Portable: Mo ti ṣiṣẹ́, ẹ jẹ́ kí n jèrè iṣẹ́ mi pẹ̀lú àmì ẹ̀ye ''Headies Award''

Portable

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gbajugbaja olorin takasufe to ṣẹṣẹ di ilumọọka, Habeeb Okikiola ti inagije rẹ n jẹ Portable ti kọ iwe ẹmabinu ranṣẹ si awọn akẹgbẹ rẹ ati ikọ alakoso ami ẹyẹ '' Headies Award.''

Eyi ko ṣẹyin bi ikọ alami ẹyẹ Headies ṣe bu ẹnu atẹ lu bi Portable ṣe dunkoko mọ awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn fi ''nominate'' rè fun ami ẹyẹ naa ni ẹka olorin tuntun to fakọyọ julọ.

Portable lo n figagbaga pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ fun Ami Ẹyẹ Best Street-Hop Artiste ati ami ẹyẹ Rookie of the Year awards.

Ẹni to ba gba Ami Ẹyẹ mi, n o fi iku pa a - Portable

Loju opo ikansiraẹni Instagram ni Portable ti kọ pe oun ni Ami Ẹyẹ Headies tọ si nitori naa ki ẹnikẹni ma ba oun du.

O ni ẹnikẹni to ba gba Ami ẹyẹ oun, pipa ni oun yoo pa.

''Ami ẹyẹ mi ni o, ẹnikẹni to ba gba a, ma a ni ki wọn pa ẹni naa. Ti awọn alakoso ba fun ẹlomiran ni ami ẹyẹ mi, iku lo ma pa wọn''

Àkọlé fídíò, Zazzu Portable: Èmi ni mo ni Zazzu Zeh, orúkọ mi ló wà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n fẹ́ gbá mi

Portable tun dunkoko, to si tẹnumọ pe ''Ẹ ma fun ẹlomiran ni ami ẹyẹ mi, ẹni ti ẹ ba fun yoo ku ni.''

Amọ awọn eniyan ko fi ara ire gba ọrọ yii ti awọn alakoso ami ẹyẹ naa si kọwe ranṣẹ si pe ko dakẹ ẹnu rẹ abi ki awọn fi ṣinkun ofin mu.

''Portable dakẹ idukoko rẹ abi ki a yọ orukọ rẹ kuro lara awọn alami ẹyẹ Headies''

Amọ ninu esi ti ikọ alakoso ami ẹyẹ naa fun Portable lẹyin idukoko naa ni wọn ti ni ko da ọrọ rẹ pada.

'' Headies bu ẹnu atẹ lu ọrọ kubakugbe ti Portable sọ, eleyii to tako ofin wa.''

Àkọlé fídíò, Orúkọ ọmọ ni Yorùbá gbà pé ó máa ń ro ọmọ nílẹ̀ Oodua

''A ti fi ọrọ naa to ikọ ọlọpaa Naijiria leti nipa ọrọ ti Okikiola sọ si awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn jọ n dije.''

''Bakan naa ni a paṣẹ ni kiakia ki o yọ fidio naa kuro lori ẹrọ ayelujara pẹlu ọrọ ẹmabinu si awọn to sọ ọrọ kugbakugbe si.''

''Ti o ba kọ lati ṣe eyi, a o yọ orukọ rẹ kuro ninu awọn to n dije fun ami ẹyẹ Headies naa.''

Awọn alakoso Headies naa tun parọwa si awọn ara ilu lati jọwọ jawọ ninu pinpin fidio ti Portable ti dunkoko naa.

Ninu esi rẹ, Portable tọrọ aforiji lọwọ awọn akẹgbẹ rẹ amọ to si tẹnumọ pe oun ni ami ẹyẹ naa tọsi nitori oun ṣiṣẹ fun.