Àwọn ọ̀nà tí ooru ń gbà ṣe àkóbá fún ọpọlọ ènìyàn

Oríṣun àwòrán, Serenity Strull/Getty Images
- Author, Theres Lüthi
- Role, BBC Future
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Igba ti Jake wa ni ọmọ oṣu marun un lo kọkọ daku rọgbọndan latari oru amuju.
Iya rẹ Stepahnie Smith sọ pe "ooru pọ gidi lọjọ naa, ara rẹ gbona ju bo ṣe yẹ lọ, ẹru si ba wa gidi lọjọ ọhun."
Lẹyin naa lo bẹrẹ si n gbona ni gbogbo igba ooru.
Ni kete ti akoko ooru ba ti de ni awọn mọlẹbi rẹ maa n wa ọna ti ko ni fi gbona mọ.
Nigba ti Jake pe ọmọ ọdun kan abọ, iwadii fi han pe o ni aisan ti wọn n pe ni "Dravet Syndrome" eyi to farajọ aarun warapa to n maa n ba nnkan bii ẹgbẹrun marundinlogun ọmọde finra lagbaye.
Yatọ si pe awọn ọmọ naa yoo maa daku rangbọndan, wọn tun maa n ni iṣọro lati sọrọ, rin, jẹun ati lati sun.
Nigba ti ooru ba mu amuju, wọn le daku.
Jake ti pe ọmọ ọdun mẹtala bayii amọ o ti daku ni aimoye igba latari bi oju ọjọba ṣe ri.
Iya rẹ sọ pe akoko ti oju ọjọ ba wa maa n ṣakoba fun ilera rẹ lọpọ igba.
Dravet Syndrome jẹ ọkan lara ọpọlọpọ aarun ti ooru amuju maa n fa gẹgẹ bii Sanjay Sisodiya nile ẹkọ University College ilu London ṣe sọ.
Gẹgẹ bii onimọ nipa aarun warapa, o maa n gbọ ti awọn obi maa n sọ pe asiko ooru ni giri maa n mu awọn ọmọ wọn julọ.
O ni "mo wa ronu pe, bawo ni ayipada oju ọjọ ko ṣe ni ṣe akoba fun ọpọlọ eeyan? Ṣebi gbogbo iṣẹ ti ẹya ara mii n ṣe lo kan ọpọlọ."
Ninu igbiyanju rẹ lati mọ si ninu iwadii ijinlẹ, o ṣawari pe pupọ ninu awọn aarun to maa n mu ki eeyan daku lo lọwọ ooru ninu.
Lara awọn aarun naa ni warapa, arun rọpa-rọsẹ, ori fifọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O tun ṣawari pe ipa ti ayipada oju ọjọ n ni ninu ọpọlọ ẹda ti n foju han ju atẹyinwa lọ.
Lasiko ti ooru mu amuju ni Yuroopu lọdun 2003, ida meje awọn to ku lo jẹ nipa awọn aarun bayii, ohun kan naa lo ṣẹlẹ lọdun 2022 ni UK.
Yatọ si eyii, ooru amuju tun le ṣe awọn akoba mii fun ọpọlọ, bii ara kikan tabi ki inu eeyan ṣadede maa bajẹ.
Ni bayii ti gbogbo agbaye n koju ayipada oju ọjọ, ki ni yoo bẹrẹ si n ṣẹlẹ si ọpọlọ wa?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nipa bi ara ṣe n gbona si, ti ọpọlọ eeyan fi diẹ pọ ju 1C ju bi ara ṣe gbona si lọ.
Sibẹsibẹ, ọpọlọ maa n gbona ni iwọn tirẹ latari iye iṣẹ to n ṣe.
To n tumọ si pe agọ ra wa gbọdọ ṣiṣẹ daadaa ki ọpọlọ le maa tutu diẹ diẹ.
Bi ẹjẹ ṣe n gba awọn inu iṣan ara ni o n mu ara tutu kuro lọwọ oru amuju.
