Kunle Adeyanju ti gun orí àpáta Kilimanjaro rí, ó sì ti gun alùpùpù láti Naijiria lọ sí Ghana

Oríṣun àwòrán, Kunle Adeyanju
Arakunrin ọmọ orileede Naijiria to n gun alaupupu bọ lati London ti balẹ si Naijiria bayii.
Kunle Adeyanju bẹrẹ irinajo yi lati London to si kan si awọn orileede Afrika ko to de ilẹ baba rẹ lọjọ Aiku yi.
Nise lawọn eeyan to ti n fi ọkan ba irinajo rẹ bọ tu yaya jade lati wa pade rẹ
Ni ibode Naijiria pẹlu orileede Benin to wa ni Seme ni awọn ololufẹ rẹ ti wa ki kaabọ.

Oríṣun àwòrán, Adebimpe Olajiga
Ìdí gaan tí mo fi ń gun ọ̀kadà alùpùpù láti London sí Eko rèé
"Kunle Adeyanju ti gun orí àpáta Kilimanjaro rí, ó sì ti gun alùpùpù láti Naijiria lọ sí Ghana".
Ọmọ Naijiria to n wa alupupu lati ilu London nilẹ Gẹẹsi, siluu Eko ni Naijiria, Kunle Adeyanju ti ṣalaye eredi to ṣe gbe igbesẹ naa.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Adeyanju ni ọna ati tan iṣoro awọn eeyan lo mu ki oun gbe igbesẹ naa.
O ni oun tun gbe igbesẹ ọhun nitori oun jẹ ẹnikan to fẹran lati maa rin irinajo to le.
- Wo bí Atiku Abubakar ṣe la Wike mọ́lẹ̀ tí Saraki náà sáré lọ kìí kú oríire
- Èèyàn 31 kú lẹ́yìn tí wọ́n tẹ wọ́n pa níbi tí ilé ìjọsìn ti ń pín oúnjẹ ọ̀fẹ́ ní Port Harcourt
- Ẹ má bínú pé mo dúnkokò mọ́ àwọn akẹgbẹ́ mi , àmọ́ èmi ni ''Headies Award'' tọ́ sí - Portable
- Àwọn jàndùkú oníbọn gbé àpóti ìdìbò abẹ́lé lọ, ‘delegate’ fara gba ọta ìbọn ní Ondo
- Kò sóhun tó ń jẹ́ pẹ́lú dìbò ko sebẹ̀ láàrín àwọn aṣojú-dìbò wa -PDP
- Ìdí mẹ́rin rè é tí dọ́là ẹyọ̀kan ṣe di 600 naira ní Naijiria
Mo ti gun alupupu lati Naijiria lọ si Ghana ri
Kunle Adeyanju sọ fun BBC Yoruba pe kii ṣe igba akọkọ ree ti oun yoo gun alupupu lati orilẹ-ede kan si omiran.
O ni ''Mo fẹran lati maa ṣe awon ohun akinkanju, mo si fẹran irinajo to le.''
''Mo ti gun ori apata Kilimanjaro ri, eyii to jẹ ori apata to ga julọ nilẹ Afrika.''
''Bakan naa ni mo ti wa alupupu lati Naijiria lọ si orilẹ-ede Ghana ri, ti mo tun gun alupupu pada wa si Naijiria.''
''Nigba ti mo pinnu lati rin irinajo yii lati ilu London si Naijiria, mo woye pe bawo ni mo ṣe le ṣe lati fi tu awọn eeyan lọrun ki n si fi ṣe awọn araalu loore.''
O ni yatọ si pe oun fẹran awọn irinajo to le, oun tun gunle irinajo naa lati ṣe ikowojọ fun awọn alaini, ati lati fi gbogun ti aisan to n ba awọn eeyan finra bii polio.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 yii ni Adeyanju gbera kuro niluu London pẹlu alupupu rẹ, ti ireti ṣi wa pe yoo gunlẹ si Naijiria lọjọ Isinmi, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2022.















