn pada lọwọ awọn oludibo lẹyin ti wọn ko bori ninu idibo abẹle naa.
Amọ sẹnetọ Shehu Sani ni awọn oludibo meji lo dibo fun oun ti oun ko si fun wọn ni nkankan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3