Eyi ṣe pataki nitori awọn ẹya inu ọpọlọ wa ko fẹran oru rara, wọn si le kọṣẹ ti ọpọlọ ba gbona tabi tutu ju.
Sisodiya ni "o ṣoro lati sọ ni pato bi gbogbo ẹya naa ṣe n ṣiṣẹ, amọ a le fi we aago ti iṣẹ rẹ ko ni pe mọ ti eyikeyi ninu ẹya rẹ ba ti kọṣẹ."
Lootọ ni pe oru amuju le ṣe ipalara fun iṣẹ ọpọlọ oniruru eeyan ni oniruru ọna, amọ awọn ti wọn ni aisan ti a mọ si "neurological conditions " ni ipalara naa pọju fun julọ.
Sisodiya ni ti awọn apakan ọpọlọ ko ba ṣiṣẹ daadaa, o le da iṣẹ ọpọlọ ọhun ru.

Oríṣun àwòrán, Magali Cohen/Hans Lucas/AFP via Getty Images
Oru amuju le ṣakoba fun oorun eeyan, o si le mu ki awọn apẹrẹ aisan kan buru ju bo 'se yẹ lọ.
Sisodiya sọ pe, fun awọn ti wọn ni warapa, giri le maa mu wọn ti wọn ko ba sun daadaa.
Iwadii fi han pe iye awọn ti wọn n fun ni ibusun nile iwosan latari pe wọn ko ranti ọpọ nnkan mọ maa n pọ si lasiko oru.
Eyii le jẹ nitori ọjọ ori wọn, nitori o maa n ṣoro fun awọn arugbo lati ṣe idinwọn bi ara wọn ṣe n gbona si.
Wọn le ma mu omi ni iwọn ati asiko to yẹ tabi ki wọn gbagbe lati ti ferese wọn.
Oru amuju ti n kun nnkan to mu ki arun rọparọsẹ peleke si lagbaye.
Iwadii ṣe ọfintoto eeyan ti arun naa n pa ni orilẹede marundinlogun esi rẹ si fi han pe awọn to ọjọ ti oru mu ju jẹ meji ninu ẹgbẹrunkan awọn to jade laye.
Bethan Davies lati University Hospitals ni Sussex, nilẹ Gẹẹsi sọ pe iye yii le kere loju amọ niwọn igba ti rọparọsẹ n gbẹmi eeyan bii miliọnu meje lọdọdun, oru le ṣokunfa nnkan bii ẹgbẹrun mẹwaa ninu rẹ, eyii si le pọ si lọjọ iwaju latari ayipada oju ọjọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oniruru nnkan ni oru amuju le da silẹ ninu agọ ara ẹda. Amọ ọna pato ti oru fi n ba ọpọlọ ja ni awọn onimọ ṣi n ṣewadii rẹ lọwọ.
Ọna ti oru n gba daamu onikaluku yatọ sira wọn, fun awọn kan inu oru ni wọn ti n ṣayọ, nigba ti awọn ẹlomiran ko le fara da oru rara.
Oriṣiriṣi nnkan lo n fa iyatọ yii, lara rẹ ni ohun ti wọn bi eeyan mọ gẹgẹ bi Sisodiya ṣe sọ.
Iyatọ to wa ninu iṣẹda eeyan le sọ bi nnkan bii oru tabi ayipada oju ọjọ yoo ṣe pa eeyan lara si.
Awọn ibere kan ṣi wa fun awọn onimọ ijinlẹ lati dahun, bii igba wo ni oru mu n amuju? Eyii le yatọ ninu agọ ara onikaluku.
Ffun apẹrẹ, asiko ti oyinbo alawọ funfun ba n kigbe oru le jẹ asiko ti ko tu irun kankan lara ọmọ alawọ dudu ilẹ Afrika ti oru ti mọ lara.
Wayi o, ṣiṣe awari ẹni ti ọrọ naa kan julọ ati eredi to fi ri bẹẹ ṣe pataki fun awọn onimọ ijinlẹ lati ṣiṣẹ le lori.












