Nse Ikpe-Etim sọ̀rọ̀ lórí ìpènijà rẹ̀ lẹ́yìn tó pàdánù ilé ọmọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, @NSE
Mò ń rí ara mi bíi obìnrin tí kò pé nítorí mi ò lè bí ọmọ láyé - Nse Ikpe-Etim
Nse, to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlaadọta, lo sọ ọrọ naa lasiko to n sọrọ nipa igbeyawo rẹ ninu ifọrọwerọ lori eto kan, #WithChude.
Oṣere naa ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ rẹ, Cliford Sule, to jẹ oniṣowo, ati olukọ agba ni fasiti Midlesex, to wa niluu London lọdun 2013.
- Ohun ìbànújẹ́ ló ṣẹlẹ̀ ní Anambra, ẹ dákún mi ò fẹ́ kẹ́nikẹ́ni fi oró ya oró lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà- Buhari
- Ẹgbẹ́ òṣèlú APC Oyo sún ètò ìdìbò abẹ́nú sí òní, ìdí rèé
- Ìjoba ti fi èsùn ìpànìyàn kan oko Osinachi, Peter Nwachukwu
- Sanwo Olu, Dapo Abiodun àti Abdulrazaq jáwé olúborí láti tẹ̀síwájú díje dupò lábẹ́ àsìá APC
- Iléẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ lórí ikú Timothy Adegoke síwájú, Wo ohun tó fàá....
- Olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ rédíò Agidigbo, Oriyomi Hamzat ti gba ìtúsílẹ̀
- Àwọn olùfẹ́hónúhàn dáná sun ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́ta àti mọ́ṣáláṣí mẹ́rin, ẹ̀mí ogún èèyàn sọnù
- Ìkò Ipolongo tí APC yàn sá̀ájú ìdìbò sípò gómínà ní Ekiti rè é…
Ninu ifọrọwerọ naa, Nse sọ pe oju ko ti oun lẹyin to han gbangba pe oun ko ni le bimọ nile aye, amọ o dabi pe oun ko pe gẹgẹ bi i obinrin.
O ni "Oju ko ti mi, amọ mo ri ara mi bi ẹni ti ko pe ni gbogbo igba ti mo ba ti n ranti."
"Ohun ti mo dupẹ fun ni bi mo ṣe dagba, nitori a ki n so itiju mọ ọrun ni idile wa, niṣe ni a n gbe igbe aye wa bii ẹni to ni ohun gbogbo to n fẹ."
Iha ti ọkọ mi kọ si ipo ti mo wa
Ni ti iha ti ọkọ rẹ kọ si, oṣere naa ni digbi ni ọkọ oun ti o un lẹyin, ko si pada lẹyin oun, oun si dupẹ fun atilẹyin rẹ.
O ni "Ọkọ mi wa lẹyin mi ninu ipo ti mo wa nitori bo ṣe yẹ ko ri naa niyẹn."
Nse sọ pe ohun to n ba oun finra naa lo n ba ọkọ oun finra, idi ree ti atilẹyin rẹ ko ṣe yẹ.
O ṣeeṣe ka gba ọmọ tọ, amọ aja ni a ṣi n tọju lọwọ
Ni ti boya o ṣeeṣe ki tọkọtaya naa gba ọmọ tọ, Nse ni ko si ohun ti ko le ṣẹlẹ.
O ni "O ṣeeṣe ki a gba ọmọ tọ, o si ṣeeṣe ki a ma gba ọmọ tọ, amọ a ko tii le sọ ohun to le ṣẹlẹ ni iha yẹn, lọwọ yii, aja ni a ṣi n tọju lọwọ."
Ọdun 2019 ni Nse kede ni gbangba pe wọn ti yọ ile ọmọ oun lẹyin ti oun ni arun 'adenomyosis.'
















