CBN pàṣẹ fún àwọn oní POS láti fi àdírẹ́sì àti àwòrán ibi tí wọ́n tí fẹ́ máa lò ó sílẹ̀

Aworan ẹrọ POS

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Banki apapọ lorilẹede Naijiria ti kede igbesẹ tuntun fun lilo ẹrọ POS, eyi ti iforukọ silẹ rẹ gbọdọ waye pẹlu agbegbe ti wọn yoo ti ma a lo.

Bakan naa ni iforukọsilẹ agbegbe yii yoo tun nilo aworan agbegbe naa.

Eyi lo wa ninu atẹjade kan ti CBN fi sita lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2025.

Ninu atẹjade naa to wa loju opo itakun agbaye rẹ, CBN palaṣẹ fun gbogbo awọn ileeṣẹ to n pin POS fun awọn eeyan bii OPay, PalmPay, Moniepoint ati awọn ile ifowopamọ yooku pe ki wọn bẹrẹ si ni ma ṣe ifọrukọsilẹ ilegbe ẹni to ba gba POS lọwọ wọn, laarin oṣu meji si asiko yii.

Eyi tumọ si pe ọpọ POS ti awọn onisowo n lo kaakiri orilẹede Naijiria ni yoo jẹ eyi ti wọn gbọdọ ṣe iforukọsilẹ rẹ pẹlu agbegbe ti wọn n gbe.

Gẹgẹ bii CBN ṣe ṣalaye, igbesẹ yii lo da lori igbiyanju lati fopin si iwa ibajẹ to wọpọ ati lati le ṣawari awọn eeyan to n lo ẹrọ yii fi ṣe iṣẹ ibi.

CBN kilọ pe ẹnikẹni to ba kọ lati tẹlẹ aṣẹ yii ko ni ni anfaani lati lo ẹrọ POS rẹ bẹrẹ lati ogunkọ oṣu Kẹwaa ọdun 2025.

Kí ni ìtumọ̀ èyí fún ààbò rẹ?

CBN ni, ẹrọ POS tuntun ti wọn yoo ma fi sita lasiko yii ni yoo nilo pe ki awọn to fẹ fi ma a ṣowo fi adirẹsi ibi ti wọn fẹ ti ma lo silẹ

CBN ni, igbesẹ tuntun yii yoo pese aabo fun araalu lọwọ kọlọrọsi ẹda.

Ni ibẹrẹ karakata, ẹrọ POS yoo nilo lati mọ adirẹsi, ti yoo si fidirẹ mulẹ boya lootọ ni adirẹsi naa wa ni agbegbe ti eeyan naa fi silẹ .

Karakata to ba waye ni iwọn mita mẹwaa si agbegbe ti ẹni naa fi forukọ silẹ, ni wọn yoo fagile lẹsẹkẹsẹ.

Gbogbo ẹrọ PO,S boya tuntun tabi ti tẹlẹ ni o gbọdọ ni orukọ agbegbe wọn ti wọn fi si ninu ẹrọ naa, ti yoo si ma a ba iwe pelebe ti to ba tẹ jade fun onibaara.

POS gbọdọ jẹ eyi ti wọn forukọ silẹ pẹlu Payment Terminal Service Aggregator (PTSA) pẹlu agbegbe ti okowo naa ti n waye.

Gẹgẹ bii o ṣe waye ninu alaye Banki Apapọ, igbesẹ tuntun yii ni yoo pese anfaani fun iwadii nipa agbegbe ti fifi owo ransẹ tabi gba owo ti waye.

O wulo fun itaja ati sise iwadii pẹlu ọpọ ẹkunrẹrẹ.

CBN ni pẹlu eyi, igbagbọ wa pe opin yoo de ba bi awọn kọlọrọsi ẹda ṣe n fi ẹrọ gba owo lọwọ awọn eeyan pẹlu ipa tabi nnkan ija oloro.

Bi o sͅe le daabo bo ara reͅ ree loͅwoͅ awoͅn oni jibiti POS

Awọn ole le lo BVN eniyan lasiko ti woͅn ba n lo POS ni oͅdoͅ woͅn, ti woͅn a si loͅ si apo isuna naa leͅyin, lati ko gbogbo owo to wa ninu apo isͅuna eͅni oͅhun.

Ni kete ti woͅn ba tẹ 'approve transaction', ohun ti eniyan gboͅdoͅ sͅe ni lati teͅ boͅtini 'cancel' ki woͅn ma ba ni anfaani si gbogbo iroyin to wa lori kaadi ATM naa.

Ti ẹ ko ba teͅ 'cancel', ti eͅni to ni POS naa ba jeͅ onijibiti, o le lo BVN eͅni naa.

Ohun ti won ma n se ni lati fi BVN naa ranse si awon obayeje, ti won a si hack account eni naa.

Leͅyin naa ni woͅn yoo ko gbogbo owo to wani ibeͅ.