'Nítorí mo fẹ́ mọ̀ nípa èdè àti àṣà ni mo ṣe wá kọ́ èdè Yorùbá ní Nàìjíríà'
Ọ̀kan lára àwọn ọ́nà tí ìjọba máa gbà láti mú àgbéga bá èdè, àṣà àti ìṣe ilẹ̀ rẹ̀ ni láti rí dájú pé àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè rẹ̀ kọ́ nípa àṣà àti ìṣe wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ òkèèrè ni wọ́n ń gbé.
Irú ìgbésẹ̀ báyìí ló máa ń wáyé láàárín ìjọba orílẹ̀ èdè kan sí òmíràn níbi tí àwọn ọmọ ilẹ̀ orílẹ̀ èdè náà máa ń wá sí Nàìjíríà láti wá kọ́ nípa èdè, àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Nàìjíríà.
Adele Olùdarí ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń kọ́ èdè Yorùbá ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Ibadan, Clement Odoje sọ pé àwọn èèyàn tó lè ní ẹgbẹ̀rún méjì ló ti wá ń kọ́ nípa èdè àti àṣà ilẹ̀ Yorùbá láti ìgbà tí wọ́n ti dá ètò náà sílẹ̀.
Odoje ní láti orílẹ̀ èdè káàkiri bíi Amẹ́ríkà, China, Japan, Brazil, Spain àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní àwọn èèyàn ti máa ń wá láti kọ́ nípa èdè Yorùbá.
Ó fi kun pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n dàgbà sílẹ̀ òkèèrè, tí wọ́n kò sì ní ìmọ̀ tó nípa àṣà àti ìṣe wọn náà máa ń wá sí iléeṣẹ́ náà láti wá kọ́ nípa èdè àti àṣà wọn.
Ó ní àwọn ń kọ́ àwọn èèyàn ní èdè Yorùbá tí wọn yóò lè máa ṣàmúlò ní gbogbo ibikíbi tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ti ba ara wọn ni àwọn ń kọ́ wọn.
"Ó máa ń jẹ́ ìwúrí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí pé wọ́n le máa kọ́ èdè wọn , tí wọ́n sì lè máa ṣe àmúlò rẹ̀ ní àwùjọ."
ílé òun.
"Ìsàlẹ̀ Eko ni wọ́n bí mi sí ṣùgbọ́n mo dàgbà sí Amẹ́ríkà. Mo padà wá sí Nàìjíríà nítorí mo fẹ́ kọ́ èdè mi, mo fẹ́ kọ́ àṣà mi," Helen Kehinde Thomas sọ fún BBC News Yoruba.
Kehinde Emmanuel Oladosu ti wọ́n bí sí ìpínlẹ̀ New York, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tí òun náà ń kọ́ nípa èdè Yorùbá náà sọ fún BBC News Yoruba pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ile Ife ní ìpínlẹ̀ Osun àti ìlú Ibadan ní ìpínlẹ̀ Oyo ni àwọn òbí òun ti wá, òun kò ní àǹfàní láti kọ́ nípa èdè Yorùbá ló jẹ́ kí òun padà sílé.
"Ìdí tí mo fi ń kọ́ èdè Yorùbá ni pé mi ò fẹ́ kí àṣà kú lórí mi," Kehinde sọ fún BBC.
Oluwatumininu Ipaye sọ pé láti kékeré ni òun ti kúrò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti kékeré tí òun sì padà wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa èdè Yorùbá nítorí òun kò fẹ́ kí èdè Yorùbá kú n

Èròńgbà dída ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀

Clement Odoje ṣàlàyé pé èròńgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ilẹ̀ Ibadan láti dá ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀ pọ̀ tí ara rẹ̀ sì jẹ́ láti mú kí àlááfíà jọba ní gbogbo àgbáyé.
Ó ní ọdún 2009 ni àwọn ti dá ètò náà sílẹ̀ tí ìjọba Amẹ́ríkà sì báwọn fọwọ́sowọ́pọ̀ láti máa ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn èèyàn orílẹ̀ èdè rẹ̀.
Ní ọdọọdún ni ètò yìí máa ń wáyé tí wọ́n máa ń kó àwọn èèyàn láti Amẹ́ríkà àti orílẹ̀ èdè míì wá sí ilé ẹ̀kọ́ náà láti kọ́ nípa èdè Yorùbá.
"Ètò yìí dàbí ìrìbọmi fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa tí wọ́n ti kọ́ nípa èdè Yorùbá láti mọ̀ nípa rẹ̀ si."






