Ìdí rèé tí ìjọba Ondo ṣe gbésẹ̀lé ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde láwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Ebenezer Adeniyan
Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede pe o ti di eewọ ki awọn ọmọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ maa ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade lati akoko yii lọ.
Ikede yii lo jẹyọ nibi ipade apero kan to waye laarin ijọba, awọn alaṣẹ ile ẹkọ aladani ni ipinlẹ naa atawọn ti ọrọ eto ẹkọ kan nipinlẹ ọhun.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ìgbésẹ̀ ọhun atawọn igbesẹ mii wa fun gbigbe opo eto ẹkọ ro nipinlẹ Ondo.
Ipinlẹ Edo, Imo, ati Benue lo ti kọkọ gbe irufẹ igbesẹ náà ṣaaju asiko yii.
Idi ree ti a fi gbẹsẹle ayẹyẹ ikẹkọọjade awọn ọmọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ - Ìjọba Ondo
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, kọmiṣọa eto ẹkọ ipinlẹ naa, Ọjọgbọn Igbekele Ajibefun sọ pe ibi ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn alakoso ile ẹkọ aladani nipinlẹ naa ni ipinnu ọhun ti jẹyọ.
Ajibesfun sọ fun BBC pe "A wo o pe ko tọ fun awọn ọmọ kekeke ti wọn ṣẹṣẹ n bẹrẹ aye wọn lati maa ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade, paapaa fun awọn obi wọn.
"Ti a ba wo bi ilu ṣe ri bayii, a ri pe ko tọ ki awọn ile ẹkọ tun maa mu aye nira fun awọn obi nipa owo ayẹyẹ ikẹkọọjade naa."
Ajibesun ni lara awọn igbesẹ ti ijọba n gbe ni lati ṣatilẹyin ati lati mu nnkan rọrun fun awọn alakoso ile ẹkọ aladani.
O ni "O han gbangba pe nnkan ti bajẹ ni ẹka eto ẹkọ, a si gbọdọ ṣe awọn nnkan to yẹ lati ri daju ogo eto ẹkọ pada si bo ṣe wa laye atijọ.
Awọn ti ọrọ yii kan gbọngbọn
Ọjọgbọn Ajibefun sọ fun BBC News Yorùbá pe awọn ti ọrọ ayẹyẹ ikẹjọọjade yii kan gbọngbọn ni awọn ọmọ to n kuro ni ipele ẹkọ alakọbẹrẹ kan si omiran.
Ìjọba Ondo ni lara awọn ti ọrọ yii kan ni awọn ọmọ to n kuro ni ile ẹkọ Jẹleosinmi 'pre-nursery' si ipele ẹkọ akọkọ nile ẹkọ alakọbẹrẹ.
Amọ ṣa, o ni awọn akẹkọọjade lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ ti wọn n lọ si ilẹ ẹkọ ipele akọkọ nile ẹkọ girama le ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade.
Bẹẹ ni awọn to ti ṣe idanwo aṣekagba nile ẹkọ girama ti wọn si n mura lati wọ fasiti naa le ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade.
Awọn igbesẹ mii ti ijọba ipinlẹ Ondo gbe lori eto ẹkọ
Yatọ si ọrọ ayẹyẹ ikẹkọọjade, Ajibefun tun sọ pe ijọba yoo fun awọn ile ẹkọ aladani ti ko gba ontẹ ijọba ni oṣu mẹfa pere lati fi orukọ silẹ.
Ati pe ijọba yoo mu eto ifọrukọsilẹ naa rọrun fun awọn to ba fẹ fi orukọ ile ẹkọ wọn silẹ.
O ni "Ti o ba ni ile ile ẹkọ aladani ti o ko forukọ rẹ silẹ, o n ṣakoso lori ile ẹkọ to lodi si ofin, ijọba yii ko ni faye gba owo ti ko ba ofin mu."
Ìjọba Ondo tẹsiwaju pe ijọba ko fọwọ si bi awọn kan ṣe n fi ọmọ ti ọjọ ori wọn kere sile ẹkọ, ati bi awọn akẹkọọ kan ṣe n lọ lati ile ẹkọ kan si omiran lai ni awọn iwe atawọn amuyẹ to tọ.
O pari ọrọ rẹ pé, ipinlẹ Ondo ko ni ṣeto ẹkọ ti ko ba igba mu tabi eyii ti ko si ni ibamu pẹlu bi wọn ṣe n ṣeto ẹkọ lawọn orilẹede to ti goke agba lagbaye.















