APC Primary Election: Aṣojú ‘delegate’ fi ara gba ọta ìbọn ní Ondo

Apoti ibo ti wọn danu

Ọkan lara awọn aṣoju ni ẹgbẹ oṣelu APC ti fi ara gba ọta ibọn lasiko idibo abẹle ni agbegbe Ariwa ati Guusu Akure (North/South) to fi mọ ijọba ibilẹ Idanre/Ifedore.

Iṣẹlẹ naa waye lasiko idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC lati yan ẹni ti yoo di asia ẹgbẹ mu fun ipo aṣojuṣofin ni idibo gbogboogbo to n bọ.

Rogbodiyan naa lo bẹ silẹ ni ilẹ itura Ade Super Hotel ni ilu Akure ni asiko ti awọn janduku ja wọ ibẹ ti wọn si gbe apoti idibo lọ.

Awọn janduku ti wọn ṣe awọn oludibo naa leṣe gbe apoti idibo naa salọ laikọ ibi ara si awọn agbofinro to wa nibẹ.

Àkọlé fídíò, Orúkọ ọmọ ni Yorùbá gbà pé ó máa ń ro ọmọ nílẹ̀ Oodua

Awọn agbọnfinro pẹlu 'armoured tank' naa lọ wa si ibi ti idibo naa ti waye.

Amọ bi awọn janduku naa ṣe n yinbọn lakọlakọ mu ki awọn eniyan sa asala fun ẹmi wọn.

Lẹyin iṣẹlẹ naa, ọkan lara awọn oludije to ba awọn akọroyin sọrọ, Mayọkun Alade ni wọn na aṣoju oun bi bara nibẹ ti wọn si tun yinbọn fun alatilẹyin oun miran ni apa rẹ.

Bakan naa ni ọrọ ri ni agbegbe Igbara Oke ni ijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ nibi ti awọn eniyan ti gbena woju ara wọn lori idibo abẹle naa.

Kaakiri orilẹede Naijiria ni awọn ẹgbẹ oṣelu ti n dibo abẹle lati yan awọn oludije wọn ṣaaju idibo gbogboogbo ti yoo waye ni ọdun to n bọ.