Ìgbéyàwó obìnrin tó fẹ́ ọkọ méjì lẹ́ẹ̀kan nàá fa ariwo lórí ayélujára

Sunita C jokoo ni awọn ọkọ rẹ Kapil N ati Pradeep N

Oríṣun àwòrán, Alok Chauhan

Àkọlé àwòrán, Sunita C pẹlu awọn ọkọ rẹ Kapil N ati Pradeep N
    • Author, Saurabh Chauhan
    • Role, BBC News Hindi
    • Reporting from, Sirmaur, Himachal Pradesh
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Aworan oke yii n ṣafihan iyawo kan to jokoo laarin awọn ọkunrin meji ni abule Himalayan ni India, ti wọn si rẹrin musẹ fun kamẹra.

Ṣugbọn eyi kii ṣe aworan igbeyawo lasan o! O joko laarin awọn ọkọ iyawo meji ti o ṣẹṣẹ fẹ ni. Eyi jẹ igbeyawo alailẹgbẹ ni orilẹ-ede ti ile olorogun ti jẹ riru ofin.

Eyi ni idi ti awọn aworan ti Sunita C to ṣe igbeyawo pẹlu ọkunrin meji, Kapil N ati Pradeep N ni ọjọ kejila, oṣu Keje, ṣe fa ọpọ ariyanjiyan lori ayelujara – ti ọpọ eeyan si n fi eebu ransẹ si idile naa - sugbon o tun ti di ọrọ orilẹede naa.

Awọn mẹtẹẹta jẹ ọmọ agbegbe Hatti, ẹya abinibi to n gbe ni ariwa Himachal Pradesh ati Uttarakhand, lẹba awọn agbegbe odo Giri ati Tons.

Agbegbe yii ni eeyan to le ni 300,000 to wa kaakiri awọn abule 400 n gbe, to si gba orukọ rẹ lati ara okowo tita irugbin, ẹfọ ati irun agutan ni awọn ọja agbegbe naa ti wọn n pe ni "Haats".

Orile-ede India fọwọsi ẹya 700, ti o jẹ ida 8.6% olugbe orilẹ-ede naa.

Sunita C pẹlu ọkan ninu ọkọ rẹ, Pradeep N, lasiko igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Alok Chauhan

Àkọlé àwòrán, Igbeyawo Hattis' ni India

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ mọ wọn si Hindus, awọn Hattis n tẹle awọn ilana igbeyawo ti o yatọ si awọn aṣa Hindu.

Wọn n pe ni "jodidara" tabi "jajda". Awọn igbeyawo wọnyii jẹ eyi ti ọkọ ati iyawo yoo jẹ ẹ́jẹ́ igbeyawo funra wọn lojukoroju, dipo si sọ ọ yipo nigba meje yika ina iṣẹmbaye kan, gẹgẹ bii aṣa igbeyawo Hindu.

Bakan naa lo jẹ pe iyawo lo ma n lewaju, ti yoo si dari igbeyawo dipo ọkọ, bo ṣe ri ninu aṣa Hindu.

"Ni aye atijọ, ọkan ninu awọn ọkọ ni yoo duro ti iyawo nile ti yoo si maa ṣe ọkọ fun un, lasiko ti ikeji ba ṣe ọdẹ ẹran lọ fun ọpọlọpọ oṣu. Bayii ni wọn o ṣe ma a yipo rẹ laarin ara wọn."

"Ṣugbọn ni ode oni, ti ko si lilọ si oko ọdẹ mọ, ọgbọn ni wọn fi n yanju ṣiṣe ọkọ, nipasẹ ifẹnuko ebi, "Sher Jung Chauhan, akọroyin kan lati agbegbe Hatti, sọ fun BBC.

"Awọn igbesẹ bii orukọ baba wo ni ọmọ yoo jẹ, ni wọn n yanju laarin ẹbi ni tubi-n-nubi," o fikun.

Ayipada aṣa nitori ko ri itẹwọgba

Ẹsin Hattis darapọ mọ Hinduism pẹlu awọn ilana rẹ, pẹlu awọn oriṣa shamanic agbegbe ti n ṣe ipa nla ninu awọn aṣa ati igbesi aye ojoojumọ wọn.

Ni igba atijọ, awujọ Hatti ma n gba ni imọran pe ki tẹgbọn-taburo to jẹ ọkunrin, pe fẹ iyawo kan naa lati le yago fun pipin ilẹ ẹbi wọn. Ilẹ oko ṣọwọn nigba naa.

Ofin orile-ede India fayegba awọn ofin ati ilana ẹya, bii Hatti, lati tọju aṣa wọn, ayafi eyi ti ijọba ba fi ofin de ni pato.

