"Ifa ń gba Dollar, ifá ń gba Pounds ni wọ́n fi yan Ọba lé wa lórí", aráàlú Ipetumodu sọ̀rọ̀ nipa Ọba wọn tó rí ẹ̀wọ̀n he l'Amẹ́ríkà
Laipẹ yii ni iroyin jade pe Ọba Apetumodu ti ilu Ipetumodu ni ipinlẹ Ọṣun, Ọba Joseph Oloyede ti ri ẹwọn he lorilẹede Amẹrika nitori ẹsun jibiti to niiṣe pẹlu owo iranwọ lasiko ajakalẹ arun COVID-19 ti ile ẹjọ sọ pe o jẹbi rẹ.
Awọn eeyan ilu naa si ti ba BBC News Yoruba sọ ero wọn lori iṣẹlẹ naa ati ohun tiwọn ri sọ sii.
Ọba wa ko si lẹwọn, mo ṣi ba kabiyesi sọrọ
Ninu ọrọ rẹ, Olori awọn afọbajẹ ni ilu Ipetumodu, Oloye Afọlabi Adedeji ni Ọba Oloyede ko si ni ahamọ, koda ko si ni ẹwọn. Agba oye ilu Ipetumodu naa ṣalaye pe oun ati Kabiyesi naa ṣi sọrọ ni ọjọ ti wọn da ẹjọ naa.
"Ni ọjọ Iṣẹgun ti wọn da ẹjọ naa, a ṣi sọrọ. Ijẹta ati ana gan, a ṣi sọrọ. Ko si ni ahamọ."
Oloye naa ni awọn n reti abajade ọrọ lati ọdọ ijọba ipinlẹ naa ni lati mọ ibi ti oju ọrọ yoo gba. O ni ijọba ipinlẹ Ọṣun ti beere fun iwe akọsilẹ idajọ naa lati le fi mọ ohun to kan ni igbesẹ.
"Ifa n gba Dollar, Ifa n gba Pounds"
Ninu ọrọ tirẹ Ọgbẹni Oyedokun Abiọdun to jẹ ọmọ bibi ilu naa ṣalaye pe ko yẹ ki ọrọ ri bo ṣe ri ka ni awọn ilana ti iṣẹṣe la kalẹ ni wọn tẹle nigba ti wọn n yan an si ipo.
Arakunrin naa ṣalaye pe nigba ti ọrọ oye jijẹ bẹrẹ ni ilu naa ti awọn eeyan n pariwo ki wọn tẹle ohun ti Ifa wi, ohun ti awọn n gbọ "ni pe Ifa mọ Dollar, Ifa mọ Pound"






