Orúkọ ọmọ ni Yorùbá gbà pé ó máa ń ro ọmọ nílẹ̀ Oodua

Àkọlé fídíò, Orúkọ ọmọ ni Yorùbá gbà pé ó máa ń ro ọmọ nílẹ̀ Oodua

Kí ede ati àṣà Yoruba ma baa parun ni a ṣe da BBC Yoruba silẹ ni Naijiria.

Aina òrósùn ni ọkan ninu awọn orukọ amutórunwa ti ọmọ Yoruba n jẹ bii oriki.

Erongba BBC Yoruba ni ki ede, aṣa ati igbagbọ iran Yoruba ma parun ni a ṣe jade lọ beere nipa awọn Aina ki a tun fi rán ara wa leti iru ọmọ to n jẹ Aina.

Aina ni ọmọbinrin ti o gbe ibi kọrun wa sile aye nigba ti a bi i.

Wọn maa n sọ ọmọkunrin to ba gbe ibi kọrun wa sile aye ni Ojo.

Ẹya Ijẹbu ni ipinlẹ Ogun ni guusu Naijiria kii sọ ọmọkunrin wọn ni Ojo.

Ati obinrin, ati ọmọ ọkunrin to ba ti gbe ibi kọrun wa saye, Aina ni wọn maa n sọ wọn.

Wọn ma n ki awọn Aina pe:

"Aina Ogunyunmọla

A dá ilá ọkọ re

A se ọbẹ̀ ọkọ lọ́tọ̀

Ebi kìí pa ọkọ Aina òrósùn rara

Iná dídá kìí ni wọn lára nitori ọkọ....."

Ọpọ eniyan lo gbagbọ pé awọn Aina maa n ni ìpinnu to ga ti ko rọrun fun ẹlomii lati yipada fun wọn.