Baltasar Engonga, àbúrò Ààrẹ Equatorial Guinea dèrò ẹ̀wọ̀n fún ìwà àjẹbánu

Aworan Baltasar Ebang Engonga ti wọn fẹsun kan pe o kowo jẹ ninu asọ suuit

Oríṣun àwòrán, Baltasar Ebang Engonga / Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile ẹjọ giga kan ni Equatorial Guinea ti ju ọga agba tẹlẹ fun ileeṣẹ ijọba to n gbogun ti iwa ibajẹ nidii owo nina ati ọrọ aje lorilẹede naa, Baltasar Ebang Engonga si ẹwọn ọdun mẹjọ fun kiko owo ilu jẹ ati fifi ọna eru ko ọrọ jọ.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin orilẹede Equatorial Guinea ṣe sọ, awọn ẹsun mii ti wọn fi kan an ni pe, o tabuku ipo rẹ, ṣiṣe owo ilu mọkumọku.

Ile ẹjọ giga Bioko to gbe idajọ kalẹ lọjọ Isẹgun, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2025, ni Ọgbẹni Engonga ati awọn marun un mii to wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba jẹbi ẹsun pe wọn ko ọpọ owo ijọba jẹ.

Baltasar Engonga di ilumọọka ni ọdun 2024 lẹyin ti ọpọ fọnran ibalopọ rẹ pẹlu ọpọ obinrin rapala bọ sori ayelujara.

Ijọba orilẹede naa ni ki Engonga lọ rọkun ni ile nitori awọn fọnran ibalopọ to le ni irinwo, to lu sita lori ayelujara, ti diẹ ninu awọn obinrin naa si jẹ iyawo eekan ilu lorilẹede Equatorial Guinea.

Lẹyin ọpọ oṣu ni ahamọ, ile ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe Engonga ati awọn adari mẹta ni ẹka eto isuna jẹbi ẹsun ti wọn ka si wọn lẹsẹ pe wọn ko owo ilu si apo ara wọn.

Ẹwọn ọdun mẹjọ ni wọn ju Engonga si, ti wọn si tun palaṣẹ fun wọn ki wọn san owo itanran.

Ile ẹjọ naa ni awọn afurasi ti wọn jẹ oludari ẹka ijọba, ti Ireneo Mangue Monsuy Afana, Baltasar Ebang Engonga Alú, ati Rubén Félix Osá Nzang, si jẹ olori to lewaju fun ẹsun naa, ti nwọn si ran wọn lọ si ẹwọn ọdun mẹjọ ati pe wọn yoo san owo itanran.

Engonga yoo san apapọ owo to jẹ $220,000.

Awọn yooku ni Rolando Asumu Ndong Oyé, Carmelo Julio Motogo Ndong, ati Florentina Ngangá Iñandji wey ni ile ẹjọ sọ si ẹwọn ọdun mẹta pẹlu owo itanran to jẹ 16 si 31 milọnu CFA francs.

Ki lo sẹlẹ ṣaaju?

Ni oṣu kọkanla ọdun 2024, Baltasar Ebang Engonga, to jẹ oṣiṣẹ ijọba orilẹede Equatorial Guinea ati aburo fun Aarẹ Teoduro Obiang Nguema di ilumọọka kaakiri agbaye.

O jẹ olori fun ileeṣẹ ijọba NFIA, to si jẹ pe iṣẹ rẹ ni ko gbe ogun ti iwa ibajẹ.

Ọpọ fọnran to le ni 400 ti Baltasar Ebang Engonga, ti n ni ibalopọ ninu ọọfiisi rẹ ati awọn ibo mii pẹlu orisirisi obinrin lo bọ sita lori ayelujara.

Ọpọ awọn obinrin to wa ninu fọnran ni wọn jẹ awọn iyawo awọn eekan ilu lorilẹede naa.

Ọjọ kẹdọgbọn oṣu Kẹwaa ni ọwọ tẹ Baltasar Ebang Engonga, pe o ji ọpọ ninu apo owo ijọba, to si lọ gbe pamọ si Cayman Islands.