Afolake Abiola: Obìnrin ẹni ọdún 47 tí kò ni ọkọ tàbí ọmọ gbẹ̀mí ara rẹ̀ l'Eko

@NwaAdaIgbo1

Oríṣun àwòrán, @NwaAdaIgbo1

"Obìnrin ẹni ọdún 47 tí kò ni ọkọ tàbí ọmọ gbé oògùn apakòkòrò Sniper mu ni".

Obinrin ẹni ọdun mẹtadinlaadọta yii to gbẹmi ara rẹ niluu Eko ni wọn ni nitori iporuru ọkan lo ṣe pa ara rẹ.

Iroyin ni obinrin ọhun, Afolake Abiola ti n ba iporuru ọkan finra tẹlẹ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ọjọ Ẹti ni oloogbe naa gbe oogun apakokoro Snipper jẹ ninu ile rẹ ti awọn mọlẹbi, ọrẹ ati ileeṣẹ ọlọpaa si ba oku rẹ ninu ile.

Ṣaaju ni awọn iroyin kan ti ọkọ sọ pe oloogbe ọhun pa ara rẹ lẹyin iporuru ọkan to n ba finra nitori ko ni ọkọ tabi ọmọ pẹlu ọjọ ori rẹ.

Awọn mọlẹbi rẹ ko gba ki ọlọpaa ṣe iwadii iku rẹ

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin sọ fun BBC Yoruba pe obinriun naa fi atẹjiṣẹ ṣọwọ si awọn mọlẹbi rẹ ko to gbẹmi ara rẹ.

O ni "Orukọ obinrin naa ni Afolake Abiola, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta si ni pẹlu."

"O ti n ba iporuru ọkan finra tẹlẹ ko to gbe oogun apakokoro Sniper mu."

Àkọlé fídíò, 'Ó ṣì wù mí kí n fi ojú mi ríran padà, owó India ni kò sí! Hip hop yìí nìkan ni mo fi ń gbéra'

"A ba ike oogun naa nilẹ ninu ile rẹ, a si ri Sniper naa ninu ẹnu rẹ amọ awọn mọlẹbi rẹ ko gba ki a ṣe ayẹwo oku rẹ fun iwadii, wọn si fun wa ni iwe aṣẹ lati ile ẹjọ to ṣafihan pe awọn ko fẹ ṣe iwadii kankan."

Hundeyin tẹsiwaju pe "Lootọ ni pe oloogbe naa ko ni ọkọ tabi ọmọ kankan, bẹẹ oun nikan naa lo n da gbe ninu ile oniraya mẹta kan to wa ni Osapa London, lagbegbe Lekki, niluu Eko."

"Ko to gbẹmi ara rẹ, o fi atẹjiṣẹ ṣọwọ si awọn mọlẹbi rẹ to si sọ ninu atẹjisṣẹ naa pe wọn yoo pade lọjọ idajọ."

"Atẹjiṣẹ naa lo mu ki awọn mọlẹbi sare tete lọ sile rẹ, amọ oku rẹ ni wọn ba, ki wọn to ke pe ileeṣẹ ọlọpaa."

Àkọlé fídíò, Ko sọna ni APC ati PDP

Kii ṣe ọrọ ọkọ tabi ololufẹ lo mu ko pa ara rẹ - Ọrẹ oloogbe

Ẹnikan to sun mọ oloogbe naa, amọ ti ko fẹ fi orukọ rẹ lede sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle Punch pe kii ṣe ọrọ ọkọ tabi ololufẹ lo mu ki oloogbe naa pa ara rẹ, amọ o n ba iporuru ọkan finra.

Ẹni naa ni "Ọjọ ti pẹ to ti n ba iporuru ọkan finra amọ iṣẹlẹ naa ko ni nnkan ṣe pẹlu ọrọ ọkọ tabi aini ibalopọ rara."

"Laarin ọdun meje sẹyin mo mọ pe o ti fẹ awọn eeyan kan."

"Oun funra rẹ lo maa n fopin si awọn ibasẹpọ pẹlu awọn ọrẹkunrin rẹ naa nitori iporuru ọkan to n ba finra."

"O maa n sọ pe oun ko fẹ gba ẹlomiran laye ninu aye oun nigba ti oun funra oun gan ko tii mọ ibi ti igbesi aye oun n dorikọ."

Àkọlé fídíò, Oromidayo Daniel: Mo tú gbogbo ilé Dayo bóya á máa rí ǹkan tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ṣùgbọ́n...