Àwọn olùfẹ́hónúhàn dáná sun ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́ta àti mọ́ṣáláṣí ní Ethiopia

Ethiopia

Oríṣun àwòrán, @peacefmonline

Awọn eeyan kan ti dana sun ọpọ ṣọọṣi ati mọṣalaṣi ni iha ariwa ati gusu Ethiopia.

Wahala naa bẹrẹ lẹyin ti awọn kan ti kọkọ ṣekupa ogun Musulumi, nigba ti ogunlọgọ awọn mii si farapa nibi eto isinku kan niluu Gondar, to wa lagbegbe Amhara.

Agbẹnusọ awọn Musulumi lorilẹ-ede naa sọ fun BBC pe mọṣalaṣi mẹrin ni wọn dana sun.

Bẹẹ naa ni agbẹnusọ fun awọn ọmọlẹyin Kristi ṣalaye fun BBC pe wọn dana sun ṣọọṣi mẹta ni iha gusu orilẹ-ede naa.

Iroyin ni o ṣeeṣe ki iṣẹlẹ naa jẹ ẹsan fun awọn ogun Musulumi ti wọn ti kọkọ pa ṣaaju nibi eto isiniku to waye ni Amhara.

Ijọba orilẹ-ede naa ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọọdunrun ati aadọrin eeyan ti wọn funra si pe wọn lọwọ ninu rogbodiyan ọhun.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

Wọn ni awọn ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iṣẹlẹ naa, nitori naa awọn yoo fi imu ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o n fa wahala lawọn ilu mi danrin.

Ẹwẹ, awọn Musulumi ni olu ilu orilẹ-ede naa, Addis Ababa ti n mura lati korajọ lọna ati fẹhonuhan lori ifẹmiṣofo naa.

Nnkan bii ida mẹrinlogoji ni awọn Musulumi to n gbe ni Ethiopia.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́