Measles: Àwọn ọmọdé mẹ́rìnlá pàdánù ẹ̀mí wọn ní ìpínlẹ̀ Anambra

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọmọdé mẹ́rin ló ti ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn bí ààrùn measles ṣe bẹ́ sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà.
Kọmíṣọ́nà fétò ìlera ìpínlẹ̀ ọ̀hún, Dókítà Afam Obidike tó fìdí ọ̀rọ̀ ọ̀hún múlẹ̀ ní àwọn ọmọdé mẹ́rìnlá lé ní irinwó ló ti lùgbàdì àrùn náà ṣùgbọ́n àwọn mẹ́rìnlá ni àrùn náà ti gba ẹ̀mí lọ́rùn wọn.
Obidike ṣàlàyé pé ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án ní ààrùn náà ti tàn dé báyìí.
- Òní lònìí ń jẹ́, BBC Yorùbá ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ Ipàdé Itagbangba ní Ekiti pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gómìnà
- Ìdí tí mo fi fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ - Peter Obi
- Òtítọ́ ni pé a mùlẹ̀ láti má sọ fún ẹnì kankan- Magdalene Chiefuna, òṣìṣẹ́ Hilton Hotel jẹ́wọ́ nílé ẹjọ́
- Àwọn agbébọn jí fadá ìjọ Kátólíkì méjì gbé ní Katsina
- Gómìnà Anambra, Àjọ CAN, Àjọ Arewa bu ẹnu àtẹ́ lu obìnrin àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣekúpa
- Ṣé lóòtọ́ ni Ààrẹ Buhari ti gbaṣẹ́ lọ́wọ́ gómìnà Báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà, Godwin Emefiele?
- Ọmọdé 19 ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìṣekúpani ní iléẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́rẹ̀ Texas
- Seyi Makinde ni PDP gbade fún láti díje dupò gómìnà Oyo lẹ́ẹ̀kán síi nínú ìdìbò abẹnu yìí
- Inú ọ̀sẹ̀ yìí ló yẹ kí ìyàwó mi bímọ kí wọ́n tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò Jubril- ọkọ aláboyún Anambra
- ASUP ṣetán láti fi kún ìyanṣẹ́lódì - Ezeibe
- MC Oluomo, òpin ti débá gbígba owó orí lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ ní Eko - Iléẹjọ́
- Wọ́n lẹ̀dí àpòpọ̀ mọ́ mi ni mo ṣe fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò abẹ́nú – Dino Melaye
- Lẹ́yìn idojúkọ ASUU, LAUTECH kéde pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọlé wa parí sáà ètò ẹ̀kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ tẹ́lẹ̀
Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà ni: Anambra East, Anambra West, Ayamelum, Ihiala, Idemili North, Nnewi North, Onitsha North, Njikoka, àti Oyi.
Ó ní láti inú oṣù Kẹta ọdún ni àjọ tó ń mójútó àjàkálẹ̀ àrùn ní Nàìjíríà, NCDC ti ta àwọn lólobó lórí àrùn náà ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́sẹ́ẹ̀sàn-án.
Ó fi kun pé èyí ló mú kí àwọn tọ àjọ ètò ìlera àgbáyé, WHO àti ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdé ní àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé UNICEF lọ láti bá àwọn wá wọ̀rọ̀kọ̀ fí ṣàdá lórí àrùn náà.
Obidike sọ síwájú pé àrùn náà ti kọ́kọ́ tàn láti ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án wọ ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlá àmọ́ àtìlẹyìn àjọ WHO ló tètè bá àwọn paná rẹ̀ kú ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án.
"Ó ṣeni láàánú wí pé pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú wa, a pàdánù ọmọ mẹ́rìnlá sọ́wọ́ àrùn yìí."
Bákan náà ló ní àwọn ti fún àwọn ọmọdé tí wọn kò tíì gba abẹ́rẹ́ àjẹsára dèna measles tí ọjọ́ orí wọn kò sì tíì ju ọdún márùn-ún lọ tí iye wọn dín díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ní abẹ́rẹ́ àjẹsára measles.
Ó fi kun pé àwọn ọmọdé tó wà ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́sàn-án yìí ni àwọn tún fún ní abẹ́rẹ́ nítorí àti dènà ìtànkálẹ̀ àrùn náà ju bó ṣe yẹ lọ.
Ó wòye pé Covid-19, àìkọbi ara sí abẹ́rẹ́ àjẹsára àti àìní ìmọ́tótó tó bó ṣe yẹ ló ṣokùnfà bí àrùn náà ṣe bẹ́ sílẹ̀.
Ẹ ó rántí pé ní ọjọ́ kẹrin, oṣù Kẹta ni àjọ NCDC kéde pé àrùn measles ti bẹ́ sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ mẹ́jọ: Jigawa, Anambra, Katsina, Rivers, Enugu, Delta, Osun àti Sokoto.
















