PDP Primaries: Gbọ́ nkán tí ẹgbẹ́ PDP sọ nípa ìròyìn tó gbòde pé ìdìbò owó lọ́wọ́ ẹyìn nílẹ̀ ní wọn n ṣé l'Abuja

PDP Abuja

Kò sóhun tó ń jẹ́ pẹ́lú dìbò ko sebẹ̀ láàrín àwọn aṣojú-dìbò wa -PDP

Eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP lati yan oludije fun eto idibo sipo aarẹ orilẹede Naijiria n waye lọwọ ni gbagede isire indoor sports hall papa isire MKO Abiola nilu Abuja.

Awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP to ba BBC sọrọ ni eto gbogbo ti to fun ayeyọri ẹgbẹ naa ati pe ko ni si wahala lẹyin eto naa.

Bakan naa ni wọn tun ṣalaye pe awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa ko mọ si oro owo re e ibo ree ti iroyin rẹ n kaakiri pe o n waye laarin awọn oludije ati aṣoju lawọn ẹgbẹ oselu lọwọ yii.

Okan lara àwọn ọmọ igbimọ majẹkobajẹ ẹgbẹ naa lati ipinlẹ Ọyọ ṣalaye pe ohun to jẹ awọn Oludije ẹgbẹ oṣelu naa ni lati yan oludije ti yoo ṣoju awọn ọmọ Naijiria ti yoo si mu igba pada si rere fun orilẹede Naijira.

Bakan naa ni aarẹ ile aṣofin agba Naijiria nigba kan ri Sẹnetọ David Mark pẹlu fi gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ PDP lọkan balẹ pe didun lọsan yoo so fun wọn ati pe o da oun loju pe ko ni si wahala, ikunsinu tabi edeaiyed kankan lẹyin abajade idibo naa.

PDP Abuja

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Bayelsa, Duoye Diri pẹlu kin ọrọ naa lẹyin ti wọn si ni eto gbogbo ti to bayii ko si si oun to n jẹ ayipada ọjọ eto naa nitori awọn ti ṣetan bayii.