Sogidi Lake: Ṣọ́jà tó dẹ́jàá láti pa ẹja odò Sogidi pàdánù ọmọ mẹ́ta láàrín ọ̀sẹ̀ kan -Ojedele
Ilu Aáwẹ́ ni ìpínlẹ̀ Oyo ni guusu Naijiria ni irinajo gbe BBC Yoruba de bayii.
Odo Adagun Sogidi ni BBC lọ ṣe iwadii rẹ nitori ti ọmọ ko ba ba itan, o gbọdọ ba arọba to jẹ baba itan.

- Èèyàn mẹ́rin míì tún ni Coronavirus nípìnlẹ́ Oyo, ó di èèyàn 97 tó níi ní Nàìjíríà
- Fíímù ṣíṣe dáwọ́ dúró, Joke Muyiwa di 'grandma', Lizzy Anjorin sọ pé coronavirus ko gbọdọ̀ díwọ́ ọjà títà
- Irọ́ ní, kìí ṣe àdó olóró ló bú gbàmù ní Akure - Ọ̀gá Ọ̀lọ́pàá Ondo!
- Kí ló fa ááwọ̀ láàárín Oluwo àti Agbowu gan-an?
- Èmi kìí ṣe ọmọ eléégún ṣùgbọ́n mò ń pe kísà sí ẹ̀ṣà- Òkòtò akéwì
- Òkè Ìyámàpó ní ìlú Ìgbẹ́tì

Alagba Ọjẹdele Adebayọ to jẹ alamojuto adagun odo Sogidi ni Aawẹ pa itan bi odo yii ṣe jẹ.
O sọrọ kikun lori awọn eewọ odo naa ati abami ẹja ko ṣẹja-ko ṣeeyan to finu adagun odo naa ṣe ibugbe.
Alagba Ojẹdele ṣalaye bi gbogbo ọrọ ti ri lati ọdun 1750 ti wọn ti wa lati Ile Ifẹ to jẹ orisun Yoruba.
Bakan naa lo mẹnuba iriri lori awọn to ti dẹ́jàá sẹyin nipa pipa ẹja inu odo yii ṣeyin.
Ni ipari, igbagbọ la fi n rire gba lọwọ Olorun.
Alagba Ojedele sọrọ lori bi adura awọn eeyan ṣe n gba ti wọn ba tọrọ nkan ninu odo yii.