Ọkọ̀ ojú omi tó kó àwọn tó ń 'Japa' lọ sílẹ̀ Yúròópù yí dànù s'ókun, èèyàn 69 kú

Awọn ọkọ oju omi ti wọn fi igi ṣe to wa leti okun

Oríṣun àwòrán, Anadolu Agency/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Eeyan 160 lo wa ninu ọkọ oju omi ọhun lasiko to gbera ti pupọ ninu wọn si jẹ ọmọ orilẹede Gambia ati Senegal
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O kere tan, eeyan mọkandinlaadọrin lo ti jade laye ti ọpọ si di awati lẹyin ti ọkọ oju omi kan danu lori okun orilẹede Mauritania.

Lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, eeyan mẹtadinlogun ni wọn ti doola ninu omi naa nigba ti iṣẹ ṣi n lọ lọwọ lati ṣawari awọn to ku.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn ti ori ko yọ sọ, orilẹede Gambia ni ọkọ oju omi naa ti gbera ni ọjọ mẹfa ṣeyin to si n rinrinajo lọ si awọn erekusu Canary, ni Spain.

Eeyan 160 lo wa ninu ọkọ oju omi ọhun lasiko to gbera ti pupọ ninu wọn si jẹ ọmọ orilẹede Gambia ati Senegal.

Ori alagbalugbu omi Atlantic Ocean ti ijamba yii ti waye jẹ ibi kan ti ọpọ ọmọ ilẹ Africa ti maa n padanu ẹmi ninu ilakaka wọn lati rekọja silẹ Yuroopu.

Nnkan bii 47,000 ọmọ ilẹ Africa lo gbiyanu lati rekọja si erekusu Canary naa lọdun to kọja, amọ ajọ ti kii ṣe ti ijọba kan ni Spain, Caminando Fronteras sọ pe nnkan bii ẹgbẹrun mẹsan an eeyan lo padanu ẹmi wọn sinu okun.

Awọn ẹṣọ alaabo ori omi agbegbe naa sọ fun ileeṣẹ iroyin EFE pe wọn n wa awọn to ja sinu omi de nnkan bii ọgọta kilomita si ibi ti ijamba ọhun ti waye titi de ariwa Nouakchott to jẹ olu ilu orilẹede naa.

A gbọ pe ijamba ọhun waye lẹyin ti awọn arinrinajo naa ri ina kan ni ọọkan ti gbogbo wọn ti korajọ si ẹgbẹ kan ṣoṣo ninu ọkọ naa lo dojude.

Agbẹnusọ Caminando Fronteras, Helen Maleno rọ awọn ẹṣo oju omi ki wọn tẹsiwaju lati maa wa awọn to ṣi wa ninu okun, lẹyin naa lo juwe iṣẹlẹ ọhun bii eyii to buru julọ ni lasiko yii.

Ẹwẹ, ibẹrẹ oṣu yii ni wọn fẹsun kan awọn ologun Mauritania pe wọn n fiya jẹ awọn to n rinrinajo lati ṣatipo lọna ti ko tọ.