Yashwant Singh Parmar, ẹni ti o jẹ minisita akọkọ ti Himachal Pradesh ati ọmọwe, ṣe akiyesi ninu iwe rẹ Polyandry in Himalayas pe "aṣa naa jade lati ara gbigbe ni ori apata, nitori ki awọn nnkan diẹ ti wọn ni le to o pin".

Ọpọ obinrin pẹlu awọn obinrin

Oríṣun àwòrán, Kapil Chauhan

Ṣugbọn iru igbeyawo yii ko wọpọ mọ lasiko yii

Awọn amoye ni eyi ko sẹyin pe ọpọ eeyan ti n kawe, idagbasoke eto ọrọ aje ati ipa ti isọdọtun to n mu iru aṣa bẹẹ idinku.

Kapil Chauhan, olugbe agbegbe naa, sọ pe idile mẹrin si mẹfa ni gbogbo abule to wa ni agbegbe naa si n kopa ninu aṣa pe ki obinrin ni ọkọ meji.

"O jẹ idanimọ wa ati ohun iwuri. Ti awọn idile ti o kan ba ti nifẹ si, ko si ẹlomiran ti o yẹ ki o ni iṣoro," o sọ fun BBC.

Gẹgẹ bi Ramesh Singhta ṣe sọ, "ọpọ iru igbeyawo bẹẹ ma n waye ni kọọrọ, laisi ariwo."

Yiyan tabi fifi tipatipa se?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iroyin igbeyawo naa fa ariyanjiyan to pọ lori ayelujara India.

Nigba ti ọpọlọpọ rii bi ọrọ igbanilaaye ati ṣiṣe ifẹ inu ara ẹni, ọpọ jiyan pe o tako awọn ẹtọ obinrin.

Awọn to fara mọ ri i bi idaabobo aṣa "jodidara" ti agbegbe Hatti ati itọju ilẹ ati iṣọkan idile.

Ọpọ tako aṣa yii ni ibamu pẹlu igbeaye ode oni, ipo rẹ labẹ ofin India ati pe o ti di nnkan atijọ.

Awọn kan sọ pe alabosi ni awọn to n ṣe e , nitori pe wọn faramọ kiobinrin ni ọkọ meji, amọ wọn tako ki ọkunrin fẹ iyawo meji.

Minisita fun ọrọ awọn ileeṣẹ ti ipinlẹ, Harshwardhan Chauhan gbagbọ ninu aṣa atijọ.

"Nipa mimu iwa yii wa laaye, Pradeep ati Kapil ti bu ọla fun ohun-ini aṣa wọn," o sọ fun BBC.

Ṣugbọn ọpọlọpọ awọn eeyan si n beere boya eyi mu ilọsiwaju ba ipo obinrin ninu ile.

"Iwa yii kii ṣe iwuri fun awọn obinrin ati pe o lodi si awọn ẹtọ ipilẹ wọn," Mariam Dhawale, akọwe gbogbogbo ti Ẹgbẹ Gbogbo Awọn Obirin ni India sọ.

O sọ fun BBC pe nini ọkọ meji le fi dandan mu obinrin lati bimọ ju iye to wu u lọ.

Sibẹsibẹ, Asha Devi, obinrin kan, to wa ninu igbeyawo "jodidara", tẹnumọ pe aṣa naa ko tako ominira obinrin kankan.

"Tako igbagbọ ọpọ eeyan, awọn obinrin ni ẹtọ lati kọ tabi fi iru igbeyawo bẹẹ silẹ ti wọn ba fẹ, ko si si ẹnikan ti o fi agbara mu sinu 'jodidara', boya obinrin tabi ọkunrin," Ms Devi sọ fun BBC.

Pradeep N, Sunita C ati Kapil N

Oríṣun àwòrán, Alok Chauhan

Àkọlé àwòrán, Pradeep, Sunita ati Kapil ka iwe, ti wọn si ni iṣẹ lọwọ

Sunita jẹ akọṣẹmọṣẹ onimọ-ẹrọ; Pradeep jẹ oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ, ti Kapil n ṣiṣẹ ni eka irinajo afẹ nilẹ okeere.

Iyawo naa sọ fun awọn akọroyin pe tinutinu ni oun fi wọ inu igbeyawo: "Ipinnu mi ni. Mo ti gba aṣa atijọ."

Awọn ọkọ rẹ ni eero kanna: "Ibasepo yii ṣe afihan igbagbọ wa ninu aṣa ati ojuse lati tọju ara wa," Pradeep ni o sọ eyi fun awọn akọroyin India.

Awọn mẹtẹẹta ti ṣe ileri ifẹ ati lati rii daju pe iduroṣinṣin ati iṣọkan alailẹgbẹ wa laarin wọn.