'Ìlú tó léwu láti gbé jùlọ fún àwọn obìnrin lágbáyé'

Àkọlé fídíò, ‘Ìlú tó léwu láti gbé jùlọ fún àwọn obìnrin lágbáyé’
'Ìlú tó léwu láti gbé jùlọ fún àwọn obìnrin lágbáyé'

Ifipabanilopọ at'awọn iwa ipa miran ti n fojojumọ pelemọ sii ni orilẹede Haiti, bi awọn ẹgbẹ janduku ṣe n gbilẹ ni ilu Port au- Prince ati kaakiri.

BBC News ba awọn obinrin ti ọrọ kan at'awọn ẹgbẹ janduku sọrọ.

Gẹgẹ bi ohun ti ọpọ awọn onwoye lagbaye n sọ bayii, orilẹede Haiti ti wa ni bebe iṣubu.

Awọn ẹṣọ alaabo atawọn fijilante n gbiyanju lati daabo bo awọn ilu kan lorilẹede naa eyi ti awọn ẹgbẹ janduku ti gba iṣakoso ti wọn siti n da ọpọ wahala silẹ, paapaajulọ iwa ipa si awọn obinrin.

Awọn ṣọja ninu mọto wọn loju popo kan ni Haiti.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Gbogbo ipa lawọn agbofinro atawọn fijilante n sa lorilẹe Haiti, paapaajulọ ilu Port-au-Prince tii ṣe olu ilu rẹ atawọn ailu t yii ka

Ọpọlọpọ ile, ọkọ atawọn dukia olowo iyebiye miran lawọn janduku wọnyii ti ji nibi ti wọn ti n doju ija kọ ara wọn; koda wọn ti pa ọpọlọpọ awọn ọmọde pẹlu.

Gẹgẹbi ọrọ ti ọkọ lara awọn fijilante to n ja fun imupadabọsipo alaafia lorilẹede naa sọ fun BBC News, 'awọn janduku yii ko tilẹ fẹ mọ ohunkohun, gbogbo eeyan ti wọn ri ni wọn n pa'.

Awọn ẹgbẹ janduku wọnyi lo n ṣakoso pupọ ilu Port-au- Prince to jẹ olu ilu orilẹede naa bayii.

'Wọn fi ipa ba mi lopọ, wọn tun ba ọmọ ọdun mẹfa ti mo gbe dani lopọ'

Obinrin kan to n rin lọ laarin igboro kan to da paroparo gbe ẹru lori fa apo ẹru miran, bi ẹni to n fi ilu silẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ awọn obinrin ni wọn ti sa kuro ni ilu Port-au-Prince ati agbegbe rẹ nitori ikọlu ati iwa ipa awọn janduku

Bẹẹ, awọn obinrin atawọn ọmọde lo n fara wi ina wahala naa julọ, ọwọja wahala naa si pọ gidi gan ni to bẹẹ ti ọpọlọpọ awọn obinrin ti fi ile ati ọna wọn silẹ lati sa asala fun ẹmi wọn. Ọkan lara awọn obinrin ti wọn ti fara kaasa iwa ipa awọn janduku yii ṣalaye pe, 'wọn fi ipa ba mi lo pọ, koda ọmọ mi, ọmọ ọdun mẹfa to wa pẹlu mi gan, wọn tun fi ipa ba a lopọ'.

Awọn obinrin miran naa tun ṣalaye nnkan ti oju wọn n ri: 'Nigba ti mo fi maa de ile, wọn ti pa baba, iya ọmọ ati aburo mi obinrin.'

Ti a ba ti bẹrẹ ija, ẹmi buruki lo maan gbe wa wọ - Olori ẹgbẹ janduku kan

Ọdọmọkunrin kan n bu epo si ina kan ti wọn n da si taya ọkọ loju popo kan ni Haiti. Ọdọmọkunrin miran n wo o lọọkan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ dukia lawọn janduku naa ti dana sun, ti wọn si ti gba ẹmi ọpọlọpọ awọn ọmọde pẹlu

Nigba ti o tun dahun ibeere siwaju sii lori idi ti wọn fi n hu iru iwa ibi bẹẹ si awọn eeyan wọn, Olori ẹgbẹ janduku naa to pe orukọ ara rẹ ni 'Vag' sọ pe, 'Gẹgẹ bi adari ẹgbẹ janduku, ojuṣe mi ni lati ja'.

'Vag' sọ pe oun atawọn akẹgbẹ oun o ni sinmi ija ati ikọlu wọn titi di igba ti ijọba ba ṣetan lati pe wọn si ijoko ijiroro.

Lọwọ yii, ọpọ araalu lo ti padanu ẹmi wọn, ti wọn si ti fi ipa ba ọpọ awọn obinrin sun pẹlu.