Rivers church stampede: Èèyàn 31 kú lẹ́yìn tí wọ́n tẹ wọ́n pa níbi tí ilé ìjọsìn ti ń pín oúnjẹ ọ̀fẹ́ ní Port Harcourt

Rivers church stampede

Oríṣun àwòrán, @instablog9ja

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ti sọ pe eeyan mọkanlelọgbọn lo jade laye lasiko ti wọn tẹ wọ pa lẹyin wọdu-wọdu to waye nibi ti ijọ kan ti n ṣeto ita gbangba niluu Port Harcourt.

Ijọ naa, Kings Assembly, ke si awọn araalu lati yọju sibi eto na, nibi ti wọn yoo ti gba ounjẹ ọfẹ atawọn ẹbun mii.

Agbegbe GRA, ni Port Harcourt ni ile ijọsin naa wa, amọ gbọgan Port Harcourt Polo Club ni eto naa ti waye lati faye gba ọpọ ero ti yoo yọju sibẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Grace Iringe-Koko, sọ pe ṣe ni ṣọọṣi naa n gbiyanju lati bukun awọn alaini lawujọ ki iṣẹlẹ laabi naa to waye.

Iringe-Koko ni ''Eeyan mọkanlelọgbọn lo ba iṣẹlẹ naa lọ nigba ti wọn tẹ ara wọn mọlẹ nibi ti ijọ kan ti n fun awọn araalu ni ounjẹ ọfẹ.''

''Nnkan bii aago mẹsan an aarọ ni wọn fẹ bẹrẹ eto naa amọ awọn eeeyan fi wọdu-wọdu wọ gbọgan ọhun.''

Àkọlé fídíò, Oromidayo Daniel: Mo tú gbogbo ilé Dayo bóya á máa rí ǹkan tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n...

''Eyii lo mu ki ọpọ ero sare wọ ibẹ lọ, ti wọn si tẹ awọn kan pa.''

Alukoro ọlọpaa naa tẹsiwaju pe ''Gẹgẹ bii ohun ti mọ, ṣe ni ijọ naa ṣeto ounjẹ atawọn ẹbun ọfẹ mii fun awọn ti ko rọwọ họri luwujọ.''

O fi kun pe awọn ti bẹrẹ iwadii lati mọ ohun gan pato to fa iṣẹlẹ laabi naa.''

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà